1 Lẹyìn èyí ni mo bà rí ìwé awọ kíká kan tí a kọ ǹkan sí níwájú àti lẹ́yìn lọ́wọ́ ọ̀tún Ẹni tó jókòó lórí ìtẹ́ náà, a sì fi èdìdì méje di ìwé náà. 2 Ni mo bá rí ángẹ́lì alágbára kan tó ń wí ni ohùn rara pé, "Tani ẹni tó yẹ láti ṣí íwé awọ kíká náà àti láti fọ́ àwọn èdìdì rẹ̀?" 3 Kò sì sí ẹnì kankan lọ́run, láyé àti ní ìsàlẹ̀ ayé ti ó lè ṣí ìwé awọ kíká náà àti láti kà á. 4 Mo sì sọkún kíkorò nítorí kò sẹ́nì kankan tí o yẹ láti ṣí ìwé awọ kíká náà àti láti kà á. 5 Ṣùgbọ́n ọ̀kan nínú àwọn àgbàgbà bá wí fún mi pé, "Má sọkún mọ́, ìwọ wòó, Kìnìhún ẹ̀ya Júdà náà, gbòǹgbò Dáfídì tí ṣégun. Òun ló le ṣí ìwé awọ kíká náà àti èdìdì méje rẹ̀." 6 Ni mo bá rí Ọ̀dọ́ Àgùtàn kan tí ó dúró ní ibi ìtẹ́, láàrin àwọn ẹ̀dá alàyè mẹ́rin náà, àti láàrin àwọn àgbàgbà náà. Ìrísí Rẹ̀ dàbi pé Ó ti kú. Ó ní ìwo méje àti ojú méje, àwọn èyí tí í ṣe Ẹ̀mí méje Ọlọ́run tí a rán jáde sí gbogbo ayé. 7 Ó lọ, Ó si gbá ìwé awọ kíká náà mú kúrò lọ́wọ́ ọ̀tún Ẹni náà tó jókòó lórí ìtẹ́ náà. 8 Nígbàtí Ó ti gba ìwé kíká náà, àwọn ẹ̀dá alàyè mẹrín náà, àti àwọn àgbàgbà mẹ́rìnlélógún náà wólẹ̀ níwájú Ọ̀dọ́ Àgùtà náà. Ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ní Hápù, àti abọ́ wúrà tí ó kún fún tùràmí, èyi tó jẹ́ àwọn àdúrà àwọn ènìyàn mímọ́ Ọlọ́run. 9 Orin titun ni wọ́n mú bọnu pé, "Ẹ̀yin náà ló yẹ, láti gba ìwé awọ kíká náà, àti láti ṣí àwọn èdìdì rẹ̀. Nítorí a ti pa yín, Ẹ sì ti ra àwọn ènìyan fún Ọlọ́run láti inú gbogbo ẹ̀yà, èdè, ènìyàn àti orílẹ̀-èdè pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ yín. 10 Ẹ sì ti sọ wọ́n di ìjọba kan àti àwọn àlùfáà láti sin Ọlọ́run wa, wọ́n ò sì tún jọba láyé." 11 Lẹ́yìn náà, ni mo bá wò, tí mo sì gbọ́ ìró ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ángẹ́lì tí wọ́n yí ìtẹ́ náà ká àti àwọn ẹ̀dá alàyè mẹ́rin náà pẹ̀lú àwọn àgbàgbà náà. Iye wọ́ jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá lọ́nà ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá lọ́nà ẹgbẹẹ̀gbẹ̀rún. 12 Pẹ̀lú ohùn rara ni wọ́n wípé, "Yíyẹ ni Ọ̀dọ Àgùtàn náà tí a pa, láti gba agbára, ọlá, ọgbọ̀n, ipá, iyì, ògo, àti ìyìn." 13 Ni mo bá gbọ́ gbogbo ẹ̀dá tí ń bẹ lọ́run, láyé, lábẹ́ ayé àti lórí òkun --gbogbo ohun tí ń bẹ nínú rẹ̀-- tí wọ́n ń wípé, "Sí Ẹni tó jókòó lórí ìtẹ́ náà, àti sí Ọ̀dọ́ Àgùtàn náà ni ìyìn, iyì, ògo àti agbára láti jọba títí láí." 14 Àwọn ẹ́dá alàyè mẹ́rin náà sì wípé, "Àmín" tí àwọn àgbàgbà náà sì wólẹ̀, wọ́n sì sìn.