1 Lẹyin nkan won yii, mo gbọ́ oun tí o dún bi ti ohùn ọ̀pọ̀ eniyan ni ọ̀run tio oun wipe,"Alleluyah. igbala, ògo ati agbara jẹ́ ti Ọlọrun wa. 2 Otitọ ati ododo ni idajọrẹ, nitori ti oti se idajọ alagbere nla ni tio ba aye jẹ nipa agbere rẹ. Oti gba ẹsan ẹjẹ awon iransẹ rẹ. ti Òun tì kararẹ̀ ta silẹ." 3 Won tun sọ̀rọ lẹrin keji wipe: "Alleluyah! Eefin ti ararẹ̀ dìde lai ati titi lai." 4 Awon agbagba mẹrinlelogun ati awon ẹda alaye mẹrin ni wolẹ won si foribalẹ̀ fun Ọlọrun, tio joko lori ìtẹ́. Won wipe, "Amin. Alleluyah!" 5 Oun kan si ti ori itẹ wa wipe, "ẹyin Ọlọrun wa, gbogbo eyin iransẹ rẹ, ẹyin tio beru rẹ̀, eyin alailókun ati eyin alagbara." 6 Lẹyin na ni mogbọ oun to dabi ohùn ọ̀pọ̀ awon eniyan, gẹgẹ bi rúrù omi, ati ti iro àrá wipe, "Alleluyah! Oluwa jọba, Ọlọrun ti o jọba lori oun gbogbo. 7 Ẹje kia yọ, ki inu wa ki o si dun gidigidi, kia si fi ogo fun nitori igbeyawo ọdọ agutan tide, aya rẹ si ti mura tan. 8 Afun ni iyon da lati wọ asọ ọgbọ funfun: nitori asọ ogbọ naa ni isẹ ìsòdodo awon eniyan mimọ Ọlọrun. 9 Angẹli naa wifun mi pe, "kọ eyi nii: alabukun fun ni awon ti ape si ibi ayẹyẹ igbeyawo ọdọ agutan." O si tun wi fun mi pe, "Won yi ni ọrọ ododo Ọlọrun." 10 Mo wólẹ̀ lẹsẹ rẹ lati jọsin fun, osi wifun mi pe, Ma se se èyí ni! iransẹ birẹ ni èmi ati ti awon arakunrin rẹ ti o di ẹri nipa Jesu mu sinsin. Sin Ọlọrun nitoripe, ẹri nipa Jesu ni ẹmi isọtẹlẹ." 11 Nigbana ni mo si ri ọrun si silẹ, siwo, ẹsin funfun kan. Ẹni tio wa lori ẹsin naa lanpe ni, olododo ati olotitọ. Pẹlu otitọ ni ofin se idajọ tio si fin jagun aye. 12 Oju rẹ si dabi ọwọ iná, lori rẹ ni asi ri awon ade wura. Oni apelé orukọ kan ni ori rẹ ti ẹnikẹni komọ afi òun tìkararẹ̀. 13 Ówọ asọ ti arì bọ inu ẹ̀jẹ̀, a sin pe orukọ rẹ ni ọ̀rọ̀ Ọlọrun. 14 Awon ogun ọrun n tọ lẹyin pẹlu ẹsin funfun, won wọ asọ ọgbọ, mimọ tio si funfun 15 Idà mímú kan ti ẹnu rẹ jade wa eyi tí ofi sẹgun awon orilẹ ede ti yio si fi dari won pẹlu ọ̀pá irin. Óun tẹ ifunti waini ibinu ati irunu Ọlọrun Olodumare. 16 Oni orukọ kan ni ara asọ ati itan rẹ:"OBA AWON OBA ATI OLUWA AWON OLUWA." 17 Mo si ri angẹli kan ti oduro ninu òrùn. Oke ni ohùn rara si gbogbo awon ẹyẹ tion fo loju ọrun, "Ẹwa, ẹkojọpọ fun àsè nla ti Ọlọrun. 18 Ẹwa ẹje ninu ẹran ara awon ọba, awon olori ologun, ati ẹran ara awon ẹni alagbara, ati ẹran ara eniyan gbogbo, ati ti ominira, ati ti ẹrú, ati ti ewe ati ti àgbà." 19 Mosi ri ẹranko naa ati awon ọba aye pẹlu awon ogun won. Won kojọpọ fun arawon lati doju ogun ko ẹni tio wa lori ẹsin ati awon ogun rẹ. 20 Akápá ẹranko naa pẹlu awon woli eke rẹ ti on se awon àmì niwajurẹ. Pẹlu ami yi ni ófín tan gbogbo awon ti o gba ami ẹranko naa ti o sin foribalẹ fun aworan rẹ. Akó awon mejeji dapọ sọ sinu ina ti on fi tunfulu jo. 21 Apa awon tí ókù pelu idà tio ti ẹnu ẹni ti ojoko lori ẹsin naa. Àpapọ̀ awon ẹyẹ si jẹ òkú ẹran arawon.