1 Pọ́ọ́lù, Àpóstélì ti Krìstì Jèsú nìpa ìfẹ Ọlọ́run, gẹ̀gẹ̀ bì ìlérí ìyè tíó wà nínú Krístì Jésù, 2 sí Tìmótíù, olùfẹ́ ọmọ: Ore Ọ̀fẹ́, àánú, àti àlàáfíà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wa àti KrístìJésù Olúwa wa. 3 Mo dúpé lọ́wọ́ Ọlọ́run, tí mò ń sìn gẹ́gẹ́ bí àwọn baba ńlá mí ti ṣe, pẹ̀lú ẹ̀rí-ọkàn tí ó mọ, bí mo se ń se ìrántí yín lemọ́lemọ́ nínú àdúrà mi ní òru àti ní ọ̀sán. 4 Bí mo se ń rántí omijé re, mo fẹ́ làti rí ọ, kí a le è fi ayọ̀ kún mi. 5 A ti mú ìgbàgbọ́ à ì lẹ́tàn rẹ wá sí ìrántí mi, èyí tí ó kọ́kọ́ wà nínú ìyá-ńlá rẹ Lóísí àti ìyá rẹ Yùníisì, mo sì ní ìdánilójú pé ó wà nínú rẹ náà. 6 Nítorí ìdí èyí ni mo se ń rán ọ létí láti ru ẹ̀bùn Ọlọ́run nínú rẹ sókè, èyí tí o rígbà nípa gbígbé ọwọ́ mi lé ọ. 7 Nítorípé Ọlọ́run kò fún wa ní ẹ̀mí ẹ̀rù, bíkòse ti agbára àti ìfẹ́ àti ìkóra ẹni ní ìjànu. 8 Nítorínà má se tijú ẹ̀rí nípa Olúwa wa, tàbí èmi, Póólù, òǹdè rẹ̀. Ṣùgbọ́n, se alábàpín nínú ìjìyà fún ìyìnrere nípasẹ̀ agbára Ọlọ́run. 9 Ọlọ́run ni ó gbà wá ó sì pẹ̀ wá pẹ̀lú ìpè mímọ́. Ó se èyí, kì íse gẹ́gẹ́ bí isẹ́ wa, ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí ète àti ore ọ̀fẹ́ rẹ̀. Ó fún wa ní ǹkan wọ̀nyí nínú Krístì Jésù kí ìgbà kí ó tó bẹ̀rẹ̀. 10 Ṣùgbọ́n nísissìnyí ati fi ìgbàlà Ọlọ́run hàn nípa ìfarahàn Olùgbàlà wa Krístì Jésù. Krístì ni ó fi òpin sí ikú ó sì mú ìyè tí kò lópin wá sí ìmọ́lẹ̀ nípasẹ̀ ìyìnrẹrẹ. 11 Nítorí èyí, a yàn mí gẹ́gẹ̀ bí oníwàásù, àpóstélì, àti olùkóni. 12 Nítorí ìdí èyí èmi ná ń jìyà ǹkàn wọ̀nyí. Ṣùgbọ́n ojú kò tì mí, nítorí mo mọ ẹni tí mo gbàgbọ̀. Mo ní ìdánilójú wípé ó le pa èyí tí mo ti fi fún n títí di ọjọ́ náà. 13 Di àpẹ̀ẹrẹ àwọn ọ̀rọ̀ òtítọ́ tí ìwọ́ ti gbọ́ lọ́dọ̀ mi mú, pẹ̀lú ìgbàgbọ́ àti ìfẹ́ tí ó wà nínú Krístì Jésù. 14 Ohun rere tí Ọlọ́run fi sí ìkáwọ́ rẹ, pa á mọ́ nípasẹ̀ Ẹ̀mí mímọ́, tí ó ń gbé nínú wa. 15 Ẹ mo èyí, pé gbogbo àwọn tí ó gbé ní Ásíà yípadà kúrò lódò mi. Nínú ìpín yí ni Fígélù àti Hérmógénì. 16 Kí Olúwa fi àánú fún ilé ónésífórù, nítorí ó ma ń tùmí lára nígbà púpọ̀ kò sì tijú nítorí ẹ̀wọ̀n mi. 17 Dípò bẹ́ẹ̀, nígbàtí ó wà ní Rómù, ó wá mi gidigidi ó sì rí mi. 18 Kí Olúwa kí ó fifún kí ó lè rí àánú gbà lọ́dọ̀ rẹ̀ ní ọjọ́ naa. GBogbo ona ti o ti ran mi lowo ni Efesu, ni e mo daradara.