Orí Kọkànlélógún

1 Nígbànáà ni mo rí ọ̀run titun kan àti ayé titun nkan, nítorí ọ̀run ti àkọ́kọ́ àti ayé ti àkọ́kọ́ ti kọjá lọ, òkun kò sì sí mọ́. 2 Mo rí ìlú mímọ́, Jerúsálèmù titun, tí ó ti ọrun sọ̀kalẹ̀ wá láti ọ̀dọ̀ Ọlórun, tí a múra sílẹ̀ bí ìyàwó tí ase lọ́sọ̀ọ́ de ọkọ rẹ̀. 3 Mo gbọ́ ohùn ariwo ńlá láti orí ìtẹ́ wá ń wípé, "Wo! Ibùgbé Ọlọ́run wà pẹ̀lú àwọn ọkàn alààye, àti wípé Òun yóò máa bá wọn gbé pẹ̀lú. Wọn yóò jẹ́ ènìyàn rẹ̀, Ọlọ́run fúnrarẹ̀ yóò wà pẹ̀lú wọn, àti pé Òun yóò jẹ́ Ọlọ́run wọn. 4 Òun yóò nu gbogbo omijé kúrò ní ojú wọn, kí yò sì sí ikú mọ́, tàbí ìbànújẹ́, tabi ẹkún tàbí ìrora. Ohun àtijọ́ ti kọjá lọ. 5 Ẹni tí ó jókó lórí ìtẹ́ náà wípé, Wóò! Mo sọ ohun gbogbo di titun." Ó wípé, "Kọ èyi sílẹ̀ nítorí àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí se é gbẹ́kẹ̀lé àtí òtítọ́ sì ni." 6 Ó sọ fún mi pé, "A ti se àwọn nǹkan wọ̀nyí! Èmi ni Álfà àti Ómígà, ìbẹ̀rẹ̀ náà àti òpin náà. Fún ẹni tí òrungbẹ́ ń gbẹ, Èmi yóò fún un ní omi tí kì yóò san owó fún láti inú kànga omi ìyè. 7 Ẹnití ó bá sẹ́gun ni yóò jogún àwọn ǹkan wọ̀nyi, Èmi yóò sí jẹ́ Ọlọ́run rẹ̀, àti òun pẹ̀lú yóò jẹ́ ọmọ mi. 8 Ṣùgbọ́n àwọn ojo, aláìgbàgbọ́, oní ìríra, àwọn apànìyàn, àwọn tó dẹ́sẹ̀ àgbèrè, àwọn osó, àwọn abọ̀rìsà, àti àwọn òpùrọ̀ gbogbo, wọn yóò ní ipa tiwọn ninú adágún iná ìléru tí jó. Èyí ni ikú kejì. 9 Ọ̀kan nínú àwọn ángẹ́lì méje náà wá sọ́dọ̀ mi, ẹnití ó ní àwo kòtò méje tí ó kún fún àwọn ìyọnu ìgbẹ̀yìn méje, ó sì wípé, "Wá níbí yíí. Èmi yóò fi ìyàwó náà hàn ọ, ìyàwó ọ̀dọ́ àgùntàn. 10 Lẹ́yin náà ni ó gbé mi lọ nínú Ẹ̀mí sori òkè ńlá àti tí ó ga ó sì fi ìlú mímọ́ Jerúsálẹ̀mù tí ó ń ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ wá láti ọ̀dọ̀ Ọlórun. 11 Jerúsálẹ̀mù ti ni ògo Ọlọ́run, ẹwà rẹ̀ dàbí wúrà dídán iyebíye, bí òkùta krístálì ti jápérì tí ó mọ́ gaara. 12 Ó ní odi ńlá, gíga pẹ̀lú ẹnù ọ̀nà méjìlá, pẹ̀lú àwọn ángẹ́lì méjìlá ní ẹnu ọ̀nà wọn. Ní ori ilẹ̀kún náà ni akọ orúkọ àwọn ẹ̀yà ọmọ Ísrẹ́lì méjìlá sí. 13 Ní ìlà oòrùn ni ẹnu ọ̀nà mẹ́ta wà, ní àríwá ọnu ọ̀nà mẹ́ta, ní gúsù ẹnu ọ̀nà mẹ́ta àti ni ìwọ̀ oòrùn ẹnu ọ̀nà mẹ́ta. 14 Odi ìlú náà ní ìpìlẹ́ méjìlá, àti ní ara odi náà ní a kọ orúkọ àwọn Àpọ́stélì méjìlá ti ọ̀dọ́ àgùntàn sí. 15 Ẹni tí o bá mi sọ̀rọ̀ ní ọ̀pá òdiwọ̀n tí afi wúrà se láti se òdiwọ̀n ìlú náà, àwọn ẹnu ọ̀nà rẹ̀, àti odi rẹ̀. 16 Ìpìnlẹ̀ ìlú náà ni afi lélẹ̀ ní igun mẹ́rin dọ́gba dọ́gba; gígùn rẹ̀ dọ́gba pẹ̀lú fífẹ̀ rẹ̀. Ó fi ọ̀pá ìwọ̀n wọn ìlú náà, ẹgbẹ̀rún méjìlá gbàgede eré ìdárayá ní gíga (gígùn rẹ̀, àti fífẹ̀ rẹ̀, àti gíga jẹ́ ọgba ọgba). 17 Ó se òdiwọ̀n odi rẹ̀ pẹ̀lú, ìwọ̀n odi náà jẹ́ mẹ́rìnlélógóje ní ìwọ̀n ti ènìyàn (èyítí í se ìwọ̀n ti ángẹ́lì pẹ̀lú). 18 Pẹ̀lú òkúta jásípérì ni a fi kọ́ odi àti ìlú náà ni afi ògidì wúrà, bíi dígí tí ó mọ́ gaara. 19 Ìpìnlẹ̀ odi náà ni a se lọ́sọ̀ọ́ pẹ̀lú orìsìírísìí òkuta iyebíye. Àkọ́kọ́ ni jásípérì, èkejì ni íse sàfáyà, ẹ̀kẹta ni ẹnu ọ̀nà, ẹ̀kẹrin ni ẹ́mírádì, 20 ẹ̀kaàrún ni ọ́nìkísì, ẹ̀kẹfà ni kànẹ́líánì, ìkeje ni krísóláìtì, ẹ̀kẹjọ ni bẹ̀ríìlì, ẹ̀kẹẹ̀sán ni tópásì, àti ẹ̀kẹẹ̀wá ni ámítísit' 21 Ẹnu ọ̀nà méjìlá náà ni iyùn méjìlá; ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ni a fi iyùn se. Àwọn òpópónà ìlú naajẹ́ ògidì wúrà, dígí tí ó mọ́ gaara. 22 Èmi kò rí tẹ́ḿpìlì niinú ìlú náà, nítorí Olúwa Ọlọ́run Alágbara àti Ọ̀dọ́ àgùntàn ni tẹ́ḿpìlì ibẹ̀. 23 Ìlú náà kò nílò òòrùn tàbí òsùpá láti mọ́lẹ̀ síi nítorípé ògo Ọlọ́run ń tàn àn síi, àti Ọ̀dọ́ àgùntàn sì ni ìmọ́lẹ̀ ibẹ̀. 24 Àwọn orílẹ́-èdẹ̀ yóò rìn nípasẹ̀ ìmọ́lẹ̀ ìlú náà. Àwọn ọba ayé yóò wá pẹ̀lú asọ ìgúnwà wọn sínú rẹ̀. Àwọn orílẹ́-èdè tí a gbàlà yóò rìn nípasẹ̀ ímọ́lẹ́ ìlú náà. 25 A kì yóò ti àwọn ilẹ̀kùn rẹ̀ ní ojù ọjọ́, àti wípé kò ní sí òru níbẹ̀. 26 Wọn yóò mú ìgúnwà wá àti ọlá àwọn orílẹ́-èdẹ̀ wá sínú rẹ̀. 27 Ohun àìmọ́ kankan kì yó wọ inú rẹ̀ láí. Kì yóò sí ẹnikẹ́ni tí ó ń se ohun ìtìjún kankan tàbí tan nijẹ tí yó wọ inú rẹ̀, ṣùgbọ́n àwọn tí a kọ orúkọ wọn sínú Ìwé Iyè ti Ọ̀dọ́àgùntàn.