Orí Kẹẹ̀wá

1 Lẹ́yìn náa mo rí ańgẹ́lì alágbára míràn tó ń sọ̀kalẹ̀ bọ̀wá láti ọ̀run. A fi kùrukùru bòó bí aṣọ, àti pé òṣùmàrè wà lokè oríi rẹ̀. 2 Ó di ìwé kékeré kan mú ní ọwọ́ọ rẹ̀, ó sì gbé ẹ̀sẹ̀ ọ̀tún si orí òkun àti ẹsẹ̀ òsì sóríi ilẹ́. 3 Nígbànáà ó sì ké ní oùn rara bíi kìnìún tí ń bú ramúramù. Nígbà to kígbe tán, àwọn ààrá méje fọùn jáde pẹ̀lú ìróo wọn. 4 Nígbàtí àwọn ààrá méje fọùn jáde, mo múra tán láti kọ̀wé, ṣùgbọ́n mo gbọ́ oùn kan láti ọ̀run ńwípé, "Pa àwọn oun tí ààrá méje sọ mọ́. Máṣe kọ ọ́ sílẹ̀." 5 Nígbànáà ańgẹ́lì tí mo rí tó dúro lóri òkun àti ilẹ̀, na ọwọ́ rẹ̀ ọ̀tún sí ọ̀run. 6 Ó búra nípa ẹni tó wà láàyè láí àti láíláí, ẹnití ó dá ọ̀run àti oun gbogbo tí ó wà nínú rẹ̀, ayé àti oun gbogbo tó wà lóríi rẹ̀, pẹ̀lú òkun àti ohun gbogbo to wà nínúun rẹ̀, ańgẹ́lì náà wípé, "Kò ní sí ìdádúró mọ. 7 Ṣùgbọ́n ọjọ́ tí ańgẹ́lì keje bá fẹ́ fọn fèrèe rẹ̀, nígbànáà ni ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run yóò di múmúṣẹ, gẹ́gẹ́ bí ó ṣe kéde sí àwọn wòlíì ìránṣẹ́ rẹ̀. 8 Oùn tí mo gbọ́ láti ọ̀run bá mi sọ̀rọ̀ lẹ́ẹ̀kan si: "Lọ, gba ìwé tó ṣí tó wà ní ọwọ́ ańgẹ́li ti ó dúro lórí òkun àti lórí ilẹ̀." 9 Nígbànáà ni mo lọ si ọ̀dọ ańgẹ́lì náà mo sọ fúu pé kó fún mi ní ìwé kékeré náà. Ó sọ fún mi, "Mú ìwé náà ko si jẹẹ́. Yí ò mú inú rẹ korò, ṣùgbọ́n ní ẹnuùn rẹ yíó sì dùn bíi oyin." 10 Mo gba ìwé kékeré náà láti ọ́wọ́ ańgẹli náà mo sì jẹé. Ó sí dùn bíi oyin ní ẹnuùn mi, ṣùgbọ́n lẹ́yìn tí mo jẹẹ́, inú mí wá di kíkorò. 11 Lẹ́yìn-náà ẹnìkán sọ fún mi, "O gbọdọ̀ sọtẹ́lẹ̀ lẹ́ẹ̀kan síi nipa ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn, àwọn orílẹ̀ède, awọn èdè ati àwọn ọba."