1 Nígbànáà ní mo rí ángẹ́lì kan ń sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run wá. Ó ní kọ́kọ́rọ́ sí ọ̀gbun tí kò ní ìsàlẹ̀, ó sì ní ẹ̀wọ̀n ńlá ní ọ̀wọ́ rẹ̀. 2 Ó sì di drágónì náà, ejò àtijọ́ náà, èyí tí í ṣe èṣù, tàbí Sátánì, ó sì dè é fún ẹgbẹ́rún ọdún kan. 3 Ó jù ù sínú ọ̀gbun tí kò ní ìsàlẹ̀ náà, ó tì í pa ó sì fi èdìdí dì í mọ́ ọ. Èyí ṣẹlẹ̀ kí ó má baà lè tan àwọn orílẹ́ èdè jẹ mọ́ títi tí ẹgbẹ̀rún ọdún náà yíò fi kọjá. Lẹ́yìn náà, a gbọ́dọ̀ tú u sílẹ̀ fún àkókò ìgbà díẹ̀. 4 Nígbàná ni mo rí àwọn ìtẹ́. Àwọn tí ó jókòó lórí wọn ní ati fi àṣẹ fún láti ṣe ìdájọ́. Mo sì tún rí àwọn ọkàn àwọn tí a ti pá nítorí ìjẹ̀rí wọn nípa Jésù àti nítorí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run náà. Wọn kò tí ì foríbalẹ̀ fún ẹranko tàbí ère rẹ̀ rí, wọ́n sí ti kọ̀ láti gba àmìn sí iwájú orí wọn tàbí sí ọwọ́ wọn. Wọ́n di i ààyè, wọ́n sì jọba pẹ̀lú Krístì fún ẹgbẹ̀rún ọdún. 5 Àwọn òkú yókù kò jí sáyé padà títí tí ẹgbẹ̀rún ọdún náà fí parí. Èyí ni àjíǹde àkọ́kọ́ náà. 6 Alábùkúnfún àti mímọ́ ní ẹnikẹ́ni tí ó ní ìpín nínú àjíǹde ti àkọ́kọ́ náà! Ikú kejì kò ní agbára lórí àwọn wọ̀nyí. Wọn ó jẹ̀ àlùfáà Ọlọ́run àti ti Krístì wọ́n yó sì jọba pẹ̀lú Rẹ̀ fún ẹgbẹ̀rún ọdún. 7 Lẹ́yìn tí ẹgbẹ̀rún ọdún náà bá wá sí ìparí, Sátánì yí ó di títú sílẹ̀ láti inú túbú rẹ. 8 Òun yóò jáde lọ́ láti tan àwọn orílẹ́èdè jẹ ni àwọn igun mẹ́rin ayé - Gọ́gù àti Mágọ́gù láti kó wọn jọ papọ̀ fún ogun náà. Wọn ó dàbi iyanrìn òkun ní yanturu. 9 Wọ́n gòkè lọ sí ilẹ̀ tí ó tẹ́jú wọ́n sì yí agbo ìpàgọ́ àwọn onígbàgbọ́ ká, ìlú tí a yànfẹ́. Ṣùgbọ́n iná sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run wá ó sì jó wọ́n run 10 Èṣù náà, tí ó ti tàn wọ́n jẹ, ni a gbé sọ sínu adáguń súfúrì tí ń jóná, níbití a ti gbé ẹranko náà àti wòlí èké náà sọ sí. A ó maa dá wọn lóró ni òwúrọ̀ àti alẹ́ láí àti láíláí. 11 Nígbànáà ni mo rí ìtẹ́ funfun ńlá kan àti Ẹni tí ó jókò lóri rẹ̀. Ayé àti ọ̀run fò lọ kúrò ní iwájú Rẹ, ṣùgbọ́n kò sí ààyè tí wọ́n lè lọ 12 Mo rí òkú - àwọn alágbára àti àwọn tí kò ṣe pàtàkì - dúró ní iwájú ìtẹ́ náà, a sì ṣí àwọn ìwé náà. Nígbà náà ni a ṣí ìwé míràn - Ìwé Ìyè náà. A dá àwọn òkú náà lẹ́jọ́ nípa ohun tí a ti kọ sílẹ̀ nínú àwọn ìwé náà, gẹ́gẹ́ bí ìṣe wọn. 13 Òkun sì yọ̀nda àwọn òkú tí ó wà nínu rẹẹ̀. Ikú àti àwọn ipò òkú jọ̀wọ àwọn òkú tí ó wà nínu wọn, a sì dá àwọn òkú náà lẹ́jọ́ gẹ́gẹ́ bí ohun tí wọ́n ti ṣe. 14 A sì gbé Ikú àti àwọn ipò òkú sọ sínu adágún iná . Èyí ni ikú kejí - adágún iná náà. 15 Bí a kò bá rí orúkọ ẹǹkẹ́ni nìnú Ìwé Ìye, a gbé e sọ sí inu adágún iná.