1 Lẹ́yìn ìgbàtí Jésù ti parí gbogbo ohun tí Ó ńsọ fún àwọn ènìyàn tán,Ó wọ kápánámù. 2 Báàyí, ọ̀gágun ọgọ́run kan ni ọmọ ọ̀dọ̀ kan ti ó wúlò fún u, ó se àìsàn, ó sì fẹ́ rẹ̀ kú. 3 Nígbàtí ọ̀gágun ọgọ́run náà gbọ́ nípa Jésù, ó rán àwọn aládarí Júù síi pe kí Ó wá lati mú ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ lára dá 4 Nígbàtí wọ́n dé ọ̀dọ̀ Jésù, wọ́n bẹ̀ ẹ́ gidigidi wípé, "Ó yẹ lẹ́ni tí Ìwọ yio se èyí fún, 5 Nítorípé o níìfẹ́ orílẹ̀èdè wa, oun ni ó kọ́ sínágọ́gù wa fún wa." 6 Nítorínà Jésù nbá wọn lọ. Ṣùgbọ́n nígbàtí Ó súnmọ́ ilé náà, ọ̀gágun ọgọrun náà rán àwọn ọ̀rẹ́ lati sọ fún u pé, "Olúwa, máse yọ ara rẹ lẹ́nu nítorípé èmi kò yẹ ní ẹnití Ìwọ yíò wọ ilé mi. 7 Ìdí yi ni èmi kò fi ròó láti wá sọ́dọ̀ Rẹ, sùgbọ́n, sọ ọ̀rọ̀ kan, ara ìránsẹ́ mi yío sì yá. 8 Nítorípé èmi náà jẹ́ ẹnití ó wà làbẹ̀ àsẹ, mo sì ní àwọn ọmọ ogun tí mo ndarí. Mo sọ fún ẹnìkan, 'lọ', yio sì lọ, ati fún òmíràn, 'wá', yio sì wá, àti fún ìránsẹ́ mi, 'se nkan yi', yio si se é." 9 Nígbàtí Jésù gbọ́ èyí, ẹnu yà á sii, Ó sì kọjú sí àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn tí ó ntọ̀ ọ́ lẹ́yìn, ó wípé, "Mo wí fún u yín, èmi kò rí irú ìgbàgbọ́ yi ri, àní ní Israeli." 10 Nígbàtí àwọn tí ó rán sì padà dé ilé, wọ́n bá ìránsẹ́ náà tí ara rẹ̀ ti yá. 11 Kò pẹ́ lẹ́hìn èyí, Jésù lọ si ìlú kan tí à npé ní Naini, àwọn ọmọ ẹ̀yìn Rẹ̀ àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn bá a lọ. 12 Ó súnmọ́ ẹnu ọ̀nà ìlú náà, wọ́n gbé òkú ọkùnrin kan, tí ó jẹ́ ọmọkùnrin kansoso tí ìyá rẹ bí (ẹnití ó jẹ́ opó), ọ̀pọ̀ ero lati ìlú naa si wa lọ́dọ̀ ọ rẹ̀. 13 Nígbàtí Olúwa sì rii, àánú rẹ se é gidigidi, Ó sì wí fún u pé "Ma sunkún." 14 Nígbànáà ni Ó súnmọ́ ọ, Ó sì fi ọwọ́ kan fírémù igi tí wọ́n fi gbé òkú rẹ̀, àwọn tí ó gbé e sì dúró wámúwámú. Ó wípé, "Ọ̀dọ́mọdékùnrin, mo wí fún ọ, dìde." 15 Ọkùnrin tí ó ti kú náà sì dìde joko, Jésù si fà á lé ìyá rẹ̀ lọ́wọ́. 16 Ẹ̀rù sì bà gbogbo wọn, wọ́n fi ìyìn fún Ọlọ́run, wípé, "Wòólì nlá kan ti dé sí àrin wa" àtipé "Ọlọ́run ti se ìtọ́jú àwọn ènìyàn rẹ̀." 17 Ìròyìn yí nípa Jésù sì tàn kiri gbogbo Judea ati gbogbo àwọn agbègbè tí ó yíi ka kiri. 18 Àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jòhánù sì sọ gbogbo nkan wọ̀nyí fún u. 19 Nígbànáà ni Jòhánù rán àwọn méjì nínú àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ sí Olúwa, wípé, "Sé ìwọ ni ẹnití nbọ̀ àbí kí à ma retí ẹlòmírán?" 20 Nígbàtí wọ́n sì dé ọ̀dọ̀ Jésù, àwọn ọkùnrin náà wípé, "Jòhánù Onítẹ̀bọmi rán wa sí Ọ wípé, 'Sé ìwọ ni ẹnití nbọ̀ àbí kí á ma reti ẹlòmíràn?'" 21 Ní àkókò náà, Ó wo ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn sàn nínú àwọn àìsàn, ìpọ́njú àti àwọn ẹ̀mí búburú, ọ̀pọ̀ afọ́jú ni Ó là lójú. 22 Jésù dáhùn, ó wí fún wọn pe, "lẹyìn tí ẹ bá padà, ẹ ròyìn ohun tí ẹ rí àti ohun tí ẹ gbọ́ fún Jòhánù, àwọn afójú nriran, àwọn arọ nrin, adẹ́tẹ̀ ndi mímọ́, odi ngbọ́ràn, a njí àwọn òkú dìde, à nsọ ìròyìn ayọ̀ fún àwọn aláìní. 23 Ìbùkún ni fún ẹnití ìgbàgbọ́ rẹ̀ nìpa ìse mi kò yẹ̀" 24 Lẹ́yìn tí àwọn tí Jòhánù ràn nísẹ́ ti lọ, Jésù nbá àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn sọ̀rọ̀ nípa Jòhánù, "Sé ewéko tí afẹ́fẹ́ ńfẹ́ ni o ńwá lọ sí asálẹ̀? 25 Sùgbọ́n kíni ohun tí o fẹ́ rí níbẹ̀? Se ọkùnrin tí o wọ asọ fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́? Kíyèsi, nínú ààfin ni àwọn to ńwọ asọ olówó nla, tí wọ́n si ngbé nínú ìgbádùn wà. 26 Sùgbọ́n kíni ẹ̀yin wá lọ? Sé wòólì kan? Òtítọ́ ni, ó tún ju wòólì lọ." 27 Èyí ni ẹnití àwọn wòólì kọ nípa Rẹ̀, "kíyèsi, mo nrán òjísẹ́ mi síwájú Rẹ̀, oun ni yio tún ọ̀nà se. 28 Èmi wí fun yin pe, kò sí ẹnikẹ́ni tí a bí nínú obìnrin tí o pọ̀ju Jòhánù lọ. Síbẹ̀, ẹnití ó kéré jù ní ìjọba Ọlọ́run pọ̀ jù ú lọ." 29 (Nígbàtí gbogbo àwọn ènìyàn náà si gbọ́ èyí, àti àwọn agbowó òde, wọ́n jẹ́wọ́ wípé Olódodo ni Ọlọ́run, nítorí ìtẹ̀bọmi Jòhánù tí wọ́n ti se. 30 Sùgbọ́n àwọn Farisí àti amòfin Ju kọ ète Ọlọ́run fún ara wọn, nítotípé Jòhánù ko tíì tẹ̀ wọ́n bọmi.) 31 "Èyí ni mo fi àwọn ènìyàn ìran yí wé, kíni wọ́n jọ? 32 Wọ́n dàbí àwọn ọmọdé tí wọn ńseré ní àrin ọjà, wọ́n joko, wọ́n si npe ara wọn wípé 'A fọn fèrè, ìwọ kòjó, a kọrin ọ̀fọ̀, ìwọ kòsunkún.' 33 Nítorí Jòhánù wá, kò jẹun, kò sì mu wáìnì, ẹ̀yin sì wípé, 'Ó ní ẹ̀mí èsù.' 34 Ọmọ ènìyàn wa, Ó ńjẹun, Ó sì ńmu, ẹ̀yín sì wípé, 'Kíyèsi, ọkùnrin yi jẹun jù, ọ̀mùtí sì ni, Ó ńba àwọn agbowó òde àti àwọn ẹlẹ́sẹ̀ se ọ̀rẹ́!' 35 Ṣùgbọ́n, ọgbọ́n Ọlọ́run fi ẹsẹ̀ múlẹ̀ nìpa àwọn ti o ntẹ̀ lé e." 36 Farisí kan sì pe Jésù láti jẹun papọ̀, lẹ́yìn tí Jésù wọ inú ilé Farisí náà, Ó joko lati jẹun ní tábìlì. 37 Kíyèsi, obìrin ẹlésẹ̀ kan lati ìlú náà wà. Nígbàtí oun mọ̀ wípé Jésù njẹun lori tábìlì ní ilé Farisí náà, ó mú òróró ìkura olóòrun díduǹ nínu ìgò Alabásítérì. 38 Bí o tí sún mọ́ Ọ, o nsunkún, o si nwẹ ẹsẹ̀ Jésù pẹ̀lú omijé rẹ̀, o tún nfi irún orí rẹ nu u, o fi ẹnu ko ẹsẹ̀, ó fi òróró ìkura olóòrun díduǹ pa á. 39 Nígbàtí Farisí tí ó pe Jésù rí i, ó rò nínú ọkán rẹ pé, bí ọkùnrin yi ba jẹ́ wòólì yi O mọ irú obìnrin ti o nfi ọwọ́ kàn án, pé ẹlẹ́sẹ̀ ni. 40 Jésù dáhùn, o sì wípé, "Símónì, mo fẹ́ bá ọ sọ̀rọ̀." Oun sì wípé, "Olùkóni, Ẹ sọ̀rọ̀!" 41 Jésù wípé, onigbèsè méji jẹ ayánilówó kan lówó. Ẹni ẹ̀kíní jẹ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta dénárì, ẹnìkejí jẹ àádọ́ta. 42 Nígbàtí wọn kò lè san an, O dáríji àwọn méjèjì. Nítorínáà,tani yio fẹ́ràn rẹ jù? 43 Símóni dáhùn pé, "Mo rò pé ẹnití ó dáríjì jùlọ." Jésù wípé, "Ìdájọ́ rẹ tọ̀nà." 44 Jésù kọjú sí obìnrin náà, Ó sì wí fún Símóni pé, "Wo obìnrin yi. Mo wọ ilé rẹ. Ìwọ kò sì fún mi ní omi lati fọ ẹsẹ̀ mi, ṣùgbọ́n oun wẹ ẹsẹ̀ mi pẹ̀lú omijé rẹ̀, o tún nfi irún orí rẹ nu u. 45 ìwọ ko fi ẹnu ko mi , ṣùgbọ́n oun kò dúró fífi ẹnu kò mí ní ẹsẹ̀ lati ìgbàtí mo ti wọ lé. 46 Ìwọ kò fi òróró ku orí mi ṣùgbọ́n oun ti fi òróró ìkura olóòrun díduǹ pa ẹsẹ̀ mi. 47 Nítorínáà, mo wí fún ọ, a ti dárí gbogbo ẹ̀sẹ̀ rẹ jin- nítorí ìfẹ rẹ pípọ̀. Ṣùgbọ́n ẹnití a dárí ẹ̀sẹ̀ díẹ̀ jìn, fi ìfẹ́ díẹ̀ han. 48 Ó sì wí fún obìnrin náà pé, "A dárí gbogbo ẹ̀sẹ̀ rẹ jìn ọ́." 49 Àwọn tí o joko lati jẹun ní tábìlì si nsọ láàrin ara wọn pé "Tani okùnrin to ndari ẹ̀sẹ̀ jìn?" 50 Jésù si sọ fún obìnrin náà pé, "A gbà ọ́ là nítorí ìgbàgbọ́ rẹ. Má a lọ ni àáláfíà."