Orí Kẹta

1 Ṣùgbọ́n ẹ mọ èyí: ní ọjọ́ ìkẹyìn ìgba ewu yí ó wà. 2 Nítorí àwon ènìyàn yí ó di olùfẹ́ ara wọn, olùfẹ́ owó, afọ́nnu, agbéraga, asọ̀rọ̀-òdì, asàìgbọràn sí òbí, aláìlọ́pẹ̀, àti aláìmọ́. 3 Wọn kì yí ọ̀ ní ìfẹ́ sí àwọn ti o sún mó wọn, oní ìkórira àlááfíà, abanijẹ́, aláìlekóra-wọn-ní-ìjánu, oníjà, aláìnífẹ̀ oun rere. 4 Wọn yí ò jẹ́ ọ̀dàlẹ̀, alágídí, ajọra ẹni lójú, olùfẹ́ fàájì ju olùfẹ́ Ọlọ́run lọ. 5 Wọn yi ó ní àfarawẹ́ ìwà-bí-Ọlọ́run, ṣùgbọ́n wọn yí ò sẹ́ agbára rẹ̀. Ẹ yàgò fún àwọn ènìyàn yí. 6 Nítorí àwọn míràn nínu wọn jẹ́ ọkùnrin tí ń wọ inú ilé tí wọn sí kọ̀ àwọn obìnrin aláìgbọ́n. Èyí ni àwọn obìnrin tí a dì mọ́ ẹ̀sẹ̀ tí a sì ń fà wọ́n kiri pẹ̀lú ìfẹ́kùfẹ́. 7 Àwọn obìnrin yí ń fi ìgbàgbogbo kọ́ ẹ̀kọ́, ṣùgbọ́n wọn kò le wá sí ìmọ̀ tí òtìtọ́. 8 Bákannáà Jánés` àti Jámbrésì kọjú ìjà sí Mósè. Ní ọ̀nà yí àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ òdì náà sí kọjú ìjà sí òtítọ́. Wọ́n jẹ́ ènìyàn tí a bàjẹ́ nínú ọkàn, ẹni ìtanù ní ti ìgbàgbọ́. 9 Ṣùgbọ́n wọn kì yí ò lọ síwájú jù. Nítorí wèrè wọn yí ò farahàn sí gbogbo ènìyàn, gẹ́gẹ́ bìi ti àwọn ènìyàn wọ̀nyí. 10 Sùgbọ́n ní ti ìwọ, ìwọ́ ti tẹ̀lẹ́ ẹ̀kọ́ mi, ìgbésí ayé mi, ìpinnu, ìgbàgbọ́, ìpamọ́ra, ìfẹ́, sùúrù, 11 inúnibíni, ìjìyà, àti oun tí ó sẹlẹ̀ sí mi ní ántíókù, àti ìcónímù, àti ní ly´strà. Mọ farada inúnibíni. Nínú gbogbo wọn, Olúwa si gbà mí. 12 Gbogbo àwọn tí ó fẹ́ gbé ìgbé ìwà-bí-Ọlọ́run nínú krístì Jésù ni a ó se inúnibíni sí. 13 Ènìyàn búburú àti àwọn ẹlẹ̀tàn yíò máa burú si. Wọn yí ò mú àwọn ẹlòmíràn sìnà. A ó sì mú àwọn pẹ̀lúpẹ̀lù sìnà. 14 Ṣùgbọ́n ní ti ẹ̀yin, ẹ dúró nínu oun tí ẹ̀yin ti kọ́ tí èyín sì ti gbàgbọ́ gidigidi. Ẹ mọ ọ̀dọ ẹni tí ẹ̀yin ti kọ́ o. 15 Ẹ mọ̀pé láti kékeré ni ẹ̀yin ti mo ìwé-mímọ́ ní. Èyí le è sọ yín di ọlọgbọ́n fún ìgbàlà nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ nínú0 krístì Jésù. 16 Gbogbo ìwé-mímọ́ ni ó ní ìmísí Ọlọ́run. Ò ní èrè fún ìkọ́ni, fún ìtọ́ka sí ibi, fun ibawi, ati fun ikoni ni ododo. 17 Èyí rí bẹ́ẹ̀ ki eniyan Ololrn ki o le è pe, tí ó múra sílẹ̀ fun gbogbo ise rere.