Orí Kẹfà

1 Mo sì wò ó nígbàtí ọ̀dọ́ àgùntàn ṣí ọ̀kan nínú u èdìdí mẹ̀je , mo sì gbọ́ tí ọ̀kan nínú àwọn ohun alàyè mẹ́rin náà so ní ohùn tí ó dàbí àrá, "Wá!" 2 Mo wò, mo sì rí ẹṣin funfun, olùwa rẹ̀ sí ì mú ọkọ̀ dání, a sì fun ní adé. Ó sì jáde gégé bí olúborí láti borí. 3 Nígbàtí ọ̀dọ́ àgùntàn ná à si ṣí èdìdí kejì, mo gbọ́ tí ohun alàyè kejì wípé, "Wa!" 4 Nígbànná à ni ẹṣin òmíràn jáde- pupa- a sì fún ẹni ti ó ń wa ní àṣẹ láti mú ìfọ̀kànbalẹ́ kúrò nínú ayé, kí àwọn ènìyàn rẹ̀ le pa ara wọn. A sì fún òlùwa rẹ̀ ní idà tí ó tóbi. 5 Nígbàtí olùwa rẹ̀ sí ṣì í èdìdí kẹrin, mo gbọ́ tí ohun alàyé kẹta wípé, "Wa! Wòó" Mo rí ẹṣin dúdú, olùwà rẹ̀ si mu ìwọn aláwẹ́ méjì ní ọwọ rẹ. 6 Mo gbọ́ oun tí ó dà bìi ohùn láàrin àwọn alàyè mẹ́rẹ̀ẹ̀rin na so wípé, "òsùwọn àlìkámà kan fún owó idẹ kan, àti osùwọn ọkà bálì mẹ́ta fún owó idẹ kan " ṣùgbọ́n maṣẹ pa òróró àti ọtí wáìnì náà lára. 7 Nígbàtí ọ̀dọ́ àgùntàn náà sì ṣí èdìdí kerin, mo gbọ́ tí ohùn èkẹrin alàyè náà wípé, "Wa!" 8 Nígbànáà ni mo rí ẹṣin tínrín. Olùwà tí ó wà ní orí rẹ̀ ni à sì pè ní ikú, àti ipò òkú sì ń tẹ̀lé e. A sì fún wọn ní àṣẹ lóríi ìdá kan nínú u ìdá mẹ́rin ti ayé, láti pa pẹ̀lú u idà, iyàn àti àjàkálẹ̀ àrùn, àti ẹranko ti búburú ayé. 9 Nígbàtí ọ̀dọ́ àgùntàn sí ṣì í èdìdí kaàrún, mo rí ni abẹ́ ẹ pẹpe àwọn ọkàn tí a ti pa nítorí tí ọ̀rọ ọlọ́run àti ti ẹ̀ri tí wọ́n dì mú. 10 Wọ́n sì kígbe jáde ní ohùn rara, "Ó ti pẹ́tó, olùdarí ohun gbogbo, mímọ́ àti olótìítọ́" , tí ìwọ yóò dájọ́ àwọn tí wọ́n ń gbé ní ayé, àti tí ìwọ yóò jà fún ẹ̀jẹ wa? 11 Nígbànáà ni a fún olúkúlùkù wọn ní aṣọ funfun, a sí sọ fún wọn kí wọn dúró díẹ̀ si títí di ìgbà tí a ó fi kàn sí àwọn ìyókù ọmọ ọ̀dọ àti àwọn arákùnrin àti arábìnrin tí a ní láti pa gẹ́gé bí a ṣe pa wọ́n. 12 Nígbàtí ọ̀dọ́ àgùntàn sí ṣì í èdìdí kẹfà, mo wò ó, ilẹ̀ rírì si ṣẹlẹ̀. Òrún sì di dúdú gẹ́gẹ́ bí i aṣọ ọ̀fọ́ onírun, òṣùpá àtàntàn náà sì dàbí ẹ̀jẹ́. 13 Àwon ìràwọ̀ ojú ọ̀run si jábọ́ sí ayé, gẹ́gẹ́ bí i èṣo tí kò pọ́n igi ọ̀pọ̀tọ́ ṣe má ń jábọ́ fúnrarẹ̀ nígbàtí ìjí bá jà. 14 Ojú ọ̀run pòórá gẹ́gẹ́ bíi èdìdí tí a ká.Gbogbo òkè àti pẹ̀tẹ́lẹ̀ ni a sì mú kúrò ni àye wọn. 15 Nígbànáà ni àwọn ọba ayé àti awọn ènìyaǹ pàtàkì, àti àwọn ààrẹ, àwọn olówó, àwọn alágbára, àti àwọn ìyóókù, ẹrú àti àwon òmìnira sá pamọ́ sínúu ihò ilẹ̀ àti nínú àpáta àwọn òkè 16 Wọ́n sì wí fún òkè àti àpáta, "Wó lé wa! Pa wá mọ́ kúrò lọ́wọ́ọ ojú ẹni tí ó joko lórí i ìtẹ́ àti lọ́wọ́ ọ ìbínú ọ̀dọ́ àgùntán 17 Nítorí ọjọ́ ńlá ìbínú náà ti dé. Ta ni yóò dúró?"