1 Mo wò, mo sì rí ọ̀dọ́ àgùtàn tí ó dúró ní orí òkè Sioni. Pẹ̀lú rẹ̀ ni àwọn, òkẹ́ méje ó lé ẹgbaaji tí ó ní orúkọ rẹ̀ àti orúkọ Bàbá rẹ̀ ní iwájú orí won. 2 Mo gbọ́ ohùn kan làti ọ̀run wá bí i ti rúrú àwọn òmi àti ìró àrá ńlá. Ohùn tí mo gbọ́ si dàbí ti àwọn olórin háàpù tí oń fun harpu won. 3 Wón kọ orin titun níwájú itẹ ati níwájú ẹ̀dá alàyè mẹrin ati awon àgbàgbà. kòsí ẹni tó le kọ́ orin náà àfi àwọn òkẹ́ méje o lé ẹgbaaji tí ati ràpadà kúrò nínú ayé. 4 Wòn yí ni àwọn tí kò fi obìnrin ba ara wọn jẹ́, tí ó ti pa ara wọn mọ́ kúrò ninu ìbálòpò. Wọ̀nyí ni ó sì ń tẹ̀lé ọ̀dọ́ àgùtàn náà lọ sí ibi gbogbo tíó lọ. Wònyi ni ẹni ìràpadà láti ìran ọmọ ènìyàn wá gẹ́gẹ́ bí èso àkọ́so fún Ọlọọ́un àti ti ọ̀dọ àgùtàn. 5 Kò sí àìsòtítọ́ lẹ́nu wọn; wón jẹ́ aláìlábàwọ́n. 6 Mo sì tún rí ángẹ́lì míràn tí ó ń fò lójú òfúrufú, tí ó ní ìròyìn ayọ̀ ti ayérayé lọ́wó láti kéde fún àwọn tí ó ń gbé inú ayé - sí gbogbo orílẹ̀ èdè, ẹ̀yà, èdè àti ènìyàn. 7 Ó ké lóhùn rara, ''Bẹ̀rù Ọlọrun kí ẹ sì fi ògo fún un. Nítorí wákàtí ìdájọ́ rẹ̀ tidé. Ẹ júbà fun, ẹni tí ó dá ọ̀run, ayé, òkun àti àwon ìsun omi.'' 8 Ángẹ́li miran - ẹlẹkeji tẹ̀le, oún wípé, ''Isubú, ìsubú nifun babiloni naa, ilu nla ni ti subu, ilu tio fun gbogbo awon oride ni otí àgbère rẹ̀ mo. 9 Angẹli miran - ẹlẹkẹta tẹ̀le won, oún wí ní ohùn goro pé, ''Bi ẹnikeni ba fi ori balẹ̀ fún ẹranko ni ati àwòranrẹ̀ tí ò si gba àmìn rẹ̀ si iwaju ori rẹ tabi ni ọwọ rẹ, 10 Òun pẹ̀lú yio mo ninu waini ìbínú Ọlọrun, waini ti adà sinu ago ìbínú rẹ lai ni àdàlù. Enikan naa tio bamu ninu rẹ ni ao pan loju pẹ̀lú iná ati tunfulu niwaju awon angẹli Ọlọrun ati ọ̀dọ́ àgùtàn. 11 Eefin ìjìyà won yío gòkè lọ lai ati lailai, ki yio si si ibi ìsinmin ni ọsan tabi ni òru fun awon ẹniti o tẹriba fun ẹranko naa ati àwòran rẹ̀ ati fun gbogbo awon tio si gba àmìn orukọ rẹ. 12 Eyi ni ipe fun sùúrù ati ìforítì fun awon eniyan mímó Ọlọrun, ti on pa ofin Ọlọrun mo ati igbagbọ won ninu Jesu.'' 13 Mo gbo ohun kan lati ọ̀run wá pé, ''Kọ eyii: Alabukun fun ni awon tio ku ninu oluwa.'' ''Beeni'' ẹ̀mí wí, ki won ba le sinmin kúrò ninu laala won nitori isẹ́ won yio ma tọ̀wón lẹ́yìn.'' 14 Mo si wo, sikiyesi kùrukùru wa. Ẹni tio dabi ọmọ eniyan si joko lori kùrukùru naa. Oni ade wura lori ati ìpaakà mímú ní ọwọ́ ọ rẹ̀. 15 Angẹli miran si jade wa lati inún tẹmpili, óké ní ohùn rara si ẹnikan naa tio joko lori kùrukùru: ''Mú ìpaakà rẹ kio si bẹrẹ si ni kórè. Nitori asiko ikore tide, ìkórè ayé sìti pón.'' 16 Enìkan naa tio joko lori kùrukùru sìsọ ìpaakà rẹ̀ si aye, asi kórè ayé. 17 Angẹli miran situn jade lati inun tẹmpili ọrun wa, òun pẹlu ni ipaaka mímú lọ́wọ́. 18 Bakan naa angẹli miran ti pẹpẹ turari wa, ẹni tio ni àsẹ lórí iná. Óké ní ohùn rara si ẹni tí ó ní ìpaakà mímú lọ́wọ́, '' Mu ìpaaka mímú rẹ kio sì ko eso ajara ilẹ ayé jọ nitoripe wón tipón.'' 19 Angẹli naa si sọ ìpaakà rẹ̀ sínú aye, osi ko awon eso ajara ilẹ̀ ayé jọ, oda won sinun ìfúntí ìbínún nla Ọlọrun. 20 Lẹyin odi ilu ni ìfúntí naa gbewa, níbẹ̀ ni a sì gbé tẹ àwon èso naa, ẹ̀jẹ̀ si tibẹ̀ yọ jade lati inu ifunti naa. Jínjìn rẹ mu ẹsin dé ijanun ọrùn, ósì gba ilẹ̀ lọ ní nnkan bi ẹgbẹ̀jọ ibùsọ̀.