Orí Kìníí

1 Èyí ni ìfihàn Jésù tí Ọlọ́run fifún Un láti fihàn ìránsẹ́ Rẹ̀ àwọn ohun tí yóò sẹlẹ̀ láìpẹ́. Ó sọ eléyìí di mímọ̀ nípa rírán ángẹ́lì Rẹ̀ sí ìránsẹ̀ Rẹ̀ Jòhánù. 2 Jòhánù jẹ́rìí nípa ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti ẹ̀rí tí a sọ nípa Jésù, àwọn ohungbogbo tí ó rí. 3 Alábùkúnfún ni ẹnití ń kàá sókè, àti tí ń tẹ́tí sí àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀rí na, tí ń se ohun tí a kọ sínú rẹ̀, nítorí àkókò nà kú sì dẹ́dẹ̀. 4 Jòhánù, sí ìjọ méje ní Ásíà: Ore -ọ̀fẹ́ àti àláfíà fún un yín láti ọ̀dọ ẹnití ń bẹ, tí Ó ti wà, ẹnití ń bọ̀ wá, àti láti ọ̀dọ àwọn ẹ̀mí méje tí ó wà níwájú ìtẹ́ Rẹ̀. 5 àti láti ọ̀dọ Jésù Kristi, ẹnití ń se ẹlẹ́rìí òtítọ́, àkọ́bí nínú àwọn òkú, àti aláàkóso àwọn ọba ayé. Sí ẹnití Ó fẹ́ wa, tí Ó túwasílẹ̀ lọ́wọ́ ẹ̀sẹ̀ nípasẹ̀ ẹ̀jẹ Rẹ̀. 6 Ó ti sọ wá di ìjọba, àlúfà fún Ọlọ́run àti baba - Òun ni ògo àti agbára wà fún lái àti láilái. Àmín. 7 Ó ń bọ̀ nínú àwọsánmà; gbogbo ojú ni yóo ri, pẹ̀lú àwọn tí ó gun lọ́kọ̀. Gbogbo ẹ̀yà nínú ayé yóò sọ̀fọ̀ nítorí Rẹ̀. Bẹẹni, Àmin. 8 "Èmi ni ẹnití o bẹ̀rẹ̀ ohun gbogbo àti ẹnití ó parí ohun gbogbo" ni Olúwa Ọlọ́run wí, "Ẹnití ó ti ń bẹ, Ẹnití ó ti wà, Ẹnití ń bọ̀ wá, Alágbára jùlọ. 9 Èmi, Jòhánù arákùnrin yín àti ẹnití ó pín pẹ̀lu yín nínú ìyà àti ìjọba àti sùúrù òun ìfaradà tí ó wà nínú Jésù - wà nínú erékùsù tí a n pe ni Pátímò nítorí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti àwọn ẹ̀rí nípa Jésù. 10 Mo wà nínú ẹ̀mí ní ọjọ́ Olúwa. Mo gbọ́ lẹ́hìn mi ohùn ńlá bi ti fèrè. 11 Ó wípé, "Kọ ohun tí o rí sínú ìwé, kí o sì fi ránsẹ́ sí ìjọ méje - sí Éfésù, sí Smyrna, sí Pergamu, sí Tiatira, sí Sardi, sí Filadéfíà àti sí Laodikia." 12 Mo yípadà láti mọ ohùn ẹnití ń bá mi sọ̀rọ̀, nígbàtí mo yípadà, mo rí ọ̀pá fìtílà méje. 13 Láàrin ọ̀pá fìtílà na, ẹnìkan tí ó dàbí ọmọ ènìyàn, Ó wọ asọ gígùn tí ó débi ẹsẹ̀ Rẹ, pẹ̀lú ẹ̀wù wúrà ní igbá àyà Rẹ̀. 14 Orí àti irun Rẹ̀ funfun bi òwú àti òjò dídì, ojú Rẹ̀ dàbí ẹ̀là iná. 15 Ẹsẹ̀ Rẹ dàbí Bàbàa dídán, gẹ́gẹ́ bi Bàbàa tí a ti tun rọ pẹ̀lú iná, ohùn Rẹ̀ dàbí ìró ọ̀pọ̀ omi sísàn. 16 Ó ní ìràwọ̀ méje ní apá ọ̀tún Rẹ̀, àti idà olójú méjì mímú ti ẹnu Rẹ̀ jáde. Ojú Rẹ̀ ń ràn bi òòrùn tí ó fi agbára ràn. 17 Nígbàtí mo ri, mo wólẹ̀ lẹ́bàá ẹsẹ̀ Rẹ̀ bi òkú ènìyàn. Ó gbé ọwọ́ ọ̀tún Rẹ̀ lé mi wípé, "Má bẹ̀rù. Èmi ni ìbẹ̀rẹ̀ àti òpin, 18 ẹnití ń bẹ láàyè. Mo kú, ṣùgbọ́n wòó, Mo wà láàyè laílaí! Mo ní kọ́kọ́rọ́ ikú àti ipò òkú. 19 Nítorí naa kọ ohun tí o rí sílẹ̀, ohun tí ń sẹlẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́, àti ohun tí yo sẹlẹ̀ lẹ́yìn eléyìí. 20 Nípa ìtumọ̀ ìràwọ̀ méje tí ó farasin tí o rí tí ó wà lọ́wọ́ ọ̀tún mi, àti ọ̀pá fìtílà méje: Àwọn ìràwọ̀ méje naa ni àwọn ángẹ́lì ìjọ méje, àti ọ̀pá fìtílà méje ni àwon ìjọ méjèje."