Orí Kẹrìndínlógún

1 Mo sì gbọ́ ohùn ńla kan pè láti inú Témpílì wá ó ń wí fún àwọn ańgẹ́lì méje náà pé, "Ẹ lọ kí ẹ sì tú àwo-kòtò ìbínú méje Ọlọ́run dà sórí ayé." 2 Ańgẹ́lì kínní sì jáde lọ ó sì tú àwo-kòto tirẹ̀ sí ayé; egbò àdáàjiná tí ó kún fún ìrora si wá sí ara àwọn ènìyàn tí ó ní ààmì ẹranko náà, àwọn tí ó ń sin àwòrán rẹ̀. 3 Ańgẹ́lì kejì naa sì tú àwo-kòtò tirẹ̀ sí inú òkun. Ó sì di ẹ̀jẹ̀, bí ẹ̀jẹ̀ ókú, gbogbo àwọn ohun abẹ̀mí tí ó wà nínú òkun sì kú. 4 Ańgélì kẹta si tu àwo-kòtò tirẹ sí inú àwọn odò àti àwọn orísun omi, wọ́n sì di ẹ̀jẹ̀. 5 Mo sì gbọ́ ańgẹ́lì àwọn omi tí o wípé, "Olódodo ni Ìwọ, ẹniti ó ńbẹ, tí ó ti wà, Ẹni Mímọ́ - nítorí ìwọ ti ṣe ìdájọ́ àwọn ohun wọ̀nyí. 6 Nítorípé wọ́n ti ta ẹ̀jẹ́ àwọn onígbàgbọ́ àti àwọn wòlíì sílẹ̀, Ìwọ sì ti fi ẹ̀jẹ̀ fún wọn mu; èyí yì ni ó yẹ wọ́n." 7 Mo sì gbọ́ pẹpẹ ń dáhùn wípé, "Bẹ́ẹ̀ ni, Olúwa Ọlọ́run Alágbára, òtítọ àti òdodo ni àwọn ìdájọ́ Rẹ." 8 Ańgélì kẹrin si tu àwo-kòtò tirẹ̀ sori òòrùn, a sì fún un ní iyọ̀ǹda láti fi iná jó àwọn ènìyàn lára. 9 Ooru gbígbóná gidigidi náà sì jó wọn, wọ́n sì sọ ọ̀rọ̀ òdì sí orúkọ Ọlọ́run, tí ó ní agbára lórí àwọn àjàkálẹ̀ àrùn wọ̀nyí. Wọ́n kò sì yí padá tàbí fi ògo fún un. 10 Nigbana ni ańgẹ́lì karùnún si tu àwo-kòtò tirẹ̀ sori ìtẹ́ ẹranko búburú náà, okùnkùn sì bo ìjọba rẹ̀. Wọ́n sì gé ahọ́n wọn jẹ nítorí ìrora náà 11 Wọ́n sì sọ̀rọ̀ òdì sí Ọlọ́run nítorí ìrora wọn àti nítorí egbò wọn, wọn sì kọ̀ síbẹ̀ wọn kò sì yí padà kúrò ninu àwọn ìṣe wọn. 12 Ańgélì kẹfà si tu àwo-kòtò tirẹ sí inú odò ńlá náà, Eúfrátè, omi rẹ̀ sì gbẹ nítorí làti pèsè ọ̀nà sílẹ̀ fún àwọn ọba ti wọn yóó wá láti ìlà-oòrùn. 13 Mo sì rí àwọn ẹ̀mí àìmọ́ mẹ́ta tí wọn dàbí ọ̀pọ̀lọ́, ti wọń ń ti ẹnu awọn dírágónì náà, àti ẹnu ẹranko búburú náà, àti ẹnu wòlíì èké náà jáde 14 Nítorì wọ́n jẹ ẹmi àìmọ́ , ti ń ṣe àwọn iṣẹ ìyanu. Wọ́n ń jáde lọ sọ́dọ̀ àwọn ọba ayé láti kó wọn jọ fún ogun tí ọjọ́ ńlá Ọlọ́run Alágbára. 15 ("Kíyèsíi! Èmi ńbọ̀ bí olè! Alábùkúnfún ni ẹni tí ń ṣọ́nà, tí ó sì ń pa aṣọ rẹ̀ mọ́ kí ó má baà jáde ní ìhòhò, wọn a sì rí ipò ìhòhò tí ó wà.") 16 Wọ́n sì kó wọn jọ pọ̀ sí ibìkan tí à ń pè ní Àmágẹ́dọ̀n ní èdè Hébérù. 17 Nígbànáà ni Ańgélì keje sì tú àwo-kòtò tirẹ sí inú afẹ́fẹ́. Nígbànáà ni ohùn ńlá kan sì ti inú Témpílì àti inú ìtẹ́ jáde wá wípé, " Ó parí!" 18 Àwọn mànàmáná sì kọ, ìrọ́kẹ̀kẹ̀, àrá sísán, àti ilẹ mímì gidigidi, ìmìlẹ̀ tí ó lágbára tí kò sì tíì sí irú rẹ rí láti ìgbà tí ìran ènìyàn ti wà lórí ilẹ ayé. 19 Ìlú ńlá náà sì pín sí mẹ́ta, àwọn orílẹ̀èdè sì subú. Nígbànáà ni Ọlọ́run sì ránti Bábílónì ìlú ńlá nní, Ó sì fi ife ọtí líle tí ó kún fún ìbínú Rẹ̀ fún un. 20 Gbogbo erékùsù si pòórá, a kò sì rí àwọn òkè ńlá mọ́. 21 Yìnyín ńla, tí ọ̀kọ̀ọ̀kan rẹ̀ tó òdiwọ̀n tálẹ́ńtì kan, sì rọ̀ sí ori àwọn ènìyàn láti ọ̀run wa. Àwọn ènìyàn sì sọ̀rọ̀ òdì sí Ọlọ́run nítorí ìyọnu yìnyín náà, àti nítorí ìyọnu náà pọ̀ gidigidi.