1 Àmì n la kan si yọ lójú ọ̀run: obìnrin tí a wọ̀ ní asọ oòrùn, pẹ̀lú òsùpá ní àtẹ́lẹsẹ̀ rẹ̀ pẹ̀lú adé ìràwọ̀ méjìlá lórí rẹ. 2 Ó lóyún, ó sì n ké rora ìbí, àní ìrora àti bí. 3 Àmì kán sìtún yọ lójú ọ̀run: sìwó! drágónì ńlá pupa kan tí ó ní orí méje àti ìwo mẹ́wǎ pẹ̀lú adé méje lórí rẹ̀. 4 ìru rẹ̀ gbá ìdá mẹta ìràwọ̀ ní ọ̀run ó sì wọ́ wọn wá sí aíyé. Drágónì náà dúró níwájú obìnrin tí ó ún rọbí, kí ó le è pa ọmọ obìnrin náà run bí ó bá ti bí i tán. 5 Ó bí ọmọkùnrin kan, tí yio darí àwon orílẹ̀ èdè pẹ̀lú ọ̀pá irin. A gba ọmọ náà lọ sí ọ̀dọ̀ Ọlọ́run àti sí orí ìtẹ́ e rẹ̀, 6 Obìnrin náà si sá lọ si inú aginjù tí ati pèsè sílẹ̀ fún lati ọwọ ọlọrun wa, fun itọju títí di ẹgbẹfa ọjọ́ o le ọgọta. 7 Nísinsìnyí, ogun kan sì wà ni ọ̀run. Mikẹli àti àwọn ángẹ́lì rẹ̀ kọjú ìjà sí drágónì náà, drágónì àti àwọn ángẹ́lì rẹ̀ pẹ̀lú sì kọjú ìjà padà. 8 Sùgbọ́n drágónì náà kò lágbára láti bori, tóbẹ̀ tí kò sí àyè fún òun àti àwọn ángẹ̀lì rẹ̀ ní ọ̀run mọ́. 9 Drágónì ńlá nì - ejò lailai ni, tí à ń pè ní èsù tàbí sátánì, ẹni tí ó tan aiyé jẹ, a lé e sọ̀kalẹ̀ sínú ayé pẹ̀lú àwọn ángẹ́lì rẹ̀. 10 Nígbànáà ni mo gbọ́ ohùn ńlá kan ní ọ̀run: ''Nísinsìnyí ni ìgbàlà , agbára, ìjọba Ọlọ́run wa, ati asẹ ti kristi wá. Nítorí a lé olùfisùn àwọn ará wa sọ̀kalẹ̀, ẹnì kan náà tí ó ń fi wọ́n sùn níwájú Ọlọ́run wa ní ọ̀sán àti ní òru. 11 Wón sẹ́gun rẹ̀ nípa ẹ̀jẹ̀ ọ̀dọ́ àgùtàn ati nípa ọ̀rọ̀ ẹ̀rí ẹnun won, nitori won ko fẹran ẹ̀mí won títí dé ojú ikú. 12 Nitori naa, ẹyọ̀, ẹ̀yin ọ̀run ati awon tion gbe inu rẹ̀! Sugbon egbe ni fun ayé àti òkun, nitori esu sọkalẹ tọ ọ wa! Ókún fún ìbínún jọjọ nitori àkókò rẹ kòpọ̀! 13 Nígbàtí drágónì náà mọ̀ wípé a lé òun sọ̀kalẹ̀ sínú aíyé, oún lépa obìnrin tí ó bí ọmọkùnrin náà. 14 Sùgbọ́n a fún obìnrin náà ní ìyẹ́ méjì bí i ti ẹyẹ ìdì láti fò lọ sí ibi tí ati pèsè sílẹ̀ fún n ní aginjù. Ní ibi tí yio ti gba ìtọ́jú fún wòn ìgbà ati àkókò kuro lọwọ ejò naa. 15 Ejò náà tu omi jáde ní ẹnu rẹ̀ bí odò tó ń sàn kí ó leebà gbe obinrin naa lọ. 16 Sugbon ilẹ̀ ran obinrin naa lọ́wọ́. Óla ẹnun rẹ̀, ósì fa gbogbo omi tí ejò naa ntu jade lati ẹnun rẹ̀ mu. 17 Ibinun dragoni naa ru si obinrin naa tobẹ ti ofi kúkú koju ija si irufẹ omobinrin naa, awon tí oń pa òfin ỌLọrun mo tí ósì rọ̀mó ẹri nipa Jesu. 18 Dragoni naa si duro sinsin lori iyanriǹ létí òkun.