1 Nítorí òfin náà kàn jẹ́ àfihàn àwọn ohun rere ti ń bọ̀wá ni, kìí sì ṣe awọn ohun rere naa tìkárá won. Àwọn tí ń tọ Ọlọ́run wá kò le di pípé nípa ìrúbọ kanna tí awọn àlùfáà ńse nígbà dé ìgbà. 2 Bíbẹ̀kọ́ ǹjẹ́ àwọn ìrúbọ náà kì yóò a ti dáwọ́dúró bí?. Nítorínà, ìbájéwípé àwọn ènìyàn náà ti rí ìwẹ̀nùmọ́ pátápátá, wọn yóò tí mọ̀ wípé àwọn kò jẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ mọ́. 3 Ṣùgbọ́n àwọn ìrúbọ yìí a máà mú ìrántí ẹ̀ṣẹ̀ wá nígbà dé ìgbà. 4 Nítórípé kòṣéése fún ẹ̀jẹ̀ màálù àti ti ewúrẹ́ láti mú ẹ̀ṣẹ̀ kúrò. 5 Nígbàtí Krístì wá sínu ayé, Ó wípé, "kìíṣe ẹbọ tàbí ọrẹ ni Ìwọ ńfẹ́. Bíkòṣé ara tí ìwọ́ ti pèsè sílẹ̀ fún Mí. 6 Ìwọ kò ní inú dídùn sí ẹbọ-ọrẹ sísun tàbí ìrúbọ fún ẹ̀ṣẹ̀. 7 Nígbànáà ni èmi wípé, 'Wòó, èmi nìyí gẹ́gẹ́ bí ati kọ nípaà mi nínú ìwé òfin lati ṣe ìfẹ́ rẹ́". 8 Lákọ̀ọ́kọ́ Ó wípé, "kìí ṣe ẹbọ, tàbí ọrẹ, tàbì odidi ẹbọ-ọrẹ sísun, tàbí ìrúbọ fún ẹ̀ṣẹ̀ ni ìwọ ń fẹ́. ìwọ kò ní inú-dídùn sí wọn. Èyí ni àwọn ẹbọ tí a rú gẹ́gẹ́ bíì òfin. 9 Ó si wí pé, "Wòó, èmí wà níbí láti ṣe ìfẹ́ Rẹ. "Ó mú ìlànà àkọ́kọ́ kúrò láti fi ìdí ìlànà ìkejì múlè. 10 Nípasẹ̀ ìlànà náà, a ti sọ wá di mímọ́ nípasẹ̀ ara Jésù Krístì tí a fi ṣe ìrúbọ fún gbogbo ènìyàn lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo. 11 Lápákan, gbogbo àlùfáà ń dúró ní ọjọ́ dé ọjọ́ latí sin Ọlọ́run. Ó ń ṣe ìrúbọ kanna lójojúmọ́, bótilẹ̀jẹ́wípé wọn kò le mú ẹ̀ṣẹ̀ kúrò. 12 Lápákejì, Krístì rúbọ kan ṣoṣo fún ẹ̀ṣẹ̀ gbogbo ènìyàn títí laílaí, Ó jòkó sí ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run. 13 Ó ńdúró títí àwọn ọ̀ta Rẹ̀ yóò fi di àpótí fún ẹsẹ̀ Rẹ̀. 14 Nítorí nípa ìrúbọ kan, Ó ti ṣe àṣepé àwọn tí a ti sọ di mímọ́. 15 Ẹ̀mí mímọ́ ń jẹ́ẹ̀rí fún wa pẹ̀lú. Nítorí ó kọ́kọ́ wípé, 16 Èyí ni májẹ̀mú tí Èmi yóò bá wọn dá lẹ́yìn àwọn ọjọ́ nà, ni Olúwa wí. Èmi yóò fi àwọn òfin mi sí ọkàn wọn, èmi yóò sì kọ wọ́n si àya wọn. 17 Èmi ki yóò rántí ẹ̀ṣẹ̀ àti àiṣedédé wọn mọ́." 18 Nísinsìyí, níbití ìdáríjì bá wà fún àwọn ǹkan wọ̀nyí, kò sí ìrúbo fún ẹ̀ṣẹ̀ mọ́. 19 Nítorínà, ẹ̀yin ará, àwá ní ìgboyà láti wọ ibi mímọ́ jùlọ nípa ẹ̀jẹ̀ Jésù. 20 Èyí ni ọ̀nà titun àti ọ̀nà ìyè tí Òún ti ṣí sílẹ̀ fún wa nípasẹ̀ aṣọ ìkèlé tííṣe nípasẹ̀ ẹran-ara Rẹ̀. 21 Nítorí àwá ní olórí àlùfáà ńlá kan lórí ilé Ọlọ́run, 22 Ẹ jẹ́ kí á wá pẹ̀lú ọkàn òtítọ́ nínú ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìdánilójú ìgbàgbọ́, kí a wẹ ọkàn wa mọ́ kúrò lọ́wọ ẹ̀rí-ọkàn búburú kí a sì fọ ara wa pẹ̀lú omi mímọ́. 23 Ẹ jẹ́ kí á dìrọ̀mọ́ ìjẹ́wọ́ ìgboyà-ìrètí wa, láì ṣiyèméjì, Nítorí Ọlọ́run tí ó ti ṣe ìlérí jẹ́ olótìtọ́. 24 Ẹ jẹ́ kí á mọ bí a ó ṣe máa rú ara wa sókè sí ìfẹ́ àti àwọn iṣẹ́ rere. 25 Ẹ má ṣe dẹ́kun àti jọ máa péjọpọ̀, gẹ́gẹ́ bíi àwọn kan ti ṣe. Dípò bẹ́ẹ̀ ẹ máa gba ara yín níyànjú síi, àti síwájú si, níwọ̀n bí ẹ̀yin bá ti ń rí tí ọjọ́ ń súnmọ́ síi. 26 Nítorí tí àwa bá ń mọ̀ọ́mọ̀ tẹ̀síwájú nínú ẹ̀ṣẹ̀ lẹ́yìn ti a tí gba ìmọ̀ òtítọ́, kò sí ìrúbọ fún ẹ̀ṣẹ̀ mọ́. 27 Dípò bẹ́ẹ̀, ìbẹ̀rù ìrètí ìdájọ́ kan ni ó wà àti iná ìléru tí yóò run àwọn ọ̀tá Ọlọ́run. 28 Ẹnikẹ́ni tí ó bá ti kọ òfin Mósè sílẹ̀ yóò kú láì sí àánú nípa ẹ̀rí láti ẹnu ajẹ́ẹ̀rí méjì tàbí mẹ́ta. 29 Ìjìyà náà yóò a ti le tó fún ẹni tí o ti kọ Ọmo Ọlọ́run sílẹ̀, tí ó ṣe ẹ̀jẹ̀ májẹ̀mú náà bíi ẹni pé kìí ṣe mímọ́ - ẹ̀jẹ̀ tí a fi ṣe ìsọdimímọ́ rẹ̀ - tí ó si kẹ́gàn Ẹ̀mí ore-ọ̀fẹ́ ? 30 Nítorí àwa mọ ẹni náà tí ó wípé, "Tèmi ni ẹ̀san; Èmi yóò sán padà." Àti wípé "Olúwa yóò se ìdájọ́ àwọn ènìyàn rẹ̀". 31 Ó jẹ́ ohun ẹ̀rù láti bọ́ sínu ìdájọ́ Olọ́run alàyè. 32 Ṣùgbọ́n ẹ rántí àwọn ọjọ́ àtẹ̀yìnwá, lẹ́yìn tí a ti là yín lòye, bí ẹ̀yin ti ṣe farada ìlàkàkà ńlá nínu ìjìyà. 33 Àwọn ènìyàn fi yín ṣẹ̀sín ní gbangba nípa ìkẹ́gàn àti inúnibíni, ẹ̀yin sí ń ṣe alábàápín pẹ̀lú àwọn tí ń la irú ìjìyà béè kọjá. 34 Nítorí ẹ̀yin fi àánú hàn sí àwọn tí ó wà ní ẹ̀wọ̀n, pẹ̀lú ayọ̀ ni ẹ̀yin sì fi jọ̀wọ́ àwọn ohun-ìní yín sílẹ̀. Ẹ̀yin mọ̀ wípé ẹ̀yin tìkarayín ní ohun-ìní tí ó dára jù tí ó sì jẹ́ aìledíbàjẹ́. 35 Ẹ má ṣe sọ ìgboyà yín nù, tí ó ní èrè ńlá. 36 Nítorí ẹ̀yin nílò sùúrù, kí ẹ̀yin kí ó le gba ohun tí Ọlọ́run ti ṣe ìlérí, lẹ́yìn tí ẹ̀yin bá ti ṣe ìfẹ́ rẹ̀. 37 Nítorí ní àìpẹ́, ẹnití ń bọ̀ wà yóò dé nítòótọ́, kì yóò sì pẹ́. 38 Olódodo mi yóó ma gbé nípa ìgbàgbọ́. Tí o bá yípadà emi ki yo ní inú dídùn síì. 39 Ṣùgbọ́n àwa kò sí lára àwọn tí ó yípadà si ìparun. Dípò bẹ́ẹ̀, àwá wà lára àwọn tí o ní ìgbàgbọ́ fún pípa ọkàn wa mọ́.