1 Nígbànáà ní ángẹ́lì náà fi odò tí ńṣàn fún omi ìyè hàn mí, tí ó mọ́ bi krístálì. Ó ń ṣàn wá láti ìtẹ́ Ọlọ́run àti ti ọ̀dọ́-àgùntàn náà. 2 Ní àárín òpópónà ìlú náà. Ní ẹ̀gbẹ̀gbẹ́ odò náà ni igi ìyè wà, tí ń so oríṣi èso méjìlá, tí o sí ń so èso rẹ̀ ní gbogbo oṣù. Àwọn ewé igi náà wà fún ìwòsàn àwọn orílẹ̀-èdè. 3 Kì yóò sí ègún kankan mọ́. Ìtẹ́ Ọlọ́run àti ti ọ̀dọ́-àgùntàn náà yóò wà ní inú ìlú náà, àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ yóò sì sìn-ín. 4 Wọn yóò rí ojú rẹ̀, orúkọ rẹ̀ yóò sí wà ni iwájú-orí wọn. 5 Kì yóò sí àṣálẹ́ mọ, wọn kì yó nílò ìmọ́lẹ̀ àtùpà tàbí ìmọ́lẹ̀ oòrùn nítorí Olúwa Ọlọ́run yóò tàn sí wọn. Wọn yóò sì jọba laí àti laílaí. 6 Ángẹ́lì náà wí fún mi pé, "Àwọn ọ̀rọ̀ yìí ní ìgbẹkẹ̀lé, wọ́n sì jẹ́ òtítọ́. Olúwa, Ọlọ́run ẹ̀mí àwọn wòlí, rán ángẹ́lì Rẹ̀ láti fi han ìránṣẹ́ Rẹ̀ ohun tí ó gbọ́dọ̀ ṣẹlẹ̀ láìpẹ́. 7 Wòó!, èmi ńbọ̀ láìpẹ́, ìbùkún ni fún ẹni náà tí ó ṣe ìgboràn sí àwọn ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ inú ìwé yìí. 8 Èmi, Jòhánù, ni ẹni náà tí ó gbọ́ tí ó sì rí àwọn ǹkan wọ̀nyí. Nígbàtí mo gbọ́ tí mo sì rí wọn, mo wólẹ̀ níwájú ẹ́sẹ̀ ángẹ́lì náà láti sìn-ín, ángẹ́lì náà tí ó fi àwọn ǹkan yìí hàn mí. 9 Ó wí fún mi pé, "máṣe bẹ́ẹ̀, ìránṣẹ́ bíìrẹ ní èmi jẹ́, àti pẹ̀lú àwọn arákùnrin rẹ tí ṣe àwọn wòlí àti pẹ̀lú àwọn tí ó ṣe ìgboràn sí àwọn ọ̀rọ̀ inú ìwé yíì. Ẹ sin Ọlọ́run!" 10 Ó wí fún mi pé, " máṣe fi àwọn ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ inú ìwé yìí pamọ́ nítorí àkókò ná súnmọ́. 11 Ẹni tí ó jẹ́ aláìṣòdodo, kí ó tẹ̀síwájú nínu àìsòdodo. Ẹni tí ń wùwà àìmọ́ kí ó tẹ̀síwájú nínu ìwà àìmọ́ rẹ̀. Ẹni tí ńse òdodo, kí ó tẹ̀síwájú láti máà ṣe ohun tí ó jẹ́ òdodo. Ẹni tí ó jẹ́ mímọ́, kí ó tẹ̀síwájú láti ma jẹ́ mímọ́. 12 Wòó, Èmi ń bọ̀ láìpẹ́. Èrè mí wà pẹ̀lú mi, làti sán padà fún olúkúlùkù gẹ́gẹ́ bi ohun tí ó ti ṣe. 13 Èmi ni Álfà àti Òmégà, àkọ́kọ́ àti ìgbẹ̀yìn, ìbẹ̀rẹ̀ àti òpin. 14 Ìbùkún ni fún àwọn tí wọ́n fọ aṣọ wọn kí wọ́n lè ní ẹ̀tọ́ làti jẹ nínu igi-ìyè náà kí woń sì lè bá àwọn ẹnu-ọnà wọ inú ìlú náà. 15 Ní ìta ni àwọn ènìyàn búburú wà, àwọn oṣó, àwọn tí ń fi àgọ́-ara wùwà áìmọ́, àwọn ápanìyàn, àwọn ábọrìṣà àti gbogbo ẹni tí ó fẹ́ràn tí ó sì ń wùwà èké. 16 Èmi, Jésù, ti rán ángẹ́lì mi láti jẹ́ẹ̀rí fun yín nípa àwọn ńkan wọ̀nyí fún àwọn ìjọ. Èmi ni gbòngbò àti irú-ọmọ Dáfídì, ìràwọ̀ òwúrọ̀. 17 Ẹ̀mí àti ìyàwó náà wípé, "Wá!", kí ẹni náà tí ó gbọ́ kó wípé, "Wá!" ẹnikẹ́ni tí òngbẹ ńgbẹ kí o wa, ẹnikẹ́ni tí ó bà sì ń pòngbẹ, jẹ́ kí o gba omi ìye ní ọ̀fẹ́. 18 Èmi ń ṣe ìjẹ́èrí fún gbogbo ènìyàn tí ń gbọ́ ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ tí ń bẹ nínu ìwé yíì: Bí ẹnikẹ́ni bá ṣe àfikún wọn, Ọlọ́run yóò mú kí àwọn àjàkálẹ̀-àrùn tí a ti kọ nípa wọn sínu ìwé yíì wá sí orí rẹ̀. 19 Tí ẹnikẹ́ni bá sì ṣe àyọkúrò nínu àwọn ọ̀rọ̀ tí ń bẹ nínu ìwé àsọtẹ́lẹ̀ yíì, Ọlọ́run yóò mú ìpín-in rẹ̀ kúrò nínu igi-ìyè náà àti nínu ìlú mímọ́ náà tí a ti kọ nípa wọn sínu ìwé yíì. 20 Ẹnití ó jẹ́èrí sí àwọn nkan wọ̀nyí si wípé, "Bẹ́èní! Èmi ńbọ̀ láìpẹ́". Àmín! máabọ̀ Jésù Olúwa! 21 Kí ore-ọ̀fẹ́ Jésù Olúwa kí ó wà pẹ̀lú gbogbo yín. Àmín.