Orí Kejì

1 Ó sìṣe ní ọjọ́ wọnnì, Késárì Àùgústù rán àṣẹ jáde wípé kí á ka gbogbo ènìyàn tì ó ń gbé nínú ayé. 2 Èyí ni ìkànìyàn àkọ́kọ́ tí a ṣe nígbà tí Kíúréníù jẹ́ gómínà ní Síríà. 3 Nítorínà gbogbo wọn lọ sí ìlú rẹ̀ láti fi orúkọ sílẹ̀ fún ìkànìyàn. 4 Jósẹ́fù náà gòkè lọ láti Gálílì, láti ìlu Násárẹ́tì, sí Jùdíà, sí ìlu Dáfídì tí ṣe Bẹ́tílẹ́ẹ́mù, nítorí ọmọ ilé àti ìdílé Dáfídì ní. 5 Ó lọ síbẹ̀ láti forúkọ sílẹ̀ pẹ̀lu Màríà, àfẹ́sọ́nà rẹ̀ tó sì tí lóyún. 6 Ó sìṣe nígbà tí wọ́n wà níbẹ̀, àkókò tó fún Màríà láti bí ọmọ rẹ̀. 7 Ó bí ọmọkùnrin, àkóbí ọmọ rẹ̀, ó sì we ní aṣọ ọ̀gbọ̀, ó sì tẹ́ẹ sí ibùjẹ́ ẹran, nítorí kò sí àyè fún wọn ní ilé-èrò. 8 Àwọn Olùsọ́-àgùtàn wà ní agbègbè náà tí wọ́n ń gbé lóri pápá, tí wọ́n sì ń ṣọ́ agbo àgùtàn wọn lóru. 9 Áńgẹ́lì Olúwa sí fara hàn wọ́n, ògo Olúwa sì tàn yí wọn ká, ẹ̀rù ńlá sì bà wọ́n. 10 Nígbànáà ní Áńgẹ́lì sọ fún wọn pé, "Ẹ máa bẹ̀rù, nítorí mo mú ìròyìn ayọ̀ tọ̀ yín wá tí yóò fi ayọ̀ ńlá wá fún gbogbo ènìyàn. 11 Lónì a bí Ólùgbàlà fún yín ní ìlú Dáfídì. Òun ní Krístì Olúwa! 12 Èyi ní yóò jẹ́ àmì tí a o fi fún yín: Ẹ̀yin ó rí ọmọ ọwọ́ tí a wé ní aṣọ ọ̀gbọ̀ tí ó dùbúlẹ̀ ní ibùjẹ́ ẹran. 13 Lójijì àwọn ogun ọ̀run ńlá parapọ̀ pẹ̀lu áńgẹ́lì, wọ́n ń yin Ọlọ́run wọ́n sì ń wípé, 14 "Ògo ní fún Ọlọ́run lókè ọ̀run, àti kí àlàáfíà wà lóri ilẹ̀ ayé láàrin àwọn ènìyàn tí inú rẹ̀ dùn sí." 15 Ó sì ṣe wípé nígbà tí àwọn áńgẹ́lì ti kúrò lọ́dọ̀ wọn lọ sí ọ̀run, àwọn olùsọ́-àgùtàn sọ fún ara wọn wípé, "Ẹ jẹ́ ká lọ nísinsìnyí sí Bẹ́tílẹ́ẹ́mù, láti rí ńǹkan yìí tó ti ṣẹlẹ̀, tí Olúwa tí jẹ́ kí á mọ̀." 16 Wọ́n sáré lọ síbẹ̀, wọ́n sì rí Màríà àti Jósẹ́fù, pẹ̀lú ọmọ ọwọ tí ó dùbúlẹ̀ ní ibùjẹ́ ẹran. 17 Lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n ti ríi, wọ́n sọ ohun tí a ti fi yé wọn nípa ọmọ yìí. 18 Ẹnú ya gbogbo àwọn tí ó gbọ́ ohun tí àwọn olùsọ́-àgùtàn sọ. 19 Ṣùgbọ́n Màríà ń ṣe àsàrò nínú ọkàn rẹ̀ fún gbogbo àwọn ńǹkan tí ó ti gbọ́. 20 Àwọn olùsọ́-àgùtàn padà, wọ́n ń fi ògo àti ìyìn fún Ọlọ́run fún ohun gbogbo tí wọ́n ti gbọ́ tí wọ́n sì ti rí, gẹ́gẹ́ bíi a ti fi tó wọn létí. 21 Nígbà tí ó di òpin ọjọ́ kẹjọ, lẹ́yìn tí a ti kọọ́ nílà tàn-án, a sọ́ ní Jésù, orúkọ tí áńgẹ́lì ti fún kí á tó lóyún rẹ̀. 22 Nígbà tí iye ọjọ́ ìwẹ̀nùmọ́ wọn ti kọjá gẹ́gẹ́ bi òfin Mósè, Màríà àti Jósẹ́fù gbé e wá sí ìnu tẹ́mpílì ní Jerúsálẹ́mù láti fi fún Olúwa. 23 Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ́ nínú òfin Olúwa, "Gbogbo àkọ́bí ọmọkùnrin ní a ó yà sọ́tọ̀ fún Olúwa." 24 Nítorínà wọ́n rúbọ gẹ́gẹ́ bí àlàkalẹ̀ òfin Olúwa, "àdàbà méjì tàbí ọmọ ẹyẹlé méjì." 25 Kíyèsi, ọkùnrin kan wà ní Jerúsálẹ́mù, tí orúkọ rẹ̀ jẹ́ Símónì, olódodo àti olùfọkànsìn ni. Ó ń retí ìtùnú Ísrẹ́lì, ẹ̀mí mímọ́ sì ń bẹ lóri rẹ̀. 26 A ti fi hàn nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ wípé òun kì yóò rí ikú títí tí òun yóò fi rí Krístì Olúwa. 27 Pẹ̀lú ìdarí ẹ̀mí mímọ́, Símónì wá sínu tẹ́mpílì. Nígbà tí àwọn òbí rẹ̀ gbé Jésù ní ọmọ ọwọ́ náà tọ̀ ọ́ wa, láti ṣe gẹ́gẹ́ bíi àlàkalẹ̀ òfin, 28 Ó gbée lọ́wọ́, Ó sì ń yin Ọlọ́run, Ó wípé 29 Nísinsìnyí, jẹ́ kí ìráńsè rẹ máa lọ ní àlááfíà, Olúwa, gẹ́gẹ́ bíi ọ̀rọ̀ rẹ. 30 Nítorí ojú mí ti rí ìgbàlà rẹ, 31 ìwọ tí pèsè sílẹ̀ níwájúu gbogbo ènìyàn: 32 Ìmọ́lẹ̀ fún ìfihàn sí àwọn Kèfèrí àti ògo fún Ísrẹ́lì ènìyàn rẹ. 33 Ẹnú ya Bàbá àti ìyá ọmọ nípa àwọn nǹkan tí a sọ nípa rẹ̀. 34 Símónì bùkún fún wọ́n, Ó sì sọ fún Màríà ìya rẹ̀ pé, "Kíyèsi, a ti yan ọmọ yìí fún ìsubú àti ìgbé dìde ọ̀pọ̀lopọ̀ ènìyàn ní Ísrẹ́lì àti fún àmì tí a kọ̀- 35 àti ídà tí yóò gún ọkàn rẹ- kí á lè fi èrò inú ọkàn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn hàn. 36 Wòlíì obìnrin kan tí a ń pe orúkọ rẹ̀ ní Ánà wà níbẹ̀. Òun ni ọmọ fánúẹ́lì láti ẹ̀ya Ásà. Ó ti darúgbó . Ó ti gbé pẹ̀lu ọkọ rẹ̀ fún ọdún méje lẹ́yìn tí a ti gba ìbálé rẹ̀, 37 Òun sì jẹ́ opó fún ọdún mẹ́rindínlọgọ́rin. Kò fi ìgbà kan fi témpílì sílẹ̀, ò ń jọ́sìn pẹ̀lu àwẹ̀ àti àdúrà, ní ọ̀sán àti ní óru. 38 Ní wákàtí náà ní Ó sún mọ́ wọn Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ní fi ọpẹ́ fún Ọlọ́run Ó sì sọ̀rọ̀ nípa ti ọmọ náà fún gbogbo ènìyàn tó ń retí ìràpadà Jerúsálẹ́mù. 39 lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n ti parí ohun gbogbo tí òfin Olúwa là kalẹ̀ fún wọon láti ṣe, wọ́n padà lọ sí Gálílì, sí ìlú wọn, tí ṣe Násárẹ́tì. 40 Ọmọ náà sì ń dàgbà Ó sì di alágbára, Ó ń dàgbà nínú ọgbọ́n, àti ore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run sì wà lóri rẹ̀. 41 Àwọn òbí rẹ̀ a máa lọ lọ́dọdún sí Jerúsálẹ́mù fún àsè ìrékọjá. 42 Nígbà tí Ó pé ọmọ ọdún méjìlá, wọ́n lọ gẹ́gẹ́ bi ìse wọn sí ibi àsè ní àkókò náà. 43 Lẹ́yìn àkókò àsè wọ́n ń padà lọ sí ilé. Ṣùgbọ́n Jésù dúró ní Jerúsálẹ́mù àwọn òbí rẹ̀ kò sì mọ̀ si. 44 Wọ́n lérò wípé Ó wà láwùjọ àwọn tí wọ́n jọ ń rin ìrìn àjò, nítorína wọ́n rìn ìriǹ àjò ọjọ́ kan. Lẹ́yìn ìgbàna ní wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ní wa làárin àwọn ará àti ọ̀rẹ́ wọn. 45 Nígbà tí wọ́n kò ríi, wọ́n pádà lọ sí Jerúsálẹ́mù, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ní wáa ní bẹ̀. 46 Ó sìṣe lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́ta, wọ́n ríi nínú témpílì, Ó jókoo láàrin àwọn olùkọ́, Ó ń tẹ́tí sí wọn Ó sí ń bérè ìbéèrè. 47 Ẹnu ya gbogbo àwọn tí Ó ń gbọ́ nípa òye rẹ̀ àti ìdáhùn rẹ̀. 48 Nígbà tí wọ́n ríi, ẹnu yà wọ́n. Ìyá rẹ̀ wí fún pé, "Ọmọ, kílódé tí Ó ṣewá báyìí? Tẹ́tí, bàbá rẹ àti èmi tí ń wá Ọ gídígídí." 49 Ó wí fún wọ́n pé, kílódé tí ẹ̀yin fi ń wá mí? Ṣé ẹ̀yin kò mọ̀ wípé mó gbọdọ̀ wà nínú ilé Bàbá mí ni? 50 Ṣùgbọ́n ohun tí Ó sọ kò yé wọn. 51 Nígbànáà ni Ó padà lọ sí ilé pẹ̀lú wọn sí Násárẹ́tì Ó sí gbọ́raǹ sí wọn lẹ́nu. Ìyá rẹ̀ pa gbogbo nǹkan wọ̀nyí mọ́ lọ́kàn rẹ̀. 52 Ṣùgbọ́n Jésù tẹ̀síwáju láti máa dàgbà nínú ọgbọ́n àti ara, Ó sí pọ̀ si nínú ojú rere pẹ̀lú Ọlọ́run àti ènìyàn.