Orí Kẹjọ

1 O sì ṣé bi Jésù ti n la ìlú ati abúlé kọjá, Ó ń wàásù, Ó ń ròyìn ìnhìnrere ayọ́ ti ijọba ọrun: àwọn méjìlá sì ń wà lọdọ̀ Rẹ̀, 2 Pẹlu àwọn obìnrín ti a ti mú láràda kúrò nínu ẹ̀mí búburú àti àarun wọn, Màríà tì à ńpè ní magaleni, lára ẹnití ẹ̀mí èsù méje ti jáde kùró, 3 Àti Jòánnà ìyàwó Kusa, ìránsẹ́ Ẹ́rọ́dù, ati Sùsánna pẹ̀lú àwọn míràn tí wọ̀n fi ohun ìní wọ́n sílẹ̀ láti bá àiní wọn pàdé. 4 Nígbàtí ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn péjọ pọ̀, lati ìlú gbogbo sí tọ̀ ọ́ wá, Ó ń fí òwe bá wọn sọ̀rọ̀ pé, 5 Àgbẹ̀ kan jáde lọ láti gbin irúgbìn re`, bí o sì tí gbín-in, díẹ̀ bọ́ si etí ọ́nà, o si di títẹ̀ mọ́lẹ̀, àwọn ẹyẹ ojú ọrun si sà á jẹ 6 Òmíràn bọ́sí orí òkúta, bí ó sì ti hu jáde, ó gbẹ nítorí tí kòrí ìri. 7 Òmíràn bọ́ si arin ẹ̀gun, ẹgún ba a dagbà sókè, ó sì fún un pa 8 Òmiràn bọ́ sí ilẹ̀ rere, ó sì so èso ọrọ́ọ́rún, lẹyìn ti Ó sọ èyí tan, Ó wípé enítí o ba ni etí lati gbọ, ki ó gbọ́. 9 Àwọn ọmọ ẹyìn Rẹ bere wípé kili itúmọ̀ òwe na 10 Ó wí fun wọn pé, ẹyìn ni afífún láti mọ ìjìnlẹ̀ ìjọba Ọlọ́run, ṣùgbọ́n fún àwọn míràn òwe ni, pé ní rírí kí wọn kí ó má lè rí, ati ní gbígbọ́ kí ó ma lè yé wọn. 11 Ǹjẹ́ ìtúmọ̀ owé na nìyí: irúgbìn ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́run 12 Àwọn ti etí ọnà ni àwọn tí ó gbọ́, ṣùgbọ́n èsù wá ò sí mú ọ̀rọ̀ na kúrò ni ọkàn wọ́n, kí wọ́n kí ó má ba gbàgbọ́, kí a má sì gba wọ́n là. 13 Àwọn tí orií òkúta ni àwọn, tí wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ na, wọ́n gba tayọ̀-tayọ̀. Ṣùgbọ́n wọ́n koni gbọòǹgbo; wọn gbàgbọ fún ìgbà díẹ̀, nígbà akókò idánwò, wọ́n subú. 14 Awọn irúgbìn tí ó bọ́ sí inú ẹ̀gún ní àwọn tó gbọ́ ọ̀rọ̀ naa, ṣùgbọ́n bí wọ́n ti lọ́ won fi itọ́jú ati ọọrọ̀ ati itùra ayé yi fún ún pa, wọ́n ko si só èsó àsogbó. 15 Ṣùgbọ́n irúgbìn tí ó bọ́ sí ilẹ̀ rere, awọ́n ni wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ náà pẹ̀lú òtìtọ́ àtí ọkan tó dára, wọ́n di mu sinsin, wọ́n si fi sùúrù so èso. 16 Kòsí ẹnìkán, nígbàtí óbá tan fìtílà tán, tí yò fi abọ́ bó mọ́lẹ̀ tàbí ti yóò íi sí abẹ́ ibùsùn, bìkòse pé, kí ó gbé e ka orí ọ̀pá fìtílà kí àwọ́n tí ń wolé lé rí ìmọ́lẹ̀ 17 Nítorí kó sí ohun tí à pamọ́ tí a kí yóò fí hàn, bẹ̀ ẹ̀ ni kòsi ohun tí ó pamọ́, tí á kí yóò mọ̀ ati tí kí yóò wá sí ìmọ́lẹ̀ 18 Ǹjẹ́, ẹ sọ́ra bí ẹ̀yin tí ń gbọ́, nítorí ẹni tí ó bá ní, ní a ó íi fún sii, ṣùgbọ́n ẹni tí kòní, lọ́wọ́ rẹ̀ ni a o ti gbà èyí tí ó ró pé òhun ní kúrò lọ́wọ́ rẹ̀. 19 Nígbàná ní ìyá Rẹ̀, ati àwọn arákùnrin Rẹ̀ tọ́ ọ́ wá, wọ́n kó sí lé sunmọn ọ nítori ọ̀pọ̀ ènìyàn. 20 Wọ́n sì wí fún un pé, ìyá Rẹ̀ ati àwọn arákùnrin Rẹ̀ dúró lóde, wọn fẹ́ ri ọ́ 21 Ṣùgbọ́n Jésù dáhùn Ó wípé, ìyá mí ati àwọn arákùnrin mi ni àwọn tí ó n gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí ó sì ń se é. 22 Ó sì se ní ijọ́ kan Ó wọ ọkọ̀ ojú omi pẹ̀lú àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, Ò sì wí fún wọ́n pé; "Ẹ jẹ́ kí á wá kí á kọjá lọ sí apá òdí kejì adágún," wọ́n sí síkọ̀ lọ 23 Bí wọ́n tí ń lọ Ó sùn. Afẹ́fẹ́ líle dìde sí wọn nínú adágún, tó bẹ̀ tí ọkọ̀ wọn bẹ̀rẹ̀ sí ní kún fún omi, wọ́n sì wà nínú ewu. 24 Nígbàná ní àwọn ọmọ ẹyìn Rẹ̀ wa ọdọ rẹ̀, wọ́n sí ji, wọ́n wípé, "Ọ̀gá! Ọ̀gá! àwa ti fẹ́ kú" Ó dìde ó sí bá afẹ́fẹ́ àti rírú omí wí, wọ́n sí dúró jẹ́, ìdákẹ́ rọ́rọ́ sí wà. 25 Nígbàná ni Ó wí fún wọn pé, "ìgbàgbọ́ yín dà?" ẹ̀rú sí bàwọ́n. síbẹ̀ ẹnu sí yà wọ́n, wọ́n bèrè lọ́wọ ara wọn pé, "irú okùnrín wo ní èyí, Ó pàsẹ́, afẹ́fẹ́ àti rírú omi si gbọ́ tirẹ̀?" 26 Wọ́n sì gúnlẹ̀ ní agbègbè àwọn ara Gádárà, tí ó kọjú sí Gálìlì 27 Nígbàtí Ó sọ̀kalẹ̀, ọkùnrin kan tí ó ní àwọn ẹ̀mi èsù wá pàde Rẹ̀. Fún ìgbà pípẹ́ ní kí ì tí wọ́ asọ, bẹ ẹ sí ní kí ì gbé ní inú ilé bikòsé ninu àwọn ibòjì. 28 Nígbàtí ó rí Jésù, ó ké rara, ó sì subù sí iwájú rẹ̀, ó kígbe ní ohùn rara pé, "Kínni ìwọ ní ìse pẹ̀lú mi, Jésù Ọmọ Ọlọ́run Ọ̀gá ògo? Mo bẹ̀ Ọ́, Má se ni mí lára." 29 Nítorí Jésù ti pàsẹ pé kí ẹ̀mí àìmọ́ yí kí ó jáde kúrò nínú arákùnrin náà. Nítorí ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà ni ẹ̀mí àìmọ́ náà ti gbée subú, bó tilẹ̀ jẹ́ wípé wọ́n ti dèé pẹ̀lú ẹ̀wọ̀n ní ọwọ́ àti sẹkẹ̀sẹkẹ̀ ni ẹsẹ rẹ, wọ́n sì tí fi sí abẹ́ ààbò, òhun a sì máa já ìdè náà, àti pé ẹ̀mí èsù máa ń darí rẹ̀ lọ sí inú aginjù. 30 Nigbana ni Jesu bere lọwọ rẹ wipe, Kini orukọ rẹ?" o daun un wipe, "ọpọ ẹmi esu" nitori ọpọ awọn ẹmi esu ti wọ inu rẹ. 31 Wọn n bẹ ẹ ki o ma le awọn lọ si inu koto. 32 Agbo àwọn ẹlẹ́dẹ̀ kán wa níbẹ̀ nibìtí wọn tí jẹ́ un lẹ́gbẹ̀ okè. Ọ̀pọ̀ àwọn ẹ̀mí èsù náá bẹ̀ Ẹ́ láti jẹ́ kí wọ́n o lọ sí inú wọ́n, Ó gba wọ́n láàyè láti lọ 33 Ọ̀pọ̀ ẹ̀mí èsù náá jáde kúrò nínú okùnrin náà lọ sí inu agbo ọ̀pọ̀ ẹlẹ́dẹ̀ náà, agbo ẹran náá sáre lọ sí inú òdò, wọ́n si kú síbẹ̀. 34 Nígbàtí àwọn tí tọ́jú àwọn ẹlẹ́dẹ̀ náá ri i o un ti o sẹlẹ̀, wọ́n sáré lọ sọ fun àwọ́n ènìyàn ní ilú ati agbègbè. 35 Àwọn enìyàn náá lọ́ wo ohun tí ó sẹlẹ̀, lẹ́yìn náà wọ́n wá sọ́dọ̀ Jésu wọn si ri ọkùnrin náà tí ọ̀pọ̀ ẹ́mì èsù jáde lára rẹ̀. Ó jókò lẹ́sẹ̀ Jésù, ó wọ ẹ́wù ósì wá ní àláfíà àti ìlera pípé; ẹ̀rù sí bàwọ́n. 36 Àwọn ti óti ri sọ́ fún wọ́n bi ọkùnrín tí ọ̀pọ̀ ẹ̀mí èsù tí darí tẹlẹ̀ ti wa ni àlàfíà. 37 Lẹ́yìn náà gbogbo ènìyàn agbègbè Gérásìn sọfún Jésù pé kó kúrò lọ́dọ̀ wọ́n, nítorí ẹ̀rù ń lá bò wọ́n. Ó wọ́ inú ọkọ̀ ojú omi láti pádà. 38 Ọkùnrín tí àwọn ẹ̀mí èsù jáde lára rẹ bẹ Jésù lati tẹle, ṣùgbọ́n Jésù da padà, Ó wipé, 39 "Padà sí ilé rẹ̀ lati royìn ní ẹkùnrẹ́rẹ́ ohun tí Ọlọ́run se fún ọ". Ọkùnrin náà lọ, ó un polo ń gó ní gbogbo ìlú ohun tí Jésù se fún un. 40 Nígbàtí Jésù padà, ọ̀pọ̀ enìyàn kí ì káà bọ nítorí wọ́n ti retí Rẹ̀. 41 Kíyèsi, ọkùnrin kan tí wọ́n pè ní Jáírù, ọ̀kan lára àwọn asíwájú ní sínágógù wa ó sí kúnlẹ̀ ní ẹsẹ̀ Jésù, ó bẹ́ Ẹ lati wá sí ilé rẹ̀, 42 Nitòrí ọmọ rẹ̀ kan ṣoṣo, ọmọ ọdún méjìlá, ń kú lọ́. Bí Jésù tí ń kọjá, ọ̀pọ̀ enìyàn yi ká. 43 Obìnrín kan wá nìbẹ́ tí ó ní ìsun ẹ́jè fún ọdún méjìlá tí o sí tí náá gbogbo owó tí oní tán, sibẹ enìkán kó lé wo sán. 44 Ó wá sí ẹ̀yín Rẹ̀, o fí ọwọ́ kán etí asọ Rẹ̀, loju ẹsẹ̀ ìsun ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sí gbẹ́. 45 Jésù wípé, tani o fí ọwọ́ kán mí? gbogbo wọ́n wípé awọ́n kọ́, Pétérù wípé, "Ọ̀gá, ọ̀pọ̀ éníyan yio ká wọn síì ń kọ lù Ọ́," 46 Ṣùgbọ́n Jésù wípé, "ẹ́nìkán fí ọwọ́ kàn mí, nítorì mo mọ̀ pé agbàrà jáde láàra Mí." 47 Nigbàtí obìnrín náá rí pé òun kó lé sá pámọ́ mọ̀, o wá pẹ̀lú ìfòyà ó sí subú niwájú Rẹ̀. Ó sọ́ niwájú gbogbo ènìyàn ìdì tí o fí fí ọwọ́ kàn-an, àti bí oun ti gba iwòsàn lojú ẹ̀sẹ̀. 48 Lẹ́yìn náà Ó wí fún un pé, "ọmọ-bìnrin, igbàgbọ́ rẹ mú ọ lára dá. máà lọ ni àláafíà." 49 Bí Ó sì ti ṣọ̀rọ̀, ẹnìkán wá lati ilé áládarí sínágọ́gù, ó wìpè, " Ọmọ bìnrin rẹ̀ kú. Máse da Olùkọ́ni láàmú mọ́n." 50 Ṣùgbọ́n nígbàtí Jésù gbọ́ èyí, Ó wí fún Jáírù pé, má bẹru; gbàgbọ́ nìkan, ara rẹ̀ ó sì yá. 51 Nígbàtí Ó dè ilé, kó gbá ẹnìkán láyè láti wọlé pẹ̀lú rẹ̀, bíkòse Pétérù ati Jọ̀hánù ati Jákọ́bù, àti bàbá ọmọ ati ìyá ọmọ. 52 Àwọn enìyàn sọ̀fọ̀ wọ́n sí sọkún fún-un, ṣùgbọ́n ó wípé, "Ẹ má sọkún; nítorí kò kú ṣùgbọ́n ó sùn." 53 Ṣùgbọ́n wọ́n ń fí rẹ́rìn-ín, nítorí wọ́n mọ̀ wipé ó ti kú. 54 Ṣùgbọ́n Ó gbà lọ́wọ́ mú Ó pè é, Ó wípé, "Ọmọ, dìde!" 55 Ẹ̀mi rẹ̀ padà, ó sí dìde lójú ẹsẹ̀. Ó wí fún wọn láti fún ní o ún jẹ. 56 Ẹnú ya àwọn òbí rẹ̀, ṣùgbọn Ó wí fun wọ́n láti má sọ́ ohun tí ó sẹlẹ̀ fún ẹnìkan.