ORÍ ÌKEJÌLÁ

1 Nítorínà, níwọ̀n ìgbàtí a yí wa ká pẹ̀lú irú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọ̀sánmọ̀ àwọn ẹlẹ́rìí báyìí, ẹ jẹ́ kí á fi ohun tí ó wúwo gbogbo àti ẹ̀ṣẹ̀ tí ó rọrùn láti so mọ́ wa sí ẹ̀gbẹ́ kan. Ẹ jẹ́ kí á fi sùúrù sá eré ìje tí a gbé sí iwájú wa. 2 Ẹ jẹ́ kí á fi etí sí Jésù, ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ àti aláṣepé ìgbàgbọ́. Nítorí ayọ̀ tí a gbé sí iwájú rẹ̀, ó fi ara da àgbélébù, ó kẹ́gàn ìtìjú àgbélébù, ó jókò sí ọwọ́ ọ̀tún ìtẹ́ Ọlọ́run. 3 Nítorínà ẹ má a ronú nípa rẹ̀, ẹni tí ó ti fi ara da irú ìdojúkọ ara-ẹni báyìí láti ọ̀dọ̀ àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀, kí ẹ̀yin kí ó má bà rẹ̀wẹ̀sì nínú ọkàn yín kí ẹ sì pẹ̀yìndà. 4 Ẹ̀yin kò tí bá ẹ̀ṣẹ̀ wí tàbí bá ẹ̀ṣẹ̀ jà títí dé gbèdéke ìtàjẹ̀sílẹ̀; 5 ẹ̀yin sì ti gbàgbé ọ̀rọ̀ ìmúnilọ́kànle tí a fi tọ́ yín gẹ́gẹ́ bí ọmọ. "Ọmọ mi, máṣe banújẹ́ sí ìbáwí Ọlọ́run, tàbí kí o sú ọ nígbà tí Ọlọ́run bá uń fi ìyà jẹ ọ́. 6 "Nítorí gbogbo àwọn tí Ọlọ́run bá fẹ́ràn ni ó má báwí, àti wípé ó má fi ìyà jẹ gbogbo àwọn tí ó jẹ́ ọmọ rẹ̀. 7 Ẹ fi ara da ìjìyà gẹ́gẹ́ bí i ìbàwí. Ọlọ́run uń bá yín wí gẹ́gẹ́ bí baba sí ọmọ. Nítorí ọmọ wo ni ó wà tí bàbá rẹ̀ kò ní báwì? 8 Bí gbogbo ènìyàn bá ní ìbáwi ṣùgbọ́n tí ẹ̀yin bá wà ní àìní ìbàwì, ọmọ àlé ni ẹ jẹ́ ẹ kò í ṣe ọmọ. 9 Síwájú si, àwá ní baba nípa ti ara tí à uń sì bọ̀wọ̀ fún wọn gẹ́gẹ́ bí olùbáwí, mélòmélò wá ní ó yẹ kí á gbọ́ràn sí baba wa nínú ẹ̀mí kí á sì yè? 10 Ní apá kan àwọn baba wa uń bá wa wí bí ó ti tọ́ fún ọjọ díẹ̀. NÍ apá kejì, Ọlọ́run náà ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ fún dídára wa kí á bàle pín nínú ìwàmiímọ́ rẹ̀. 11 Kó sí ìbáwí tí ó dùn mọ́ wa ní ìsinsìnyì, kàkàbẹ́ẹ̀, ó jẹ́ ohun ìnira fún wa. Ṣúgbọ́n ní ìgbẹ̀yìn yíò so èso àláfíà tí òdodo fún àwọn tí ó bá gba ẹ̀kọ́ náà. 12 Nítorínà, ẹ mú ọwọ́ yín tí ó subú àti erúnkún yín tí ó rọ le. 13 Ẹ mú ọ̀nà yín tọ́, kí ohun tí ó ya arọ má bà wà ní yíyarọ síbẹ ṣùgbọ́n kí ó le gba ìmúláradá. 14 Ẹ lépa àláfíà pẹ̀lú gbogbo ènìyàn, àti pẹ̀lú ìwà mímọ́, ní à ì sí èyí kò sí ẹni tí yíò rí Olúwa. 15 Ẹ má a kíyèsára kí ẹnikẹ́ni má ba à ṣe aláìní ore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run, àti pé kí gbòuǹgbò ìkorò kankan tí ó le fa wàhálà máṣe hù jáde nínú yín, kí ọ̀pọ̀lọpọ̀ má bà ti ipaṣẹ bẹ́ẹ̀ di aláìmọ́. 16 Ẹ kíyèsára kó má ṣe sí ágbérè tábí aláìhùwàbí Ọlọ́run ní àrin yín bí i Ísáù, ẹni tí ó ti ìtorí ìṣù òkèlè oúnjẹ kan ta ogún ìbí rẹ̀ . 17 Nítorí ní ẹ́yìnọ̀rẹyìn ẹ̀yin mọ̀ wípé nígbàtí ó fẹ́ láti jogún ìbùnkún náà padà, a kọ̀ ọ́, nítorípé kò rí àyè fún ìrònúpíwàdà bí ó tilẹ̀ jẹ́ wípé ó fi omijé wa. 18 Nítorí ẹ̀yin kò tí wá sí òkè tí a le fi ọwọ́ kàn, òkè tí ó uń fi iná jó, tí òkùnkùn, ti ìsúdudu, àti orí-òkè ìjì. 19 Ẹ̀yin kò tí wá sí ibi ìfun-ìpè, tàbí sí ibi ohun tí ó ún sọ́rọ̀ tí àwọn olùgbọ́ rẹ̀ sí ún bẹ́bẹ̀ wípé kí ó má sọ́ ọ̀rọ̀ míràn mọ́. 20 Nítorí wọn kò le fi ara da ohun tí a pa láṣẹ fún wọn: "Kódà bí ó bá ṣe ẹranko ní ó bá fi ọwọ kan òkè náà, a ó sọ ọ́ ní òkúta pa." 21 Nítorí ohun ẹ̀rù báyí tí Mósè rí ni ó fi wípé, "Ẹ̀rù bà mi mo sì wá rírì." 22 Kàkàbẹ́ẹ̀, ẹ̀yín tí wá sí orí-òkè Síónì àti sí ìlú tí Ọlọ́run ún gbé, èyí ni Jerúsálẹ́mù ti ọ̀run, àti sí ẹgbẹ̀rún mẹ́wá àwọn ágẹ́lì tí wọ́n yọ̀. 23 Ẹ̀yín tí wá sí àwùjọ àwọn àkọ́bí, tí a ti kọ orúkọ wọn sí ọ̀run. Ẹ̀yín ti wá sí ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, olùdájọ́ ènìyàn gbogbo, àti sí ọ̀dọ̀ ẹ̀mí òdodo nì tí a ti ṣe ní àṣepé. 24 Ẹ̀yín ti wá sí ọ̀dọ̀ Jésù, alárinà májẹ̀mú titun, àti sí ìbùnwọ́n ẹ̀jẹ́ tí ó ún sọ ohun tí ó dára ju ti ẹ̀jẹ̀ Àbẹ́lì lọ. 25 Ẹ rí i dájú wípé ẹ̀yin kò kọ ẹni tí ó ún sọ̀rọ̀. Nítorí bí wọn kọ̀ bá bọ́ kúrò nígbà tí wọ́n kọ ẹni ti ó kìlọ̀ fún wọn nínú ayé, mélòmélò ni ẹ̀yin yí ò bọ̀ bí ẹ̀yin bá yípadà kúrò ní ọ̀dọ̀ ẹni tí ó ún kìlọ̀ fún yín láti ọ̀run wá. 26 Ní àkókò kan, ohùn rẹ̀ mi ayé. Ṣùgbọ́n níìsínsìnyí ó ti ṣe ìlérí ó sì wípé, "Ní ìgbà kan sí i, Èmi kì yóò mi ayé nìkan, ṣùgbọ́n àti àwọn ọ̀run pẹ̀lú." 27 "Ní ẹ̀kan sí i", àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀n yí túmọ̀sí yíyọ àwọn ohun tí ó ṣe é mì, èyí ni, àwọn ohun tí a ti dáá, kí àwọn ohun tí kò ṣé mì bà le wà títí. 28 Nítorínà, ní gbígba ìjọba tí a kò le mì, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ẹ jẹ́ kí á dúpẹ́ kí á sì sin Ọlọ́run pẹ̀lu ẹ̀rù. 29 Nítorí iná ajónirun ni Ọlọ́run wa.