1 Nígbàtí Ọ̀dọ́-Àgùtàn náà ṣí èdìdì keje náà, gbogbo ọ̀run pa rọ́rọ́ fún bíi ọgbọ̀n ìṣẹ́jú. 2 Lẹ́yìn náà ni mo rí àwọn áńgẹ́lì méje tí wọ́n dúró níwájú Ọlọ́run, a sì fún wọn ní àwọn fèèrè méje. 3 Áńgẹ́lì míràn sì wá, pẹ̀lú àwokòtò tùràrí wúrà lọ́wọ́ ọ rẹ̀, ó sì dúró níwájú pẹpẹ tùràrí. A sì fún un ní tùràrì púpọ̀ kí ó le fi rúbọ pẹ̀lú àdúrà gbogbo àwọn onígbàgbọ́ níwájú ìtẹ́ tùràrí wúrà náà. 4 Èéfín tùràrí náà, pẹ̀lú àwọn àdúrà àwọn onígbàgbọ́, sì gòkè tọ Ọlọ́run lọ láti ọwọ́ ańgẹ́lí náà. 5 Áńgẹ́lì náà sì gbé àwokòtò tùràrí náà ó sì fi iná orí pẹpẹ kún inú rẹ̀. Lẹ́yìn náà ló lẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀, ó sì fọ́nká pẹ̀lú ààrá, ìrọ́kẹ̀kẹ̀, ìtànsán mọ̀nàmọ́ná àti ilẹ̀-mímì. 6 Àwọn áńgẹ́lì méje tí wọ́n ní fèèrè méje lọ́wọ́ náà ti múra tán láti fọn wọ́n. 7 Ańgẹ́lì àkọ́kọ́ fọn fèèrè rẹ̀, òjò dídì àti iná tí ó dàpọ̀ mọ ẹ̀jẹ̀ sì bo ilẹ̀ tóbẹ̀ tí ìdá kan nínú mẹ́ta ilẹ̀, àwọn igi àti gbogbo koríko tútù fi jóná dànù. 8 Áńgẹ́lì kejì fọn fèèrè rẹ̀, a sì sọ nǹkan tí ó dàbi òkè ńlá tí ó ń jó fún iná sínú òkun. Ìdá kan nínú mẹ́ta òkun náà sì di ẹ̀jẹ̀, 9 idá kan nínú mẹ́ta àwọn ẹ̀dá-alààyè inú òkun náà sì kú, bẹ́ẹ̀ni ìdá kan nínú mẹ́ta àwọn ọkọ̀ ojú omi sì bàjẹ́. 10 Áńgẹ́lì kẹta fọn fèèrè rẹ̀, ìràwọ̀ ńlá kan tí ó ń jò bí iná sì já láti ojú òfurufú sí inú ìdá kan nínú mẹ́ta àwọn odo àti àwọn orísun omi. 11 Iwọ sì ni orúkọ ìràwọ̀ náà. Ìdá kan nínú mẹ́ta àwọn omi náà sì di kíkorò bíi iwọ, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn sì kú láti ipasẹ̀ àwọn omi tí ó di kíkorò náà. 12 Áńgẹ́lì kẹ̀rin sì fọn feèrè rẹ̀, a sì kọlu ìdá kan nínú mẹ́ta òrùn, òsùpá àti àwọn ìràwọ̀. Fún ìdí èyi, ìdá kan nínú mẹ́ta wọn ṣókùnkùn; kò sì sí ìmọ́lẹ̀ ní ìdá kan nínú mẹ́ta ojú-ọjọ́ àti ìdá kan nínú mẹ́ta alẹ́. 13 Mo wò, mo sì rí ẹyẹ idì kan tí ó ń fò ní agbede méjì òfurufú, tí ó sì ń kígbe ní ohùn rara pé, "Ègbé, ègbé, ègbé, ni fún àwọn tí ó ń gbé inú ayé nítorí àwọn ohùn ìpè yókù tí àwọn áńgẹ́lì mẹ́ta yókù fẹ́ fọn."