Orí Kọkànlá

1 A sì fi ọ̀pá ìyẹ́ kan fún mi láti lò tí ó dà bi ọ̀pá ìwọ̀n. A sọ fún mi pé, "Dìde kí o wọn tẹ́mpílì Ọlọ́run àti pẹpẹ àti àwọn tí nsìn nínú rẹ̀. 2 Ṣùgbọ́n kí o ma se wọn àgbàlá tẹ́mpílì náà, nítorí a ti fi fún àwọn kèfèrí. wọn ó tẹ ilẹ̀ mímọ́ fún osù méjìlélógójì. 3 Èmi ó fi àṣẹ fún àwọn ẹlẹ́ẹ́rí mi méjì láti sọtẹ́lẹ̀ fún ẹgbẹ̀fà lé ọgọ́ta ọjọ́, tí a fi aṣọ ọ̀fọ̀ wọ̀." 4 Àwọn ẹlẹ́ẹ̀rí yí ni igi ólífì méjì àti ọ̀pá fìtílà méjì náà tí ndúró níwájú Olúwa ayé. 5 Bí ẹnikẹ́ni bá yàn láti pawọ́n lára, iná á ti ẹnu wọn jáde yóò sì pa àwọn ọ̀tá wọn run. Ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ pa wọ́n lára ni a gbọdọ̀ pa lọ́nà yí. 6 Àwọn ẹlẹ́ẹ̀rí yí ní agbára láti ṣé ọ̀run tí òjò kò fi ní rọ̀ ní àkókò tí wọn bá sọtẹ́lẹ̀. Wọn tún ní agbára láti sọ omi di ẹ̀jẹ̀ àti láti fi onírurú àjàkálẹ̀ àrùn kọlu ayé ní àkókò tí wọn bá fẹ́. 7 Nígbà tí wọn bá sì fi parí ẹ̀rí wọn, ẹranko tí n ti inú ọ̀gbun gòkè wá yóò gbógun tì wọ́n, yó sì borí wọn yó sì pa wọ́n. 8 Òkú wọn yó sì wà nílẹ̀ ní ìgboro ìlú nlá náà (tí àpẹrẹ pípè rẹ̀ jẹ́ Sódómù àti Égíbítì) níbití a gbé kan Olúwa wọn mọ́ àgbélébú. 9 Fún ọjọ́ mẹ́ta àti àbọ̀ ni àwọn kan láti inú ènìyàn, ẹ̀yà, èdè, orílẹ̀ àti èdè yóo wo àwọn òkú wọn. A kò ní gbà wọ́n láyè kí á gbé òkú wọn sínù bojì. 10 Àwọn tí ó ń gbé ayé yóò yọ̀ wọn ó sì ṣe àjọyọ̀ lóri wọn. Wọn yóò fi ẹ̀bùn fún ara wọn nítorí àwọn wòlíì méjèjì yí dá àwọn olùgbé ayé lóró. 11 Ṣùgbọ́n lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́ta ìmí ìyè láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run yóò wọ inú wọn, wọn yóò sì dìde lórí ẹsẹ̀ wọn. Ẹ̀rù ńlá yóò dé bá àwọn tí ó rí wọn. 12 Nígbà náà ni wọn yóò gbọ́ ohùn ńlá kan láti ọ̀run sì wọn wípé, "Ẹ gòkè wá síbí!" Nígbà náà ni wọn sì gòkè lọ sí ọ̀run, àwọn ọ̀tá wọn sì rí wọn. 13 Ní wákàtí náà ìṣẹ̀lẹ̀ ńlà kan ṣẹ̀, ìdámẹ́wàá ìlú náà sì wó. Ẹdẹ̀ẹ́gbàrin ènìyàn ni a pa nínú ìṣẹ̀lẹ̀ náà, ẹ̀rù yóò mú àwọn tíó yèé wọn yóò fi ògo fún Ọlọ́run ọ̀run. 14 Ègbé kejì ti lọ. Wòó! Ègbé kẹta sì ń bọ̀ wá kánkán. 15 Nígbà náà ni ańgẹ́lì keje fun fèrè rẹ̀, oùn ńlá kan sì fọ̀ láti ọ̀run tí ó wípé, "Ìjọba ayé náà ti di ti Olúwa wa àti ti Krísítì Rẹ̀. Òun yóò jọba láí àti láíláí." 16 Nígbà náà ni àwọn àgbààgbà mẹ́rìnlélógún tí wọn jókòó lórí ìtẹ́ wọn níwájú Ọlọ́run dojúbolẹ̀. Wọn sin Ọlọ́run. 17 Wọn wípé "A fi ògo fún Ọ, Olúwa Ọlọ́run Alágbárà jùlọ, ẹni tí ó wà, tí ó ti wà, nítorí ìwọ ti gba agbáre ńlá rẹ, ìwọ tí ń jọba. (ẹ̀dà míràn kà pè "Ẹni tí ó jọba lórí ohun gbogbo, tí ó wà, tí ó ti wà, tí ó sì ń bọ̀ wá. Ṣùgbọ́n àwọn ẹ̀dà òde òní kò kọọ́ bẹ́ẹ̀). 18 Àwọn orílèdè sì bínú, ṣùgbọ́n ìbínú Rẹ tì dé. Àkókò náà dé láti dá àwọn òkú lẹ́jọ̀ àti láti fi èrè fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ wòólì, àwọn onígbàgbọ́, àti àwọn tí ó bẹ̀rù orúkọ Rẹ, àti ẹni tí kò se pàtàkì ati alágbára. Àkókò náà ti dé fún Ọ láti pa àwọn tí ó ń pa ayé náà run rẹ́." 19 Nígbà náà ni tẹ́mpílì Ọlọ́run ní ọ̀run ṣí sílẹ̀, a sì rí àpótí májẹ̀mú nínú tẹ́mpìlì Rẹ̀. Mànàmáná sì kọ, a sì gbọ́ ohùn, àrá sì sán, ìṣẹ̀lẹ́ sì ṣẹ̀, yìyín ńlá sì bọ́.