Orí Kọkànlá

1 Ǹ jẹ́ ìgbàgbọ́ ni ìdánilójú nípa àwọn ohun tí à ń fi ìdánilójú retí. Ó jẹ́ ẹ̀rí náà nípa àwọn ìsẹ̀lẹ̀ ohun tí a kò tíì rí. 2 Nítorí ìdí èyí ni àwọn bàbá ńlá wa fi di ìtẹ́wọ́gbà nítorí ìgbàgbó wọn. 3 Nípa ìgbàgbọ́ a ní òye wípé Ọlọ́run dá ayé nípa àṣẹ Rẹ̀, nítorí nàà a kò dà ohun tí a rí láti inú àwọn ohun tí a ti fojúrí. 4 Nípa ìgbàgbọ́ ni Ábẹ́lì rú ẹbọ tí ó dára ju ti Káínì lọ fún Ọlọ́run, nípasẹ̀ èyítí a fi ṣe ìkéde rẹ̀ ní olódodo, Ọlọ́run sì sọ rere nípa rẹ̀ nítorí ọrẹ ẹbọ rẹ̀, àti nípa ìgbàgbọ́ Ábẹ́lì sì ń sọ̀rọ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ wípé ó ti kú. 5 Nípa ìgbàgbọ́ ni a gba Énọ́kù lọ sókè kí ó má bà rí ikú, "A kòsì ríi mọ́, nítorí Ọlọ́run gbàá lọ." kí ó tó di wípé a gbàá lọ, a jérìí nípa rẹ̀ pé ó wu Ọlọ́run. 6 Ǹ jẹ́ láìsí ìgbàgbọ́ a kò le wú Ú. Nítorí tí ó se pàtàkì pé ẹnikẹ́ni tí yóò wá sí ọ̀dọ Ọlọ́run gbọ́dọ̀ ní ìgbàgbọ́ pé Ó wà láàyè àti wípé Òun sì ni olùsẹ̀san fún àwọn tí ó wá A. 7 Nípa ìgbàgbọ́ ni Nóà, nígbà tí a ti fún un ní iṣẹ́ ìránṣẹ́ kan láti ọ̀run wá nípa àwọn ohun tí a kò tíì rí, pẹ̀lú ọ̀wọ̀ fún Ọlọ́run ó kan ọ̀kọ̀ ojú omi kan láti gba ará ilé rẹ̀ là. Nípa síse èyí, ó dá ayé lẹ́bi àti pé ó sì di ajogún òdòdo èyítí íse nípaṣẹ̀ ìgbàgbọ́. 8 Nípa ìgbàgbọ́ ni Ábráhámù, nígbà tí a pèé, ó gbọ́ràn ó sì jáde lọ sí ibi tí ó ní láti gbá ní ìní rẹ̀. Ó jáde lọ, láì mọ ibi tí òun ń lọ. 9 Nípa ìgbàgbọ́ ni ó fi gbé ní ilẹ̀ ìlérí gẹ́gẹ́ bí ara ìlẹ̀ òkèrè. Ó gbé nínú àwọn àgọ́ pẹ̀lú Íṣákì àti Jákọ́bù, àwọn àjùmọ̀ jogún ìlérí kan náà. 10 Nítorí tí ó ń wo ọ̀kánkán sí ìlú náà èyí tí ó ní àwọn ìpìlẹ̀, ìlú náà tí Ọlọ́run yóò jẹ́ ayàwòrán àti ọ̀mọ̀lé náà. 11 Nípa ìgbàgbọ́, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Sárà fúnrarẹ̀ yàgàn, wípé Ábráhámù gba okun láti di baba ọmọ. Eléyìí ṣẹlẹ̀ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti di ogbó, níwọ̀n ìgbàtí ó kà Ẹní tí ó se ìlérí fún un gẹ́gẹ́ bíi olódodo . 12 Nítorí náà, láti ọ̀dọ ọkùnrin kan náà yìí, ẹni tí ó tí fẹ́rẹ̀ kú tán, ni a ti bí àwọn tí wọ́n dàbí àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run nítorí tí wọ́n pọ̀ àti bí iyanrìn ní etí òkun, tí a kò le è kà iye wọn. 13 Nìpa ìgbàgbọ́ ni àwọn wọ̀nyí kú láì rí ìlérí náà gbà. Dípò bẹ́ẹ̀, lẹ́yìn tí wọn ti rí tí wọ́n sì ti kí wọn láti ọ̀nà jínjìn wá, wọ́n gbà pé àlejò àti àtìpó ní àwọn ní orí ílẹ̀ ayé. 14 Fún àwọn ẹni tí ó sọ nǹkan wọnnì jẹ́ kí ó yé ni kedere wípé àwọn n wá ilé ìbílẹ̀ kan. 15 Bí wọ́n bá ti ń ronú orílẹ̀ èdè tí wọ́n ti jáde lọ, wọn kò bá ní anfààní láti padà. 16 Ṣùgbọ́n bí ó ti rí, wọ́n ń pòǹgbẹ orílẹ̀ èdè kan tí ó dára, tí í se, ìlú ti ọ̀run kan. Nítorí náà Ọlọ́run kò tijú kí á pè Òun ní Ọlọ́run wọn, níwọ̀n ìgbàtí Ò ti pèsè ìlú kan sílẹ̀ fún wọn. 17 Nípa ìgbàgbọ́ ni Ábráhámù, nígbà tí a dán an wò, jọ̀wọ́ Ísákì. Ọmọ rẹ̀ kan ṣoṣo ni o jọ̀wọ́, ẹnití ó ti rí àwọn ìlérí náà gbà. 18 Fún Ábráhámù ni a ti sọ fún wípé, "Láti ipasẹ̀ Ísákì ni àwọn àrọ́mọdọ́mọ rẹ̀ yóò ti gba orúkọ." 19 Ábráhámù gbèrò pé Ọlọ́run ní ágbára láti jí Ísákì dìde kúrò nínú ipò àwọn òkú, tí a bá fi ojú inú wòó, láti inú wọn ni ó ti gbà á padà. 20 Àti nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ nípa àwọn ohun tí ń bọ̀ ni Ísákì bùkún fún Jákọ́bù àti Ésáù. 21 Nípa ìgbàgbọ́ ni Jákọ́bù, nígbà tí ó n kú lọ, ó súre fún ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ọmọ Jósẹ́fù. Jákọ́bù jọ́sìn, ní gbígbé orí lé ọ̀pá rẹ̀. 22 Nípa ìgbàgbọ́ ni Jósẹ́fù, nígbà tí òpin ọjọ́ rẹ̀ súnmọ́ etílé, ó sọ̀rọ̀ nípa kíkúrò àwọn ọmọ Ísrẹ́lì láti ilẹ̀ Íjíbítì àti pé ó pàṣẹ fún wọn nípa egungun ara rẹ̀. 23 Nípa ìgbàgbọ́ ni Mósè, nígbà tí a bi, a gbe pamọ́ fún osù mẹ́ta láti ipasẹ̀ àwọn òbí rẹ̀ nítorí pé wọ́n ríi ní ọmọ tí ó rẹwà. Wọn kò bẹ̀rù àsẹ ọba. 24 Nípa ìgbàgbọ́ ni Mósè, nígbà tí ó ti dàgbà, ó kọ̀ láti jẹ́ kí á máa pè òun ní ọmọ ọba 'bìnrin Fáráò. 25 Dípò bẹ́ẹ̀, ó yàn láti jìyà pẹ̀lú àwọn ènìyàn Ọlọ́run náà, ju kí ó máa jẹ àwọn ìgbádùn ẹ̀sẹ̀ tí ó wà fún ìgbà díẹ̀. 26 Ó ròó pé ìtìjú títèlé Krístì jẹ́ ọrọ̀ ńlá ju ìsúra Íjíbítì lọ. Nítorí tí ó ńfi ojú rẹ̀ ń wo èrè rẹ̀. 27 Nípa ìgbàgbọ́ ni Mósè fi Íjíbítì sílẹ̀. Kò sì bẹ̀rù ìbínú ọba, nítorí ti ó faradàá bí ẹnipé ó ń rí ẹni aìrí náà. 28 Nípa ìgbàgbọ́ ni ó pa àjọ ìrékọjá mọ́ àti fífi ẹ̀jẹ̀ wọ̀n, kí olùpa àkọ́bí run má bà fi ọwọ́ kan àwọn àkọ́bí ọmọkùnrin àwọn ọmọ Ísrẹ́lì. 29 Nìpa ìgbàgbọ́ ni wọ́n la òkun pupa kọjá bí wípé lórí ilẹ̀ gbígbẹ. Nígbà tí àwọn ara Íjíbítì gbìyànjú láti se irú èyí, omi ru bò wọ́n mọ́lẹ̀. 30 Nípa ìgbàgbọ́ ní odi Jẹ́ríkò wó lulẹ́, lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n ti yíi po fún ọjọ́ méje. 31 Nípa ìgbàgbọ́ ni Réhábù asẹ́wó kò fi kú pẹ̀lú àwọn tí wọ́n jẹ́ aláìgbọ̀ràn, nítorí tí ó ti gba àwọn amí sí ilé ní àláfíà. 32 Kínni kí èmi kí ó tún sọ? Nítorí àkókò yòó jámikulẹ̀ tí mo bá sọ nípa Gídíónì, Bárákì, Sámsónì, Jẹ́ftà, Dáfídí, Sámúẹ́lì, àti nípa àwọn wòlíì. 33 Nípa ìgbàgbọ̀ ni wọ́n ti ṣẹ́gun àwọn ìjọba, wọ́n siṣẹ́ ìdájọ́ ododo, tí wọ́n sì gba àwọn ìlérí. Wọ́n pa àwọn kìnìún lẹ́nu mọ́, 34 wọ́n pa agbára iná, wọ́n bọ́ lọ́wọ́ ikú idà, a wò wọ́n sàn nínú orísìírísìí aìsàn, wọ́n di alágbára nínú ogun, wón sì sẹ́gun àwọn ọmọ ogun àjèjì. 35 Àwọn obìnrin gba òkú wọn padá nípa àjíǹde. àwọn míràn jìyà, wọn kò gba ìtúsílẹ̀ kí wọ́n leè rí àjíǹde tí ó dára gbà. 36 A dán àwọn ẹlòmíràn wò nípa ìfi sẹlẹ́yà àti nínà, débi wípé a fi ẹwọ̀n dè wọ́n a tún sọ wọ́n sínú túbú. 37 A sọ wọ́n ní òkúta. A fi ayùn gé wọn sí méjì. A pa wọ́n pẹ̀lú idà. Wọ́n ń lọ káàkíri nínú awọ àwọn àgùtàn àti awọ àwọn ewúrẹ́. Wọ́n di aláìní, ẹni tí à ń pọ́n lójú, àti àwọn ẹnití a ń dá lóró. 38 Àwọn tí ayé kò yẹ fún. Wọn di àlárìnkiri nínú aginjù, lórí àwọn òkè, nínú àwọn ihò àpáta, àti nínú ihò ilẹ̀. 39 Bí ó tilẹ̀ jẹ́pé Ọlọ́run fọwọ́ sí àwọn enìyàn wọ̀nyí nítorí ìgbàgbọ́ wọn, wọn kò gba ìlérí náà. 40 Ọlọ́run ti ṣètò ohun tó dara fún wa, kí ó lẹ̀ jẹ́pé laisi awa, a kò ní ṣe wọ́n pé.