1 Lẹ́yiǹ eyìí nì mo rí àwon ángélì mérin tí wọ́n dúró lórígun mérèrin aíyé, ódá afẹ́fẹ́ orígun mẹ́rẹ̀rin ayé naa dúró tóbè tí kì yio sì félu aíyé, òkun tàbí sí igi kankan. 2 mo sì tún rí ángẹ́lì mínràn tí oún ti ìlà orùn bòwá, ti òun ti èdìdí Ọlọ́run alàyè lówó. Ó sì kérara sí àwon ángèlì mérèrin tí a fún ní ìyònda lati kolu aíyé, àti òkun 3 wípé, ''máse pa aíyé, òkun tàbí àwon igi lára títí a o fi fi èdìdí sí iwájú orí ìránsẹ́ olorun wa.'' 4 Mo sì gbó iye àwon tí afi èdìdí naa fun ni: ọkẹ meje o le ẹgbaaji, tí afi èdìdí naa fun lati gbogbo ẹ̀yà àwon ènìyàn Israẹli: 5 ẹgbẹ̀ruń méjìlá lati ẹ̀yà Juda, ẹgbẹ̀ruń méjìlá lati ẹ̀yà Rubeni, ẹgbẹ̀ruń méjìlá lati ẹ̀yà Gadi, 6 ẹgbẹ̀ruń méjìlá lati ẹ̀yà Asha, ẹgbẹ̀ruń méjìlá lati ẹ̀yà Naphtali, ẹgbẹ̀ruń méjìlá lati ẹ̀yà Manaseh, 7 ẹgbẹ̀ruń méjìlá lati ẹ̀yà Simioni, ẹgbẹ̀ruń méjìlá lati ẹ̀yà Lefi, ẹgbẹ̀ruń méjìlá lati ẹ̀yà Issaka, 8 ẹgbẹ̀ruń méjìlá lati ẹ̀yà Sebuluni, ẹgbẹ̀ruń méjìlá lati ẹ̀yà Josẹfu, àti ẹgbẹ̀ruń méjìlá lati ẹ̀yà Benjamani ni asì se èdìdi rẹ̀. 9 lẹ́yìn eyi ni, si kíyèsi, ọ̀pọ̀ ènìyàn tí a kò le sàkàwe rè lati gbogbo orílẹ̀ èdè, ẹ̀yà, èyàn àti èdè dúró níwájú ìtẹ́ àti níwájú ọ̀dọ́ àgùtàn. Wón wọ asọ funfun pèlú imọ̀ ọ̀pẹ lọ́wọ́ wón sansan, 10 wón sí n ké ni ohùn rara pé: ''ìgbàlà jẹ́ ti Ọlọ́run, eni tí o joko lori ìtẹ́ àti sí ọ̀dọ́ àgùntàn'' 11 gbogbo àwon ángẹ́lì dúró yíká ìtẹ́ naa ati yíká àwon àgbàgbà àní yíká àwon ẹ̀dá alàyè mẹ́rin naa, wón wólẹ̀ níwájú ìtẹ́ wón sì jọ́sìn fún Ọlọ́run, 12 wípé, ''Amin! ìyìn, ògo, ọgbọ́n, ọpẹ́, ọlá, agbára, ati ipá jẹ́ ti Ọlọ́run wa láí àti láílai! Àmín!'' 13 nigbana ni ọ̀kan nínú àwon àgbàgbà naa bi mí wípé, ''awon wo nìwòn yí, tí awọ̀ ní asọ funfun, níbo ni wọ́n sì ti wá?'' 14 mo si dáhùn wípé, ''Olúwa mi, ìwọ́ mọ̀," ó sì wí fún mi pé, "wòn yí ni àwon tí ó ti la ìdàmú ńlá kọjá. Tí wón sì ti wẹ asọ won mọ́ nínú ẹ̀jẹ̀ ọ̀dọ́ àgùntàn. 15 Fún ìdí èyí ni, wọ́n wà níwájú ìtẹ́ Ọlọ́run, wón sìn ń jọ́sìn fún n ní ọ̀san àti ní òru ní tẹ́mpílì rẹ̀. Ẹni tí ó jókǒ ní orí ìtẹ́ yíò tẹ́ àgọ́ ọ rẹ̀ sórí wọn. 16 Ebi kì yíò pawón mọ́, bẹ́ẹ̀ni òrùngbẹ kì yíò gbẹ wọ́n mọ́. Òruǹ ki yio pawón tabi ọwọ́ iná líle. 17 Nítorí ọ̀dọ́ àgùntàn tíó wà ní orí ìtẹ́ ni yíò jẹ́ olùsọ́ wọn, òun ó sì darí wọn sí orísun omi ìyè, Ọlọ́run yio si nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn.''