Luku Ori Keta

1 Ní ọdun kẹ́ẹ́dógún isejọba Kesari Tìbérùsì - nigbati Póntù Pílátù jé gómìnà Jùdíà, Hẹ́rọ́dù jẹ báálẹ̀ Gálílì, arakunrin rẹ Fílípì jẹ báálẹ̀ agbègbè Ìtúríà ati Tirakonítì, Lìsánìà jẹ báálẹ̀ Abílinì, 2 ní àkókò ti Ánà ati kèáfásì jẹ olú àlúfà - ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tọ Jòhánù ọmọ Sekaráyà ninu aginjù. 3 O lọ si gbogbo agbègbè ti o yi Jódánì ká, o nwàásù ìrìbọmi ìrònúpìwàdà fún ìdàríjì ẹ̀sẹ̀ 4 Gẹ́gẹ́ bí ati kọ́ ninu iwe ọ̀rọ̀ wòlí Àìsáyà, "ohùn ẹni to nki gbe jade ninu aginjù, 'ẹ pese ònà Olùwa sílẹ̀, ẹ mú ònà rẹ̀ tọ́. 6 5 Gbogbo àfonífojì ni a o kú, gbogbo òkè gíga ati kìkì òkè ni a o rẹ̀ sílẹ̀, awọn ònà ọ̀gbún ni ao mú tọ́, awọn ibi gbọ́ngugbọ̀gu ni a o kọ sí ònà, 6 gbogbo ẹran ara yio si ri ìgbàlà Ọlọ́run. 7 Nitori naa Jòhánù sọ fún awọn ọ̀pọ̀ ènìyàn ti o jáde wá lati se ìrìbọmi nipá sẹ rẹ̀ 'ẹ̀yin ọmọ paramọ́nlẹ̀!Ta lo kílọ̀ fun yin lati sá kúrò fún ìbínú to nbọ? 8 Nítorí nàà, ẹ so èso to yẹ fun ìrònúpìwàdà, ki ẹ mọ́ sì mọ wi ninu ara yin wípé, 'Awa ni Ábúrámù ni bàbá,' nitori mo wi fun yin wipe Ọlọ́run ni ipa lati gbe awọn ọmọ dide fun Ábúrámù lati inú òkúta wọ̀n yíí. 9 Kódà bayii atifi àáké le gbòngbòn awọn igi.Nítorí nàà gbogbo igi ti ko ba so èso rere a ké lulẹ̀ asi gbe so sinu inán. 11 10 Lẹyin naa ọ̀pọ̀ ènìyàn nbi lere wipe, "ki ni ohun ti a o se lẹyìn naa ? 11 O dahun o si wi fun wọn pe, 'Bi ẹnikẹni ba ni tubi meji, ki o pin pẹlu ẹniti ko ni kankan, ẹniti o ba si ni ounje ki o se bẹ́ẹ́ gẹ́gẹ́." 12 Awọn agbowó òde pẹlu wa lati se ìrìbọmi, wọn si wi fun pe, "Olùkọ́ni, kini awa o se? 13 O wi fun wọn pe, "ẹ mọ se gbà ju iye owó tí ati pa yin lásẹ lati gbà lo." 14 Àwọn ọmọ ogun kan pẹ̀lú bi lere pé, "Bàwo nípa wa? Kíni ohun tí àwa ó se? Ó wí fún wọn pé, "Ẹ mọ́ se fi ipá gba owó lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni, ẹ mọ́ si se fẹ̀sù kan ẹnikẹ́ni láìtọ́. Ẹ jẹ́kí ówo ọ̀yà yin tẹ́yín lọ́rùn." 15 Níbáyìí bi àwọn eniyan ti n retí wíwá Krístì náá gidigidi, olúkúlúkù nró ninu ara rẹ̀ nipá Jùhánù, bóyá aajẹ́ Krístì náá . 16 Jùhánù dáhùn nípa wíwí fún gbgbo wọn, "Bi o se tèmi, emí rì yín bọmi, ṣùgbọ́n ẹnìkan nbọ ti o lágbára jù mí lọ, èmi ko si yẹ kódà lati tú ókùn sálúbàta rẹ̀. oun o baptisí yin pẹ̀lu ẹ̀mí mímọ́ ati iná. 17 Ohun èlò ìpakà rẹ̀ nbẹ lọ́wọ́ rẹ lati gbá ilẹ̀ ìpakà rẹ mọ́ tónítóní ati lati ko ọkà rẹ̀ si inú àka rẹ̀. Ṣùgbọ́n oun o jó èpò pẹ́lu iná ti a ko le dáá." 18 Pẹ̀lu ọ̀pọ̀ ìyànjú mìíràn, ni Jùhánù fi wàásù fun àwọn ènìyaǹ. 19 Nigbati a bá Hẹ́rọ́dù Tẹ́trákì wí fún fífẹ́ aya arákùnrin rẹ̀ Hẹrodíà, ati fún àwọn ibi mìíràn ti Hẹ́rọ́dù ti se, 20 ó fi eyii ku gbogbo wọn, pé ó fi Jùhánù há sínú túbú. 21 Ní bàyíí o si se, nigbati a tẹ gbogbo àwọn ènìyàn bọmi, a tẹ Jésù pẹ̀lú bọmi, nígbàtí o si ngbàdúrà, àwọn ọ̀run ṣí, 22 ẹ̀mí mímọ́ si sọ̀kalẹ̀ ní ìrí ara bí àdàbà sára rẹ̀. Ohùn kán sí tòrun wa, "Ìwọ ni ọmọ mi tí mo fẹ́. Mo yọ́nú sí ọ. 24 23 Nigbati Jésù bẹ̀ẹ̀rẹ ìhìnrere rẹ, ó jẹ́ bi ọmọ ọgbọ̀n ọdún. Ó jẹ́ ọmọ (gẹgẹ bi a se ròó) Jósẹ́fù ọmọ Hílì, 24 ọmọ Mátátì, ọmọ Léfì, ọmọ Mélíkì, ọmọ Jánáì, ọmọ Jósẹ́fù. 25 Jósẹ́fù si jẹ́ ọmọ Màtátíásì, ọmọ Ámósì, ọmọ Náhúmù, ọmọ Ésílì, ọmọ Nágáì, 26 Máátì, ọmọ Màtátíásì, ọmọ Sémíì, ọmọ Jósékì, ọmọ Jódà 27 Jódà si jẹ́ ọmọ Jòánánì, ọmọ Rísà, ọmọ Ṣèrúbábélì, ọmọ Sálátiẹ́lì, ọmọ Nírì, 28 ọmọ Mélíkì, ọmọ Áádì, ọmọ Kósámì, ọmọ Elimádámì, ọmọ Érì 29 ọmọ Jòsúà, ọmọ Eliásárì, ọmọ Jórímì, ọmọ Mátátì, ọmọ Léfì. 30 Léfì si jẹ́ ọmọ Símónì, ọmọ Júdà, ọmọ Jósẹ́fù, ọmọ Jónámì, Élíákímù, 31 ọmọ Mélíà, ọmọ Mínánì, ọmọ Mátátá, ọmọ Nátánì, ọmọ Dáfídì 32 ọmọ Jésè, ọmọ Óbédì, ọmọ Bóásì, Sálmónì, ọmọ Náshónì. 33 Náshónì si jẹ ọmọ Amínádábù, ọmọ Ádmínì, ọmọ Árínì, ọmọ Hésírónì, ọmọ Pérésì, ọmọ Júdà, 34 ọmọ Jákọ́bù, ọmọ Ísáákì, ọmọ Ábráhámù, ọmọ Tẹ́rà, ọmọ Náhórì, 35 ọmọ Sérúgù, ọmọ Ríhù, ọmọ Pẹ́lẹ́gì, ọmọ Íbárì, ọmọ Ṣílà. 38 37 36 Ṣílà si jẹ́ ọmọ Kénánì, ọmọ Áfásádì, ọmọ Sémù, ọmọ Nóà ọmọ Lámékì, 37 ọmọ Mètúsẹlà, ọmọ Énókù, ọmọ Járédì, ọmọ Màhálálélì, ọmọ Kénánì, 38 ọmọ Énósì, ọmọ Sẹ́tì, ọmọ Ádámù, ọmọ Ọlórun.