1 Nígbànáà ni mo sìrí ẹranko búburú kan tí o ń jáde láti inú òkun. Ó ní ìwo mẹ́wǎ àti orí méje. Lórí àwọn ìwo rẹ̀ ni adé mẹ́wǎ wà, lórí orí kọ̀ọ̀kan ni orúkọ tón sòrò òdì wà. 2 Eranko búburú tí mo rí náà dàbí Àmòtẹ́kùn. Ẹsẹ̀ rẹ̀ dàbi ti ẹranko bẹ́árì, àti ẹnu rẹ̀ dàbí ẹnu kìnìnú. Drágónì náà fún ní agbára rẹ̀, àti ìtẹ rẹ̀ àti àsẹ ńlá rẹ̀ làti jọba. 3 Ọ̀kan nínú àwọn orí ẹranko búburú nàá dàbi ẹni pé a ti pá, ṣùgbón ojú ọgbẹ́ rẹ̀ náà san. Ẹnú ya gbogbo aiyé bí wón se ń tẹ̀lé ẹranko búburú náà. 4 Wón tún foríbalẹ̀ fún drágónì náà, nítorítí ó ti fi àsẹ rẹ̀ fún ẹranko búburú náà. Wọ́n foríbalẹ̀ fún ẹranko búburú yìí, wón sì ń sọ wípé, "Tani ó dàbí eranko búburú yi? Tani ó lè dojú ìjà kọọ́?" 5 Ẹranko náà ni a fún ní ẹnu kan láti le sọ àwọn ọ̀rọ̀ ìgbéraga àti àwọn ọ̀rọ̀ òdì. A fún un láyè láti pàṣẹ fún oṣu méjì le logójì. 6 Nítorínà ẹranko náà la ẹnu rẹ̀ láti sọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ òdì sí Ọlọ́run: ọ̀rọ̀ ọ́dì sí orukọ Rẹ̀, sí ibùgbé Rẹ̀ náà, àti sí àwọn tí ń gbé ní ọ̀run. 7 Ẹranko náà ni a fún ní ààyè láti bá àwọn onígbàgbọ́ jagun àti láti ṣẹ́gun wọn. A sì fún ni àṣẹ lórí ẹ̀yà gbogbo, ènìyàn, èdè àti orílẹ̀-èdè. 8 Gbogbo olùgbé ayé ni yóò foríbalẹ̀ fun, gbogbo àwọn tí a o kọ orúkọ wọn, làti ìbẹ̀rẹ̀ ìṣẹ̀dá ayé, sínú Ìwé Ìyè náà, èyí tí ó jẹ́ ti Ọ̀dọ́ Àgùntàn, tí a ti pa. 9 Bí ẹnikẹ́ni ba létí, jé kí ó gbọ́. 10 Bí a bá ní láti mú ẹnikẹ́ni lọ sínú ìgbèkùn, sínú ìgbèkùn ni yóò lọ. Bí a bá ní láti pa ẹnikẹ́ni pẹ̀lú idà, pẹ̀lú idà ni a ó paá. Èyí ni ìpè láti ní sùúrù nínú ìpamọ́ra àti ìgbàgbọ́ fún àwọn ẹni mímọ́. 11 Nígbanáà ni mo rí ẹranko mírán tí ó ń jáde bọ̀ láti inú ayé wa, ó ní ìwo méjì bí i ti ọ̀dọ́ àgùntàn, àti pe o n sọ̀rọ̀ bí i drágónì. 12 Ó sì ń lo gbogbo àṣẹ eranko ìkínní ni íwájú rẹ̀, ó sì mú kí ayé àti àwọn tí ó ń gbé nínú rẹ foríbalẹ̀ fun ẹranko ìkínní - èyí tí a wo ọgbẹ́ jínjìn rẹ̀ sàn. 13 Ò ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu tó lágbára. Ó tilẹ̀ mú kí iná sọ̀kalẹ̀ sórí ayé láti ọ̀run wá ní iwájú àwọn ènìyàn. 14 Pẹ̀lú àwọn àmìn tí a gbà á láyè láti ṣe, ó tan àwọn ti o ńgbé nínú ayé jẹ. Ó sọ fún wọn kí wọn gbẹ́ ère ní ìbu olá fún ẹranko tí ó ní ọgbẹ́ idà tí ó sì yè. 15 A gbà á láyè láti fi èémí fun àwòrán ẹranko náà tí àwòrán náà yóò fi sọ̀rọ̀ ti yóò si mú kí gbobo àwọn tí kọ̀ bá foríbalẹ̀ fun ẹranko náà di pípa. 16 O si n fi ipa mu gbogbo ènìyàn, ẹni ti ko se pàtàki àti alágbárá, olówó àti tálákà, òmìnira ati ẹrú láti gba àmì ní ọwọ́ ọ̀tún tàbí iwájú orí wọn. 17 Kò ṣeéṣe fún ẹnikẹ́ní láti rà tàbí láti tà bí kòṣepé ó ní àmì ẹranko náà, tí ó jẹ́ pé, àmi tí ó dúró fún orúkọ rẹ̀. 18 Èyí pè fún ọgbọ́n. Tí ẹnikẹ́ni bá ní òye inú, jẹ́ kí ó ṣe ìṣirò àmì ẹranko náà. Nítorí pé àmì ènìyàn kan ní í ṣe. Àmì náà sì jẹ́ ọ̀tàlélẹ́gbẹ̀ta ó lé mẹ́fà.