1 Sí ángẹ́lì ìjọ ní Sádísì sí kộ: 'Èyí ni àwọn ọ̀rọ̀ ẹnití ó dí ẹ̀mí méje Ọlọ́run àti ìràwọ̀ méje mú. "Èmí mọ ohun tí o ti ṣe. Ìwọ ní ìyìn pé ẹwà láyé, ṣùgbọ́n ìwọ́ ti kù. 2 Jí ki o si fi okun fún éyì tó kù , nítorí ó ti fẹ́ kú, ṣùgbọ́ èmi kó tí rí iṣé yín ní pípé ní iwájú Ọlórun mi. 3 Ránti, nítorínà, ohun tí ìwọ ti gbà tí o sì ti gbọ́. Ṣe igbọnran si, kí o sì yípadà. Ṣùgbọ́n bí o bà jí dìde, Èmi yóò wá í olè, ìwọ kì ó sí ní mọ àkokònâ tí èmi yóò wá láti lòdì sí ọ. 4 Sùgbọ́n orúkọ àwọn ènìyan díẹ̀ ní Sádísì tí kò jẹ́ kí asọ wọn yí ẹ̀rẹ̀. Wọ́n yóò rìn pẹ̀lú mi, pẹ̀lú asọ funfun lára wọn nítorí ó yẹ wọ́n. 5 A o wọ ẹni tí ó bá ṣégun ní aṣo funfun, èmi kò sì ní pa orúkọ rẹ̀ kúrò nínu ìwé ìyè láilái, èmi yóò sì sọ orúkọ rẹ̀ níwájú Bàbá mǐ, àti níwájú àwọn ángẹ́lì rẹ̀. 6 Jẹ́ kí ẹni tí ó ní etí kí ó gbọ́ ohun tí Ẹ̀mí ń bá ìjọ sọ."" 7 Sí ángẹ́lì ti ìjọ ni Filadẹ́fíà kọ: 'Èyí ni ọ̀rọ̀ ẹni tí jẹ́ mímọ́ tí ó sì tọ́-ó di kọ́kọ́rọ́ Dáfídì mú.Ó ṣi kò sì sí ẹni tó le tìí, ó tǐ kò sẹ́ni tó le ṣi. 8 Èmi mọ hun tí ẹ ti ṣe, wòó, mo fi ilẹ̀kùn tó ṣí sílẹ̀ sí íwájú yín ti ẹnikẹ́ni kò le tì. Èmí mọ̀ wípé ìwọ́ ní agbára kékeré, síbẹ̀ ìwọ́ pa ọ̀rọ̀ mi mọ́, ìwọ kò sì sé orúkọ mi pẹ̀lú. 9 Wòó! Àwọn tí ó jẹ́ ti sínágọ̀gù sàtánì, àwọn tí wọ́n pe ara wọn ní ará Jû ṣùgbọ́n wọn kìí ṣe jû; dípò irọ́ ni wọ́n pa. Hún ò jẹ́ kí wọ́n wá wólẹ̀ àtẹlẹsẹ̀ rẹ, wọ́n yóò sì wá mọ̀ pé mo nífẹ̌ rẹ. 10 Nítorí ìwọ ti pa òfin mi mọ́ láti forítǐ, Èmi yóó pa ọ́ mọ́ ní wákàtí ìdánwó tí ń bọ̀ wá sí orí gbogbo àgbáyé, láti dán àwọn tí ó ńgbé inú ayé. 11 Èmi ń bọ̀ kánkán. Dǐmú ṣinṣin ohun tí o ní kí ẹnikẹ́ni má ṣe gba adé rẹ. 12 Èmí yóò sọ ẹni tó bá ṣẹ́gun di gbòngbòn ní ilé Ọlọ́run mi, Òun kì yóò jáde kúrò nínú rẹ̀ pẹ̀lú. Èmi yóò kọ orúkọ Ọlọ́run mi si lára, orúkọ ìlú Ọlọ́run mi (Jerúsálẹ́mù titun èyí tí ó sọ̀kalẹ̀ wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run mi ní ọ̀run), àti orúkọ titun mi. 13 Jẹ́ kí ẹni tí ó ní etí gbọ́ ohun ti Ẹ̀mí ń bá ìjọsọ. 14 Sí ángẹ́lì ti ìjọ ní Laodíkìa kọ: 'Wọ̀nyí ni ọ̀rọ̀ Àmín, ẹni tó tó gbẹ́kẹ̀lé àti ẹlẹ́rì òtítọ́ olùdárí gbogbo ẹ̀dá Ọlọ́run. 15 Èmí mọ̀ ohun tí o ti ṣe, àti pé ìwọ kò gbọ́ná bẹ́ẹ̀ ìwọ kòtutù. Èmì sì fẹ́ gbèrò pé kí ẹ tutù tàbí gbóná 16 Ǹjẹ́, nítorí ìwọ jẹ́ kògbónákòtutù- o kó gbóná tàbí tutù-Èmí ti ṣe tán làti pọ̀ ọ́ jáde kúrò lí ẹnù mi. 17 Nítorí ìwọ́ wípé, 'Èmi ní owo, mo ní ohunìní púpọ̀, mi ò sì ní lò ohunkóhun.' Ṣùgbọ́n ìwọ kò mọ̀ wípé ìwọ ni oṣe otoṣìjùlọ, ìkáàánú, tálákà, afọ́jú àti ìhòhò. 18 Tẹ́tísí ìmọ̀ran mi: Rà wúrà láti ọ̀dọ̀ mi tí ó ti la iná kọ ja kí ìwọ lè di olówó, àti kí o lè wọ aṣo funfun tí ó dára kí o má sì fi ìhòhò rẹ hàn, kí o sì fi òróró ojú rẹ kí o lè rírǎn. 19 Emi kọ́ gbogbo ẹni tí mo fẹ́ràn, àti èmi sì kó wọn bí wọn yóò ṣe gbé. Nítorínà, ẹní ìtara kí ẹ sì yípadà. 20 Wòó, mò ń dúró lẹ́bá ẹnu ọ̀nà mo sì ń kanlẹ̀kùn. Bí ẹnikẹ́ni bá gbọ́ ohùn mi tí ó sì ṣílẹ̀kùn pẹ̀lú, Èmi yóò wọ lé rẹ̀ láti jẹun pẹ̀lú rẹ̀ òun yóò sì wà pẹ̀lùmi 21 Ẹni tó bá sẹ́gun, Emi yóò fun ní àǹfàní làti jókô pẹ̀lúmi lórí ìtẹ́mi gẹ́gẹ́ bí èmi pẹ̀lú ti ṣẹ́gun tí mo sì jókô pẹ̀lú Bàbá mi lórí ìtẹ́ rẹ̀. 22 Jẹ́ kí ẹni tí ó ní etí gbọ́ ohun tí Ẹ̀mí ń bá ìjọsọ.