Orí Kẹẹrin

1 Nígbà náá Jésù, ẹnití a kú fún ẹ̀mí mímọ́, padà láti odò Jọ́dánì, a sì ti ipasẹ̀ Ẹ̀mí darí rẹ si ní aginjù, 2 ni ibi tí a ti dánwò lati ipasẹ̀ èsù fún ogóji ọjọ́. Òun kò jẹ ohun kan ní àwọn ọjọ́ wọn nì, ni ìparí àkókò náá ebí paá 3 Èsù wi fuǹ pe, "Bì ìwọ́ ba jẹ́ ọmọ Ọlórun, pàsẹ fún òkúta yìì kó di bùrẹ́dì ." 4 Jésù dá lóhùn, "Ati kọ́ pé, Ènìyàn kìí wà láàyè nipa búrẹ́dì nì kan. 5 Nígbà náá ni èsù ntọ́ Jésù lọ sí ibi òkè gigá kan o si fi gbogbo ìjọba ayé hán ní wàràsesà 6 Èsù wí fún pé, "Èmi ó fi gbogbo àṣẹ yíí ati gbogbo didara wọn, nítorí a ti fi wọn fún mi, mo sì le fi wọ́n fun ẹnikẹ́ni tí m fẹ́. 7 Nítorí náá, tí ìwọ o ba fori balẹ̀ kí o si sìn mì, yio jẹ́ tìrẹ. 8 Ṣùgbọ́n Jésù dáhùn ó sì wi fún pé, "Ati kọ́ pé, "Ìwọ o sin Olúwa Ọlọ́run rẹ, o si sin òun nì kan." 9 Nígbà náá ni èsù tọ́ Jésù lọ́ sí Jerúsálẹ́mù o si fi sí otí òkè gíga jùlọ tẹmpìlì, ó si wí fún pé, "bí ìwọ bá íse ọmọ Ọlọ́run, ju ara rẹ sílẹ̀ lati ibí yíí 10 Nítorí ati kọ́ wí pé, 'Òun yóó fí àsẹ fún àwọn ángẹ́lì rẹ̀ ni paà rẹ, lati dá àbò bò ọ́,' 11 o si gbé ọ sókè ní ọwọ́ wọn, kí ìwọ mọ́ ba fi ẹsẹ̀ rẹ jú òkúta." 13 12 Jésù dá lóhùn, o wí pé, "Ati kọ́ pé, 'Mọ́ se dán Olúwa Ọlọ́run rẹ wò.'" 13 Nígbà tí èsú ti parí dídán Jésù wò, ó lọ kúrò o si fíí sílẹ̀ di ìgbà mííràn. 14 Nígbà náá ni Jésù padà sí Gálílì nínú agbára Ẹ̀mí, ìròyìn nípa rẹ̀ sí tàn kákíri gbogbo agbègbè yí ká 15 Nígbà náá ní ó bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ni nínú sínágọ́gù wọn, gbogbo wọ́n si gbóríyìn fún. 16 Òun sí wá sí Násárẹ́tì, níbi ti a ti tọ́ọ́ dàgbà, gẹ́gẹ́ bí ìse rẹ̀, ó wọ inú sínágọ́gù ni ọjọ́ ìsinmi, ó sì dìde lati kà jadé 17 A si fi ìwe wòlí Àìsáyà fún. Ó sí ìwe náá, o si rí ibi tí ati kọ́ pé, 19 18 Ẹ̀mí Olúwa wá lórí, nítorí o fí ìfàmì òróró yán mí lati kéde ìhìnrere fún àwọn tálákà. Òun ti rán mi láti kéde òmìnira fún àwọn òndè ati ìtúnríran fún àwọn afójú, lati tú àwọn tí a ni lára sílẹ̀, láti kéde ọdún ojúrere Olúwa." 20 Ó si ká ìwé náá, o si dá padà fún òsìsẹ́ sínágọ́gù, o si jókó, Gbobo àwọn wà ní sínágọ́gù sí tẹjúmọ́ọ́ 21 Ó bẹ̀rẹ̀ sí sọ fún wọ́n, "Lóni ìwé mímọ́ yíí nii amúsẹ lét´ yín." 22 Gbogbo àwọn tó wà níbẹẹ̀ sọ ohun dáradára nípa rẹ̀, ẹnu sí yà wọ́n si àwọn ọ̀rọ̀ ore-ọ̀fẹ́ tó nti ẹnu rẹ̀ jáde, wọ́n si bí pé, "Èyí kí a se ọmọ Jósẹ́fù bí?" . 24 23 Ó wí fún wọn, "Nítòótọ́ ẹ̀yin o pa òwe yíí fú mi, 'Dókítà, wo ara rẹ sàn. Ohunkóhun ti a gbọ́ pé o se ni Kapanáhúmù, se ohun kan náá ni ìlú abínibí rẹ." Ṣùgbọ́n ó wí pé, "Lóótọ́ ni mo wí fún yin, kò sí wòlíí ti a tẹ́wọ́gbà ni ìlú abínibí rẹ. 26 25 lóótọ́ ni mo wí fún pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ opó ni ó wà ní Ísírẹ́lì ní àkókò Èlíjà, nígbà tí a ṣé ọ̀rún fún ọdún mẹ́ẹta ati osù mẹ́ẹ́fà, ìyàn nlá sí wà ní gbogbo ílẹ. Ṣùgbọ́n, a kò rán Èlíjà si ọ̀kankan nínú wọn, àyàfi sí opó kan tí ó gbé ní Sáréfátì ti Sídónì 27 Ọ̀pọ̀ adẹ́tẹ̀ ni ó wà ní Ísírẹ́lì ní àkókò Èlísà, ṣùgbọ́n a kò wo ọ̀kankan sàn àyàfi Námánì ará Síríà." 28 Gbogbo àwọn tó wà nínú sínágọ́gù si kún fún ìrúnú gidigidi nígbà tí wọ́n gbọ́ nkàn wọ̀n mí 29 Wọ́n dìde, wọ́n fi ipá mú já de ní ìlú náá, wọ́n sí tọ́ lọ si ténté òkè lórí èyí tí a kọ́ ìlu wọn lé lórí, kí wọ́n lé sọ́ sílẹ̀ lati ténté òkè 30 Ṣùgbọ́n ó kọjá láárín wọn, ó sì lọ sí ibò mííràn. 32 31 Nígbà náá ní ó sọ̀kalẹ̀ lọ sí Kapanáhúmù, ìlú kan ni Gálílì, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ wọn ni ọjọ́ ìsinmi. Ẹnú yá wọn si ẹ̀kọ rẹ̀, nítorí ó sọ̀rọ̀ pẹ̀lú àṣẹ. 33 Ní báyíí ọkùn rin kan wà nínú sínágọ́gù tí ó ní ẹ̀mí àìmọ́, ó sì kí gbe ní ohùn rara, 34 Ah! Kíni a ni se pẹ̀lú rẹ, Jésù ti Násárẹ́tì? Njẹ́ ìwó wá latí pa wá run? Mo mọ ẹnití ìwọ́ se - ẹni mímọ́ Ọlọ́run!" 37 35 Jésù bá ẹ̀mí àìmọ́ náá wí, wí pé, Mọ́ se sọ̀rọ̀, sì já de kúrò nínú rẹ̀!" Nígbà tí ẹ̀mí àìmọ́ náá ti gbé okùrin náá sánlẹ̀ láárín wọn, ó jáde kúrò nínú rẹ̀, kò sì páá lára lọ́nà kankan. 36 Ẹnú sí ya gbogbo ènìyàn gidigidi, wọ́n sí nsọ́ fún ara wọn ní pa rẹ̀. Wọ́n wí pé, "Irú ọ̀rọ̀ wo lèyíí? Ó pàsẹ fún ẹ̀mí àìmọ́ náá pẹ̀lu àṣẹ ati agbára, wọ́n sí já de." Bẹ́ẹ́ ìròyìn nípa rẹ̀ sí bẹ̀rẹ̀ sí tán yí gbogbo agbègbè náá ka. 39 38 Nígbà náá ní Jésù fí sínágọ́gù sílẹ̀ ó sì wọ inú ilé Símónì. Ní bàyíi ìyá aya Símónì se áisán ibà líle, wọ́n sì sìpẹ̀ nítorí rẹ́ pẹ̀lu rẹ̀. 39 Bẹ́ẹ́ ó dúró léé lórí, ó sí bá ibà náá wí, ó sí fíí sílẹ̀. Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ó dìde, ó sì se oújẹ fún wọn. 40 Nígbà tí òrún wọ̀, àwọn ènìyàn gbé olúkúlùkù tó nsáìsàn onírúurú tọ Jésù wá. Ó sí gbé ọwọ́ lé gbogbo wọn, ó sí wò wọ́n sàn 41 ẹ̀mí àìmọ́ jáde lára ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn, wọ́n kígbe wí pé, "Ìwọ ni ọmọ Ọlọ́run!" Jésù bá àwọn ẹ̀mí àìmọ́ náá wi, kò sì jẹ́ kí wọ́n sọ̀rọ̀, nítorí wọ́n mọ̀ pé òun ni Krístì náá. 42 Nígbà t´ ilẹ̀ mọ́, ó jáde lọ sí ibi tó dáwà. Ọpọ ènìyàn nwá kiri, wọ́n sì wá sí ibi tí ó gbé wà. Wọ́n gbíyànjú ati páá mọ́ kí ó mọ́ bàà kúrò lọ́dọ̀ wọn. 43 Ṣùgbọ́n ó wí fún wọn pé, "mo gbọ́dọ̀ wàásù ìjọba Ọlọ́run fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìlú nlá míírán pẹ̀lú, nítorí ìdí tí a fi rán mi wa ibí nì yíí." 44 Bẹ́ẹ́ ní ó tẹ̀sìwájú láti wàásù nínú àwọn sínágọ́gù ní gbogbo Jùdíà.