1 Mo pàse yí fún ọ níwájú Ọlọ́run àti Krístì Jésù, ẹni tí yí ó se ìdájọ́ alààyè àti òkú, àti nítorí ìfarahàn rẹ̀ àti ìjọba rẹ̀. 2 Wàásù ọ̀rọ̀ náà. Gbáradì nígbà tó wọ̀ àti nígbà tí kò wọ̀. Bániwí, se ìtọ́ni, se ìgbani-níyànjú, pẹ̀lú gbogbo sùúrù àti ẹ̀kọ́. 3 Nítorípé ìgbà náà yí ò dé nígbà tí àwọn ènìyàn kì yí ò le gba ẹ̀kọ́ tí ó yè koro.Sùgbọ́n wọn yí ò kó àwọn olùkọ́ jọ fún ìfẹ́kúfẹ̌ ara wọn. Wọn yí ò ma rin etí wọn. 4 Wọn ó yí etí wọn kúrò nínú òtítọ́; wọn yí ò si fi etí sí ìtàn asán. 5 Ṣùgbọ́n ìwo, máa se pẹ̀lẹ́ nínú ohun gbogbo. Farada ìyà; se isẹ́ ajíhìnrere; se isẹ́ ìsìn rẹ. 6 Nítorí a ń fi mí rúbọ nísisìyí. Àkókò àtilọ mi ti dé. 7 Èmi ti ja ìjà rere; èmi ti parí iré-ìje náà; èmi ti pa ìgbàgbọ́ mọ́. 8 A ti fi adé òdodo lélẹ̀ fún mi, tí Olúwa, onídàjọ́ òdodo, yí ò fifún mi lí ọjọ́ nà, kì í sì íṣe fún èmi nìkan, ṣùgbọn fún gbogbo àwọn tí ó ti fẹ́ ìfarahàn rẹ̀. 9 Sa ipá rẹ láti tètè tọ̀ mí wá. 10 Nítorí Dẹ́mà tí kọ̀ mí sílẹ̀. Ó fẹ́ ayé ìsisìyí, ó sì ti lọ sí Tẹssalóníkà. Kírísẹ́nì lọ sí Galatia, àti Títù sí Dalmatia. 11 Lúkù nìkan li ó wà pẹ̀lú mi. Mú Mákù wá pẹ̀lú rẹ nítorí ó wúlò fún mi fun iṣẹ. 12 Mo rán Tíkíkúsì lọ sí Éfẹ́sù. 13 Aṣọ tí mo fi sílẹ̀ ní Tróásì pẹ̀lú Kápúsì, mú n wá nígbàtí ìwọ bá mbọ̀ , àti àwọn ìwe, pàápà àwọn ìwé aláwọ. 14 Alẹsanderu alágbẹ̀dẹ bàbà ṣe mí ní ibi púpọ̀. Olúwa yíò sán fún u gẹ́gẹ́ bí ìsẹ rẹ̀. 15 Kí ìwọ kí ó máa ṣọ́ra fún n, nítorí tí ó kọ ojú ìjà sí ìwásù wa púpọ̀. 16 Kò sí ẹnití ó bá mi gba ẹjọ́ ro. Ṣùgbọ́n gbogbo ènìyàn li o kọ̀ mí sílẹ̀. Kí á má ṣe kà á sí wọn lí ọrùn. 17 Ṣùgbọ́n Olúwa gba ẹjọ́ mi ro ó sì fún mi lágbára pe, nípasẹ̀ mi, kí ìkéde kí ó le wá sí ìmúsẹ, àti pé kí gbogbo àwọn Kèfèrí kí ó le gbọ́. A si gbà mi kúrò lí ẹnu kìnìún nì. 18 Olúwa yíò yọ mí kúrò nínú ìse búburú gbogbo, yíò si gbé mi dé inú ìjọba ọ̀run rẹ̀. Sí ẹnití ògo wà fún láí àti láíláí. Àmín. 19 Kí Pìrìsíllà àti Àkúílà, àti ilé Ònísífórọ́sì. 20 Erastu sí dúró ní Korinti, ṣùgbọ́n mo fi Trofimu sílẹ̀ ní Míletu nínú àìsàn. 21 Sa ipá rẹ láti tètè wá ṣájú ìgbà òtútù. Eubulusu ki yin, atipudenisi, linusi, Claudia, àti gbogbo àwọn arákùnrin. 22 Kí Olúwa wà pẹ̀lú ẹ̀mi rẹ. KÍ ore-ọ̀fẹ́ wá pẹ̀lú yín.