1 Ní báyìí májẹ̀mú àkọ́kọ́ gan ni ìlàna fún ìsìn àti àgọ́ ti ayé yìí. 2 Nítorí àgọ́ jẹ́ pípésè sílẹ̀. Yàrá àkọ́kọ́, níbi tí ọ̀pa fìtílà wà, tábílì àti àkàrà iwájú Olúwa, ni a pè ni ibi-mímọ 3 Lẹ́yìn aṣọ ìkéle kejì ni yàrá miran, tí a pè ni ibi-mímọ jùlọ. 4 Ó ní pẹpẹ wúra fún tùràri. Ó tún ní àpótí májẹ̀mú, èyí tí a fi wúrà yíiká. Nínú rẹ̀ ni àwo wúrà tí a kó mánà sìí, ọ̀pá Árónì tí o rúwé, àti tábúlẹ́tì ti májẹẹ̀mú. 5 Lókè àpótí majẹ̀mú ni, Kérúbù ológo ti ṣíji bo ìdérí kòkò ètùtù, èyí tí a kò le sọ̀rọ̀ lóri rẹ̀ nísínsìn yii lẹ́kúnrẹ́rẹ́. 6 Lẹ́yìn ti àwọn nǹkan wọ̀n yìí ti di pípèsè sílẹ, àwọn àlúfà má n wọ yàrá tí o wà ni òde àgọ́ láti ṣiṣẹ́ àwọn ìrúbọ wọn. 7 Ṣùgbọ́n olórí àlúfá nìkan ni a wọ yàrá kejì, lẹ́ẹ́kan lọ́dún, pẹ̀lu ẹ̀jẹ̀ fun ètùtù ẹ̀ṣẹ̀ àìmọ́mọ̀ dá tòun àti àwọn ènìyàn. 8 Ẹ̀mí-mímọ́ fi hà pe níwọn ìgbà tí àgọ́ àkọ́kọ́ bá sí ń dúró ni ojú ọ̀ná sí ibi mímọ́ jùlọ k tíì farahàn. 9 Èyí jẹ́ àkàwé fún àkókó ìsinsìn yí. Àti ẹ̀bùn àti ẹbọ tí ó ń di rírú nísìnsinyi kò tó láti se ẹ̀rí ọkàn olùsìn ni àsepé. 10 Ohun to kàn wọ́n ni ọ̀rọ́ oúnjẹ àti mímu ati onírúurù fífọ nù. Èyí ni ìlànà tó wà fún ara títi tí àkóko ìlàna titun fi dé. 11 Krístì wá gẹ́gẹ́ bi olórí àlúfà tí ó jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ohun kan dáradára tí ó ti wá. O kọjá láàrin àgọ́ ti o tobi ti o si pe jù tí a kòṣe láti ọwọ ènìyàn, èyí ti kìí ṣe ti ayé yìí. 12 Kìí ṣe nípa ẹ̀jẹ̀ àwọn ewúré àti ti àwọn ọmọ màálu, ṣùgbọ́n nípa ẹ̀jẹ̀ òun tìkálára rẹ̀ ni ó wọ ibi mímọ jùlọ lẹ́ẹ̀kan náà àti pe ó se ìdájú ìgbàlà wa ti ayérayé. 13 Nítorí tí ẹ̀jẹ̀ àwọn ewúrẹ́ àti ti àwọn màálù àti wíwọ́n eérú ọ̀dọ́ màálù sára àwọn tí o ti di aláìmọ le sọ wọ́n di ẹni ọ̀tọ̀ sí Ọlọ́run fún ìwẹ̀nùmọ́ ara 14 mélòómélòó ni ti ẹ̀jẹ̀ ti Krístì, ẹni tí ó tipaṣẹ Ẹ̀mí ayérayé rú ara rẹ̀ ní ẹbọ àìlábàwọ́n sí Ọlọ́run, tí ó si fọ ẹ̀rí ọkàn wa mọ́ kúro nínú òkú iṣẹ́ láti sin Ọlọ́run alàye? 15 Fún, ìdi eèyi, Òun ni olùlàjà ti májẹ̀mú titun. Èyí rí bẹ̀ kí, níwọ̀n ìgbà tí ikú kan ti wáye láti dá àwọn to wa lábẹ́ májẹ̀mú àkọ́kọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Àwọn tí a pè yíó gba ìléri ogún ayérayé. 16 Nítorí ni ibi tí ìwé ogún bá wà, àrídájú ikú ẹni tó ṣeé gbọdọ fìdímúlẹ̀. 17 Nítorí ìwé ogun lágbára nígbà tí iku ẹni to seé bá ṣẹlẹ̀, nítorí kò lágbára nígbà tí ẹni náà ṣì wà láàyè 18 Kìí se pé májẹ̀mú àkọ́kọ́ náà wa láì lo ẹ̀jẹ̀. 19 Nítorí nígbá tí Mósè ti fún àwọn ènìyàn ní gbogbo àṣẹ tó wà nínú òfin, ó mú ẹ̀jẹ̀ àwọn ọmọ màálù àti ti ewúrẹ́, pẹ̀lu omi, òwú pupa, àti híssobù, àti pé ó fi wọ́n awọ kíka pẹ̀lú àti àwọn ènìyàn náà. 20 Nígbà náà ló wípé, "Èyí ni ẹ̀jẹ̀ májẹ̀mú tí Ọlọ́run pàsẹ fún yín. 21 Ní ọ̀nà kan náà, ó fi ẹ̀jẹ̀ wọ́n àgó àti gbogbo ohun tí ó wà fun èlò iṣẹ́. 22 gẹ́gẹ́ bíi òfin, gbogbo ohunkan lo fẹ́rẹ́ wẹ̀ pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀. Láì sí ìtàjẹ̀ sílẹ̀ kò sí ìdáríjì. 23 Nítorí náà, ó se pàtàki pé àwọn ẹ̀dà àwọn ohun ti ọ̀run jẹ́ wíwẹ̀mọ pẹ̀lú àwọn ẹbọ àwọn ẹranko wọ̀n yí. Síbẹ̀síbẹ̀, àwọn ohun kan tọ̀run ní láti jẹ́ ìwẹ̀mọ́ pẹ̀lú àwọn ẹbọ ti o túnbọ̀ sunwọ̀n. 24 nítorí Krístì ko wọ inu ibi mímọ́-jùlọ tí a fọwọ́ kọ́, èyí tí ṣe ẹ̀dà èyí to jẹ òtítọ nìkan. Dípò bẹ̀, ó wọ ọ̀run lọ fún rarẹ̀, láti fara hàn níwájú ìwàláàyè Ọlọ́run fún wa. 25 Kò lọ síbẹ̀ láti lọ fara rẹ̀ rúbọ láìmọye ìgbà, gẹ́gẹ́ bí olóri àlúfà ṣe ma ń ṣe, tí ó ma ń wọ ibi mímọ́ jùlọ lọ́dọọdún pẹ̀lu ẹ̀jẹ̀ miràn. 26 Tí ó bá jẹ pe o rí bẹ, ǹjẹ́ yíó ti jìyà lọ́pọ̀lọ́pọ̀ ìgbà láti ìbẹ̀rẹ̀ ayé. Ṣùgbọ́n nísìnsìnyí O fara han ní bèbè òpin ayé láti ṣe ìyẹra fún ẹ̀ṣẹ̀ nípa ìrúbọ ara rẹ̀. 27 Gẹ́gẹ́ bí ènìyàn ti yàn láti kú lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo, àti lẹ́yìn èyí ni ìdájọ́, 28 bákan náà, Krístì di ìrúbọ láti kó ẹ̀ṣẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀ lọ. Àti pé yí O tún padàwá lẹ́ẹ̀kan síi, kìí se láti mú ẹ̀sẹ̀, sùgbọ́n fún ìgbàlà àwọ́n tí ó ń dúró dè é pẹ̀lú ìfarabàlẹ̀