Orí Kejì

1 Sí ángẹ́lì náà nínú ìjọ Éfésù, kọ ìwé yìí: "Àwọn wọ̀nyí ni ọ̀rọ́ ẹnití ó di ìràwọ̀ méje náà mú ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀, ẹni tí ń rìn láàrin àwọn ọ̀pá fìtílà wúrà méje, èyí tíi se àmì fún ìjọ méje. 2 Èmi mọ ohun tí o ti se, isẹ́ takuntakun rẹ àti sùúrù pèlú ìfaradà rẹ. Mo mọ̀ pé, ìwọ kò le fààyè gba ènìyàn búburú. Mo mọ̀ pé ìwọ ti se àyẹ̀wò àwon tí wọ́n pe ara wọn ní àpọ́stélì, sùgbọ́n tí wọn kìí se àpọ́stélì, ìwọ ti ri dájú pé èké ni wọn. 3 Èmi mọ̀ pé o ní sùúrù pẹ̀lú ìfaradà, àti pé o ti jìyà púpọ̀ nítorí orúkọ mi, àti pé ìwọ kò tíì rẹ̀wẹ̀sì 4 Sùgbọ́n mò ní àríwí sí ọ, nítorí wípé o ti kọ ìfẹ́ àkọ́kọ́ rẹ sí mi sílẹ̀. 5 Nítorí nà, rántí bí o se fẹ́ràn mi tó tẹ́lẹ̀, ronúpìwàdà, kí o sì padà sí ìfẹ́ ìsáájú tí o ní sí mí. Bí kò se pé o bá ronúpìwàdà, èmi yóò tọ̀ ọ́ wá, èmi yó sì fa ọ̀pá fìtílà rẹ yọ kúrò ní ipò rẹ̀. 6 Sùgbọ́n èyí ni ìwọ ní: o kórira ìṣe àwọn tí ń tẹ̀lé ẹ̀kọ́ Níkólátíání, èyí tí èmi náà kórira pẹ̀lú." 7 kí ẹni tí ó ní etí kí ó gbọ́ ohun tí Ẹ̀mi ń sọ fún àwọn ìjọ. Ẹni tí ó bá sẹ́gun ni Emi yóò fún jẹ ńínú èso igi ìyè tí ó wà láàrin párádísé ti Ọlọrun. 8 Sí ángẹ́lì náà nínú ìjọ ti ìlú Símúnà, kọ ìwé yí: "èyí ni àwọn ọ̀rọ̀ Ẹni tí Ó jẹ́ ìbẹ̀rè àti òpin, Ẹni tí Ó ku, tí O sì tún di ààye padà. 9 Èmi mọ gbogbo ìjìyà àti àíní rẹ, sùgbọn ọlọ́rọ̀ ni ìwọ. Èmi mọ gbogbo ìṣáátá àwọn tí ó pe ara wọn ni Júù, sùgbọn wọn kìí se Júù rárá. Sínágọ́gù sátánì ni wọ́n. 10 Má se bẹ̀rù àwọn ìjìyà ti ó ń bọ̀ lọ́nà. Kíyèsi! Láìpẹ́, éṣù yóò sọ àwọn kan nínú yín sí inú ẹ̀wọ̀n láti lè dán yín wò, ẹyín yí ò wà nínú ìpọ́njú fún ọjọ́ mẹ̀wáà. Se olóòtítọ́ títí dé ojú ikú, èmi yóò fún ọ ni adé ìyè." 11 Ẹni tí ó ba ní etí kí ó gbọ́ ohun tí Ẹ̀mi ń sọ fún àwọn ìjọ. Ẹni tí ó bá sẹ́gun kì yí o jìyà ikú kejì. 12 Sí ángẹ́lì náà ní ìjọ Páágámù ni kọ ìwé yí: Èyí ni àwọn ọ̀rọ̀ ẹni tí O ní idà ẹlẹ́nu méjì: 13 "Èmi mọ ibi tí ìwọ ń gbé, níbití ìtẹ́ ìjọba Sátánì wà. Síbẹ̀ ìwọ di orúkọ mi mú ṣinṣin. Mo mọ̀ pé ìwọ ko sẹ́ ìgbàgbọ́ rẹ nínú mi, kódà ní àwọn ọjọ́ Ántípà ajẹ́ẹ̀ri mi, ènìyàn olóòtọ́, tí wọ́n pa láàrin yín, níbití Sátánì ń gbé. 14 Sùgbọ́n mo bínú sí ọ lórí àwọn ìse rẹ kan: ẹní àwọn kan láàrin yín tí wọ́n di ẹ̀kọ́ Bálámù mú ṣinṣin, ẹni tí ó kọ́ Bálákì láti fi ọ̀nà ẹ̀sẹ̀ han àwọn ọmọ Ísrẹ́lì, kí wọn leè jẹ óúnjẹ ìrúbọ sí òrìsà ati láti se àgbèrè. 15 Bákan náà, àwọn kan láàrin yín tí wọ́n di ẹ̀kọ́ Nikolátíánì mú ṣinṣin. 16 náà, ronúpíwàdà! Bí ìwọ kò bá se bẹ̀, Èmi Ó tọ̀ ọ́ wá ni kíákíá, Èmi yí ó si gbógun tì wọ́n pẹ̀lú idà ẹnu mi. 17 Jẹ́ kí ẹni tí ó bá ní etí, kí ó gbọ́ ohun tí Ẹ̀mí ń sọ fún àwọn ìjọ. Ẹni tí ó bá sẹ́gun ni Èmi yóò fún ni mánà tí a fi pamọ́, Èmi yí ò fún ní òkúta funfun tí a kọ orúkọ tuntun sí orí rẹ̀, orúkọ tí ẹnìkan kò mọ̀ lẹ́yìn ẹni tí o gbàá." 18 Sí ángẹ́lì náà ní ìjọ Tiatírà, kọ ìwé yí: Èyí ni àwọn ọ̀rọ̀ Ọmọ Ọlọ́run, "Ẹni tí ojú Rẹ̀ dà bíi ọ̀wọ́ iná ati ẹsẹ̀ Rẹ̀ bíi bààbà tí a se lọ́sọ̀ọ́: 19 Èmi mọ ohun tí o ti se: ìfẹ rẹ, ìgbàgbọ́ rẹ, isẹ́ rẹ àti sùúrù òhun ìfaradà rẹ. Mo mọ̀ pé àwọn ohun tí o se láìpẹ́ yí ju àwọn ti ìsáájú lọ. 20 Sùgbọ́n mo ní àríwí sí ọ lórí àwọn ìse rẹ kan: Ìwọ fi ààyè gba arábìnrin Jésébẹ́lì náà, tí ò ń pe ara rẹ̀ ni wolíì. Ó fi ẹ̀kọ́ rẹ tan àwọn ìránsẹ́ mi jẹ láti se àgbèrè àti láti jẹ oúnjẹ tí a fi rúbọ sí òrìsà. 21 Mo fi àkókò sílẹ̀ fún un láti ronúpìwàdà, sùgbọ́n ó kọ̀ láti ronúpìwàdà kúrò nínú ìwà èéri rẹ. 22 Kíyèsi! Èmi yí ò sọ ọ́ sí orí àkéte àìsàn, àti àwọn tí ó se àgbèrè pẹ̀lú rẹ̀ ni Èmi yí o fi si inú ìjìyà ń lá, àyààfi tí wọ́n bá ronúpìwàdà kúrò nínú ìse rẹ̀. 23 Èmi yí o lu àwọn ọmọ rẹ̀ pa, gbogbo ìjọ yí o sì mọ̀ pé Èmi máa ń wádìí èrò àti ọkàn gbogbo. Èmi yóò sán fún olúkúlùkù yín gẹ́gẹ́ bíi isẹ́ yín. 24 Sùgbọ́n sì ẹ̀yin tókù ní Tíátírà, sí olúkúlùkù tí kò di ẹ̀kọ́ yí mu, tí wọn kò sì mọ̀ ohun tí àwọn kan ń pé ní ohun ìjìnlẹ̀ Sátánì-- ẹ̀yin ni mo sọ èyí fún, Èmi kò di ẹrù wúwo míràn leyín lórí. 25 Lábẹ́ bí ó ti wù kí ó rí, ẹ dúró ṣinṣin títí n Ó fi dé. 26 Ẹni tí ó bá sẹ́gun, tí ó sì se ohun ti Mo ti se títí dé òpin, ni Èmi yí ò fún ní àsẹ lórí gbogbo orílẹ̀èdè. 27 'Yí ò fi ọ̀pá irin se ìjọba lórí wọn, bíi ìkòkò amọ́ ni òhun yí ó sì fọ́ wọn túútú.' 28 Gẹ́gẹ́ bí mo se gbàá lọ́wọ́ Bàbá mi ni Èmi yóò fún ní ìràwọ̀ òwúrọ̀ náà 29 Jẹ́ kí ẹni tí ó ní etí kí ó gbọ́ ohun tí Ẹ̀mí ń sọ fún àwọn ìjọ.