1 Lẹ́yìn àwọn ǹ kan wọ̀nyí mo rí ańgélì kan sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run. Ó ní àṣẹ ń lá, ògo rẹ̀ sì tan ìmọ́lẹ̀ yí ayé ká. 2 Ó kígbe ní ohùn rara, wípé, "Óṣubú, Bábílónì ńlá ṣubú! Ó ti di ibùgbé fún àwọn ẹ̀mí òkùnkùn, ibi ìsádi fún àwọn ẹ̀mí àìmọ́ gbogbo, ibi ìsádi fún gbogbo ẹyẹ àìmọ́ àti ìríra. 3 Nítorí gbogbo orílẹ̀ èdè ti mu ọtí i wáìnì ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ̀. Àwọn ọba ayé ti ṣe ìfẹ́kúfẹ̀´ pẹ̀lú u rẹ̀. Àwọn oníṣòwò ayé ti di ọlọ́rọ̀ nípasẹ̀ agbára ìgbé ayé ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ̀." 4 Nígbà náà ni mo gbọ́ ohùn kan láti ọ̀run wí pé, "Jáde kúrò nínù rẹ̀, ẹ̀yin ènìyàn mi, kí ẹ má baà pín nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, kí ẹ̀yin kí ó sì má ṣe ní ìpín nínú àjàkálẹ̀ àrùn rẹ̀. 5 Ẹ̀ṣẹ̀ ẹ rẹ̀ ti ga dé ọ̀run, Olúwa sì ti rańtí iṣẹ́ ibi rẹ̀ gbogbo. 6 San án padà fún un bí ó ti ṣe san án padà fún àwọn ẹlòmíràn, san án padà fún un ní ìlọ́po méjì ohun tí ó ti ṣe; aago tí ó ti pò pọ̀, pòó ní ìlọ́po méjì fún un. 7 Bí ó ti ṣe ara rẹ̀ lógo tí ó sì ń gbé nínú ọrọ̀ púpọ̀, fi ìyà púpọ̀ jẹ ẹ́ àti ìwúwo ọkàn. Nítorí ó wí ní ọkàn rẹ̀ pé, 'Mo jókòó bí Ayaba; è mi kìí ṣe opó, bẹ́ẹ̀ ni è mi kì yóò rí ọ̀fọ̀.' 8 Nítorí náà, ní ọjọ́ kan ni àjàkálẹ̀ àrùn rẹ̀ yóò dé: ikú, ọ̀fọ̀, àti ìyàn. Iná yóò jẹ ẹ́ run, nítorí alágbára ni Olúwa Ọlọ́run, òn sì ni onídàjọ́ọ́ rẹ̀." 9 Àwọn ọba ayé tí ó ṣe ìfẹ́kúfẹ̀é pẹ̀lú u rẹ̀ tí o sì ṣi ìwà hù pẹ̀lú u rẹ̀ yóò sọkún, wọn yóò sì pohùn réré ẹkún lórí i rẹ̀ nígbà tí wọ́n bá rí èéfín sísun rẹ̀. 10 Wọn yóò dúró ní òkèèrè jíjìn réré, ìjìyà a rẹ̀ bà wọ́n lẹ́rù, wípé, "Ègbé, ègbé sí ìlú ńlá náà, Bábílónì, ìlú alágbára náà! Nítorí ní wákàtí kan ṣoṣo ìjìyà a rẹ dé." 11 Àwọn oníṣòwò ayé sọkún, wọ́n sì ṣọ̀fọ̀ fún un, nígbà tí ẹnikẹ́ni kò ra ọjà a rẹ̀ mọ. 12 Ọjà wúrà, fàdákà, òkúta iyebíye, píálì, aṣọ ọ̀gbọ̀ dáradára, elése àlùkò, sílíkì, aṣọ pupa, oríṣiríṣi igi olóòórùn dídùn, gbogbo ohun èlò eyín erin, ohun èlò tí a fi igi olówó iyebíye ṣe, idẹ, irin, òkúta mábù, 13 Sínámónì, ata olóòórùn dídùn, tùrààrí oríṣiríṣi, ọtí wáìnì, òróró, ìyẹ̀fun kíkúnná, ọkà, mààlúù àti àgùntàn, àwọn ẹṣin àti kẹ̀kẹ́ ogun, àti ẹrú àti àwọn ènìyàn. 14 Èso tí ó pòǹgbẹ fún pẹ̀lú agbára a rẹ̀ ti bọ́ lọ́wọ́ ọ rẹ̀. Gbogbo ọrọ̀ àti ọlá a rẹ̀ ti parẹ́, a kì yóò tún rí wọn mọ́. 15 Àwọn oníṣòwò ọjà wọ̀nyí tí ó ti di ọlọ́rọ̀ nípasẹ̀ rẹ̀ dúró takété sí i lókèèrè nítorí ìbẹ̀rù ìpọ́njú rẹ̀, ẹkún àti ìpohùn réré ẹkún rẹ̀. 16 Wọn yóò wípé, "Ègbé, ègbé sí ìlú ńlá náà tí ó wọ aṣọ ọ̀gbọ̀ dáradára, elése àlùkò, aṣọ pupa, tí a fi wúrà ṣe lẹ́ṣọ̀ọ́, ẹ̀ṣọ́ olówó iyebíye, àti píálì! 17 Ní wákàtí kan, gbogbo ọrọ̀ náà ti di ègbé. "Gbogbo ọ̀gá ọkọ̀ ojú omi, àwọn arìnrìnàjò lójú omi, àwọn atukọ́, àti àwọn tí ó ń ṣòwò lójú omi, dúró lókèèrè réré. 18 Wọ́n kígbe sókè nígbàtí wọ́n rí èéfín sísun rẹ̀. Wọ́n wípé, "Ìlú wo ló dàbí ìlú ń lá náà?" 19 Wọ́n da erùpẹ̀ sí orí ara wọn, wọ́n kígbe sókè, wọ́n ń sọkún, wọ́n sì ń ṣọ̀fọ̀, "Ègbé, ègbé, sí ìlú náà nípasẹ̀ ẹni ti àwọn tí ó ní ọkọ̀ ojú omi ti di olówó nípa ọrọ̀ ọ rẹ̀. Nítorí pé, ní wákàtí kan a sì paárun." 20 "Yọ̀ lórí i rẹ̀, ọ̀run, ẹ̀yin onígbàgbọ́, ẹ̀yin àpóstélì, àti ẹ̀yin wòlíì, nítorí Ọlọ́run tí mú ìdájọ́ yín wá sórí i rẹ̀!" 21 Ańgẹ́lì ńlá kan sì gbé òkúta ńlá kan bí ọlọ ńlá, ó sọ ọ́ sínú òkun wípé, "Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, Bábílónì, ìlú ńlá náà, ni a ó fi ipá fàá lulẹ̀, a kì yóò sì rí i mọ́. 22 Ìró àwọn tí ń lu Háàpù, àwọn oní fèèrè, àwọn akọrin, àwọn tí ó ń fun ohùn ìpè, àwọn tí ó ń fun fèèrè ni a kì yóò gbúròó nínù rẹ mọ́. A kì yóò rí oníṣẹ́ ọnà kankan nínú ù rẹ. A kì yóò gbọ́ ìró ọlọ nínú rẹ mọ́. 23 Ìmọ́lẹ̀ àtùpà kì yóò tàn nínú u rẹ̀ mọ́. Ohùn ọkọ ìyàwò àti ti ìyàwó ni a kì yóò gbọ́ nínú u rẹ̀ mọ́, nítorí àwọn oníṣòwò rẹ ni àwọn ọmọ aládé ayé, a sì tan àwọn orílẹ̀ èdè jẹ nípa ìṣe oṣó ò rẹ. 24 Nínú rẹ̀ ni a gbé rí ẹ̀jẹ̀ àwọn Wòlíì àti àwọn onígbàgbọ́, àti ẹ̀jẹ̀ gbogbo àwọn tí a ti pa ní ayé.