1 Mo si ri àmìn míràn ni ọ̀run, ótó bi osi yani lẹnu: Awon angẹli meje kán wà pẹlú ìyọnun meje, tí ójẹ́ ìyonun ìkẹyìn, nitori ninu won ni ibinu Ọlọrun yio dopin. 2 Mo ri oun to farahan bi òkun dígí to dàpọ̀ mó iná. awon tio wa lẹba òkun naa ni awon tio ti sẹgun ẹranko naa ati aworan rẹ ati lori iye ònkà to duro fun orukọ rẹ. Won si mu ohun elo orin harpu ti afun won lati ọwọ Ọlọrun lọwọ. 3 Won kọ orin Mose, iransẹ Ọlọrun, ati orin ti ọdo agutan naa: ''Titobi ati ìyàlẹ́nu ni ise rẹ Oluwa Ọlọrun, alagbara julọ. Otitọ ati ododo ni ọna rẹ, ọba gbogbo ayé. 4 Tani ko ni bẹru rẹ Oluwa ati lati fi ògo fun orukọ? Nitori iwọ nikan ni ó jẹ́ mímó. Gbogbo aye yio pejọ jùmò fori balẹ niwaju rẹ nitori isẹ otito rẹ di mí mò.'' 5 Lẹyin nkan won yi mo wò, si kiyesi asi tempili agọ ẹ̀rí kan silẹ ni orun. 6 Lati ibi mímó jùlo ni awon angẹli meje ti wá ti on ti ìyọnu meje lọwọ. Awọ won ni asọ ọ̀gbọ̀ funfun tin dan, asi fi àmùrè wura di won ni ookan àyà. 7 Ọ̀kan ninu awon ẹ̀dá alàyè mẹrin ni fun igo wura meje fun awon angẹli meje naa, ti o kún fun ibinu Ọlọrun, ẹniti mbẹ laaye lai ati lailai. 8 Tẹmpili naa sì kún fún eefin lati inú ògo Ọlọrun ati agbara rẹ̀. Ẹnikẹni kole wọ inu rẹ titi ìyọnu meje awon angẹli meje naa fi parí.