1 Nítorínà ìwọ ọmọ mi, ẹ jẹ́ alágbára nínú ore-ọ̀fẹ́ tí ó wà nínú Krístì Jésù. 2 Àwọn ohun tí ẹ ti gbọ́ lọ́dọ̀ mi láàrín àwọn ẹlẹ́rìí púpọ̀, ẹ fi lé àwọn olóòtọ́ ènìyàn lọ́wọ́ tí wọn yí ò le kọ́ àwọn ẹlòmíràn. 3 Ẹ bá mi pín nínú ìpọ́njú mi, bí ọmọ ogun rere Krístì Jésù. 4 Kò sí ẹni tí ń jagun tí ó n fi ohun ayé yìí di ara rẹ̀, kí ó le mú inú ọ̀gá ogun rẹ̀ dùn 5 Bẹ́ ẹ̀ gẹ́gẹ́, bí ẹnikẹ́ni bá sì ń sáré, a kìí dé e ní adé bíkòse pé ó bá pa ìlànà mọ́. 6 Ó pan dandan pé kí àgbẹ̀ tí ó ń se làálàá kọ́kọ́ gba ìpín rẹ̀ nínú èrè oko. 7 Ẹ ronú nìpa ǹkan tí mo ń sọ, nítorí Ọlọ́run yí ó fún yín ní òye ní gbogbo ǹkan. 8 Rántí Jésù Kristì, láti inú irú ọmọ Dáfídì, tí a jí dìde kúrò nínú òkú. Gẹ́gé bí ìhìnrere mi, 9 nínú èyítí mo ń jìyà títí dé inú ìdè gẹ́gẹ́ bí ọ̀daràn. Ṣùgbọ́n a kò de ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. 10 Nítorínà mo farada ohun gbogbo fún àwon tí a yàn, kí wọn kí ò le gba ìgbàlà tí ó wà nínú Krístì Jésù, pẹ̀lú ògo ayérayé. 11 Ọ̀rọ̀ yí jẹ́ òtítọ́: "tí a bá ti kú pẹ̀lú rẹ̀, àwa yí ò sì yè pèlú rẹ̀. 12 Bí àwa bá faradà, a ó tún báa jọba. Bí àwa bá sẹ́ ẹ, òun náà yí ò sì sẹ́ wa. 13 Bí àwa bá jẹ́ aláìlóòtọ́, òun jẹ́ olótìtọ́, nítorí òun kò le sẹ́ ara rẹ̀. 14 Ẹ máa rán wọn létí ǹkan wọ̀nyí. Ẹ kìlọ̀ fún wọn níwájú Ọlọ́run kí wọn kí ó má ní èdè àìyedè nípa ọ̀rọ̀. Nítorí èyí kò sí ohun tí ó wúlò. Nítorí èyí ìparun wà fún àwọn tí kò bá gbọ́. 15 Sa ipá à rẹ láti fi ara rẹ hàn fún Ọlọ́run bí ẹnití ó ye, òsìsẹ́ tí kò ní ìdí láti tijú, tí ó ń kọ́ ọ̀rọ̀ òtítọ́ bí ó ti yẹ. 16 Ẹ yàgò fún ọ̀rọ̀ asán, tí ó ń lọsíwájú àti síwájú si àìwàbí Ọlọ́run. 17 Ọ̀rọ̀ wọ́n gbilẹ̀ bí ====. Lá ra wọn ni Hímánéùsì àti Fígélù. 18 Èyí ni àwọn ènìyàn tí ó ti sìnà ní ti òtítọ́. Wọ́n sọ wípé àjíǹde ti sẹlẹ̀. Wọ́n sì mú ìgbàgbọ́ àwọn ẹlòmíràn subú. 19 Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ìpìlẹ̀ Olúwa tí ó dájú dúró. Ó ní àkọlé yìí: "Olúwa mọ àwọn tí ó jẹ́ tirẹ̀" àti pẹ̀lu kí " gbogbo eni tí ó ń pe orúkọ Olúwa yàg` fún àìsòdodo." 20 Nínú ilé ọlọ́rọ, kìí se ohun èlò wúrà àti fàdákà nìkan ni ó wà. ohun èlò igi àti amọ̀ náà wà pẹ̀lú. Òmíràn fún lílò tí ó ní ọlá, àti òmíràn fún àìlọ́lá. 21 Bí ẹnikẹ́ni bá wẹ ara rẹ̀ mọ́ kúrò ní ìlò àìlọ́lá, ó di ohun èlò ọlá. A yà á sọ́tọ̀ ;ó sì yẹ fún ìlò Olúwa, tí a sì pèsè sílẹ̀ fún gbogbo isẹ́ rere. 22 Sá fún ìfẹ́kúfẹ̀ ọ̀dọ́.Máa lépa òdodo, ìgbàgbọ́, ìfẹ́, àti àlààfíà pẹ̀lú àwọn tí ó ń pe orúkọ Olúwa láti inú ọkàn tí ó mọ́. 23 Ṣùgbọ́n lòdì sí ìbéèrè agọ̀ àti aláìmọkan. O mọ̀ wípé a máa dá èdè àìyedè sílẹ̀. 24 Òsìsẹ́ Olúwa kò gbọdọ̀ jà. Dípò béè ó gbọ́dọ̀ ní ìwà pẹ̀lẹ́ sí gbogbo ènìyàn, kí ó le è kóni, àti kí ó ní sùúrù. 25 Nínú ìwà pẹ̀lẹ́ o gbọdọ̀ le kọ́ àwọn tí ó lòdì síi. Ọlọ́run le è fún wọn ní ìrònúpìwàdà tí wọn yíò fi nì ìmọ̀ òtítọ́. 26 Wọ́n le è ronú jinlẹ̀ kí wọn sí kúrò nínu pańpẹ́ èsù, lẹ́yìn ìgbà tí ó ti dè wọ́n fun ete re.