1 Lẹ́yìn nkàn wọ̀nyí ni mo bá wò, tí mo sì rí ìlẹ̀kùn ṣíṣí kan ní ọ̀run. Ohùn àkọ́kọ́ tí mó ti gbọ́ ń bá mi sọ̀rọ̀ bí fèrè idẹ wípé, "Wá sókè ní ìhín, èmi ó sì fi ǹkan tí ò gbọ́dọ̀ ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn àwọn nkàn wọ̀nyí hàn ọ́" 2 Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ mo sì wà nínú ẹ̀mí, ni mo bá rí níbẹ̀, ìtẹ́ kan ní ọ̀run, tí ẹnìkan sì jókòó lórí rẹ̀. 3 Ẹni náà tó jókòó lórí rẹ̀ dàbi jaspà àti kànílíànì. Òṣùmàrè kan sì yí ìtẹ́ náà ká. Òṣùmàrè náà sì dàbi ẹ́míràdì. 4 Àwọn ìtẹ́ mẹ́rìnlélógún sì yí ìtẹ́ náà ká, tí àwọn àgbààgbà mẹ́rìnlélógún tí wọ́n wọ aṣọ àlà, pẹ̀lú adé wúrà lórí wọn sì jókòó lórí àwọn ìtẹ́ náà 5 Ìtànṣán mọ̀nànmọ́nán, ìrọ́kẹ̀kẹ̀ àti ìró àrá tí ń sán, sì ń jáde láti ara ìtẹ́ náà. Fìtílà méje tíí ṣe ẹ̀mí méje Ọlọ́run sì ń tàn níwájú ìtẹ́ náà. 6 Òkun àwo, bíi krístálì sì wà níwájú ìtẹ́ náà. Àwọn ẹ̀dá alàyè mẹ́rin, tí wọ́n kún fún ojú níwájú àti lẹ́yìn sì wà láàrin ìtẹ́ náà, tí wọ́n sì tún yíi ká. 7 Ẹ̀dá alàyè àkọ́kọ́ náà si dàbí kìnìhún, ti èkejì si dàbí ọ̀dọ́ màálù, ẹ̀dá alàyè kẹ̀ta náà ní ojú bíi ti ọkùnrin, ẹlẹ́kẹ̀rin dàbi ẹyẹ idì tí ń fò. 8 Ọ̀kọ̀kan àwọn ẹ̀dá alàyè mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ní ìyẹ́ mẹ́fà tí ó kún fún ojú lókè àti lábẹ́. Lálẹ́ àti lójúmọmọ wọn kò dákẹ́ àti máa wípé, "Mímọ́, mímọ́, mímọ́ ni Olúwa Ọlọ́run Alágbára jùlọ, Ẹni tí ó ti wà, tí ó sì wà, tí yíó sì máa wà." 9 Ìgbàkíìgbà tí àwọn ẹ̀dá alàyè náà bá ń fi ògo, ọlá àti ọpẹ́ fún Ẹni náà tó jókòó lórí ìtẹ́ náà, Ẹni tó wà títí láí, 10 àwọn àgbàgbà mẹ́rìnlélógún náà a sì wólẹ̀ níwáju Ẹni náà tó jókòó lórí ìtẹ́ náà, wọ́n a sì júbà Rẹ̀, Ẹni tó wà títí láí. Wọn a sì tẹ́ àwọn adé wọn sílẹ̀ níwájú ìtẹ́ náà, wọn á wípé, 11 "Ẹ̀yin ni ó yẹ, Olúwa àti Ọlọ́run wa láti gba ògo àti ọlá àti agbára, nítorí Ẹ̀yin lẹ dá ohun gbogbo, àti pé nípa ìfẹọkàn yín ni wọ́n wà, tí a sì dá wọn."