Orí Kẹ̀sán

1 Lẹ́yìn náà ańgẹ́lì kaàrún fọn fère rẹ̀. Mo rí íráwọ̀ kan lojú ọ̀run tó ti jábọ́ sórí ilẹ̀. Íràwọ̀ náà ni a fún ní kọ́kọ́rọ́ láti ṣí ìlẹ̀kùn ọ̀gbun ìsàlẹ̀. 2 Ó ṣí ìlẹkùn ọ̀gbun ìsàlẹ náà, èéfín sì jáde sókè láti ẹnu ọ̀nà náà bíi èéfín láti inúun ìléru ńlá. Òòrùn àti afẹ́fẹ́ yípadà sí dúdú nípa èéfín tó tújáde láti ẹnu ọ̀gbun. 3 Láti inú èéfín náà ni àwọn esú wá sórí ilẹ̀ayé, àti pé a fún wọn ní agbára bíi ti àkekèé lóríi ayé. 4 A sọ fún wọn kí wọn máṣe pa koríko orí ilẹ̀ lára tàbí ewéko tàbí igi, bí kò ṣe àwọn ènìyàn tí kò ní èdìdì Ọlọ́run ní iwájúu wọn. 5 A kò fún wọn ní ààyè láti pa àwọn ènìyàn náà, bíkòṣe láti pọ́n wọn lójú fún osù márùn. 6 Ní ìgbà náà awọn ènìyàn yóò wá ikú, ṣùgbọ́n wọn kì yóò rii. Wọn ó ṣàníyàn gidigidi láti kú, ṣùgbọ́n ikú yóò sá fún wọn. 7 Ìrísí àwọn esú náà dàbíi àwọn ẹṣin tí wọ́n múra fún ogun. Lórii wọn ni àwọn nǹkan bíi adée wúrà, ìrísí ojú wọn dàbíi ti àwọn ènìyàn. 8 Wọ́n ní irun bíi ti àwọn obìnrin, àti pé eyín wọn dàbíi eyín àwọn kìnìún. 9 Wọ́n ní àwọn ìgbàyà bíi àwọn ìgbàyà irin, bẹ́ẹ̀ ni ìró apá wọn dàbíi ti ìró ọ̀pọ̀ kẹ̀kẹ́ogun àti àwọn ẹṣin tó ńsáré lo sí ogun. 10 Wọ́n ní ìrù pẹ̀lú ìtani bíi ti àwọn àkekèé; nínú ìrù wọn, wọ́n ní agbára láti pa ènìyàn lára fún oṣù márùún. 11 Wọ́n ní àwọn ańgẹ́lì ọ̀gbun ìsàlẹ̀ bíi ọba lóríi wọn. Orúkọ rẹ̀ ní èdè Hébérù jẹ́ Abádọ́nì, àti ní Gíríkì ní orúkọ rẹ̀ ńjé Apolíónì. 12 Ègbé àkọ́kọ́ ti kọjá lọ. Wòó! Lẹ́yìn èyí àjálù ńlá méjì sì ń bọ̀. 13 Ańgélì kẹfà sì fọn fèrèe rẹ̀, mo sì gbọ́ ohùn kan tó ńbọ̀ láti inú àwọn ìwo ti orí pẹpẹ wúrà tí ó wà níwájú Ọlọ́run. 14 Ohùn náà sọ fún ańgẹ́lì kẹfà tó ni fèrè náà, "Tú àwọn ańgélì mẹ́rin tí wọ́n gbédè sí odò ńláa Eúfretì." 15 Àwọn ańgélì mẹ́rẹ̀rin tí wọn ti múra sílẹ̀ fún wákàtí náà, ní ọ́jọ́ náà, ní oṣù náà, àti ní ọdún náà, a tú sílẹ̀ láti pa ìdá kan nínúun méta ìran ènìyàn. 16 Iye àwọn ọmọ ogun ẹlẹ́ṣin jẹ́ igba mílíọ́nù. Mo gbọ́ iye wọn. 17 Báyí ni mo ṣé rí àwọn ẹṣin ní ojú ìranàn mi ati àwọn tí ó gùn wọ́n: àwọn ìgbaàyà wọn pupa bíi iná, olomi aró àti aláwọ̀ èsúrú. Orí àwọn ẹṣin náà jọ orí àwọn kìnìún, àti láti ẹnu wọn ni iná ti jáde, èéfín, àti súfúrú. 18 Ìdákan nínúun mẹ́ta àwọn ènìyàn ni àwọn àjàlù mẹ́ta wọ̀nyí pa: iná, èéfín, àti súfùrù tó ti ẹnu wọn jáde. 19 Nítorí agbára àwọn ẹṣin náà wà ní ẹnu wọn àti ní ìrùu wọn - nítorí ìrùu wọn dàbí àwọn ejò, àti pé wọn ní orí tí wọn fí ńdógbẹ́ sára ènìyàn. 20 Ìran ènìyàn tó kù, àwọn tí àjálù buburú wọ̀nyí kò tíì pa, kò ronú pìwàdà àìṣedédé tí wọ́n ti ṣe, bẹ́ẹ̀ wọn ko jáwọ́ọ sínsin ẹ̀mí buburú àti ère wúrà, fàdákà, idẹ, òkúta, àti igi - àwọn nǹkan tí kò lè ríran, gbọ́ràn, tàbí rìn. 21 Bẹ́ẹ̀ni wọn kò yípadà nínú ìwà ìpànìyàn wọn, iṣẹ́ oṣó, ìfẹ́kúfẹ́ ara tàbí ìwà olèjíjà.