ORÍ ÌKẸTÀLÁ

1 Ẹ jẹ́ kí ìfẹ́ ará má a tẹ̀síwájú. 2 Ẹ má ṣe gbàgbé àlejò ṣíṣe fún àwọn àjèjì. Nítorí láti ipaṣẹ eléyí, àwọn kan ti ṣe áńgẹ́lì ní àlejò ní àìmọ̀. 3 Ẹ rántí àwọn tí ó wà ní ẹ̀wọ̀n bí ẹni wípé a dè yín pọ̀ mọ́ wọn. Ẹ rántí àwọn tí à ún fìyà jẹ gẹ́gẹ́ bí wípé ẹ̀yin náà wà pẹ̀lu wọn nínú ara. 4 Ẹ jẹ́ kí gbogbo ènìyàn bu ọlá fún ìgbéyàwó. Ẹ jẹ́ kí àketè ìgbéyàwó wà ní mímọ̀, nítorí Ọlọ́run yí ò dá àwọn panságà àti àwọn alágbérè ní ẹjọ́. 5 Ẹ jẹ́ kí ìgbe-ayé yín jẹ́ èyí tí ó ní òmìnira kúrò lọ́wọ́ ìfẹ́ owó. Ẹ ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú ohun gbogbo tí ẹ ní, nítorí Ọlọ́run fúnrarẹ̀ sọ wípé, "Èmi kì yò fi yín sílẹ̀, tàbí kọ̀ yín sílẹ̀." 6 Ẹ jẹ́ kí á ní ìtẹ́lọ́rùn kí á bàle fi ìgboyà wípé, "Ọlọ́run ni olùrànlọ́wọ́ mi; Èmi kì yíò bẹ̀rù. Kín ni ènìyàn lè ṣe fún mi?" 7 Ẹ kíyèsí àwọn aládarí yín, tí wọ́n sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fùn yín, kí ẹ sí kiyèsí ìwà wọn. Ẹ kọ́ kí ẹ ṣe àmúlò ìgbàgbọ́ wọn. 8 Jésù Kristì nì kan ni ní àná, ní òní, àti títí ayé. 9 Ẹ má ṣe jẹ́ kí á fi àwọn ẹ̀kọ́ àjèjì gbá yín lọ. Nítorí ohun tí ó dára ni kí á mú ọkàn wa le pẹ̀lu ore-ọ̀fẹ́, kì í ṣe nípa oúnjẹ tí kò le ran àwọn tí ó ún rìn nípa wọn lọ́wọ́. 10 Àwa ní pẹpẹ kan èyí tí àwọn tí wọ́n ṣiṣẹ́ ìsìn níbẹ̀ kò ní ẹ̀tọ́ láti jẹun níbẹ́. 11 ẹ̀jẹ̀ ẹranko tí a pa fún ẹ̀ṣẹ̀ ni olóri àlúfà yíò mú wá sí ibi mímọ́ jùlọ, tí a ó sì sun ẹran ara wọn ní ìta àgọ́. 12 Kí ó bà le ya àwọn ènìyàn sí mímọ́ nípa ẹ̀jẹ̀ òun tìkálára rẹ, Jésù pẹ̀lú jìyà ní ìta ẹnu ibodè ìlu nà. 13 Nítorínà ẹ jẹ́ kí á tọ̀ ọ́ lọ sí ìta ibùdò, kí á sì ru ìtìjú rẹ̀. 14 Nítorí àwa kò ní ìlú tí ó wà títí ní ìhínyí. Kàkà bẹ́ẹ̀, àwa ún wo èyí tí ó ún bọ̀. 15 Ẹ jẹ́kí á ma rúbọ ọpẹ́, ọpẹ́ ti èso ètè wa tí ó uń fi ọlá fún orúkọ rẹ̀ nígbà gbogbo, nípasẹ rẹ̀. 16 Ẹ máse gbàgbé láti má ṣe ohun rere kí ẹ sì ma ran ara yín lọ́wọ́, nítorí irú ìrúbọ yìí ni Olúwa ní inú dìdùn sí. 17 Ẹ ma gbọ́ràn sí àwọn aládarí yín lẹ́nu kí ẹ sì tẹríba fún wọn, nítorí wọ́n uń ṣe ìṣọ́ lórí ẹ̀mí yín, gẹ́gẹ́ bí ẹni tí yíò jí yìn. Ẹ gbọ́ràn kí àwọn aládarí yín le ṣe èyí pẹ̀lu ayọ̀, kì í sí ṣe pẹ̀lú ìnira, tí kò ní ànfàní kankan fún yín. 18 Ẹ ma gbàdúrà fún wa, nítorí tí àwá ní ìdánilójú wípé a ní ẹ̀rí ọkàn tí ó mọ́ àti wípé ìfẹ ọkàn wa ní láti gbe ìgbe-ayé tí ó tọ́ nínú ohun gbogbo. 19 Mó gbà yín níyànjú láti ṣe ju èyí lọ, kín bà le wá sí ọ̀dọ̀ yín ní àípẹ́. 20 Ǹjẹ́ ní ìsinsìnyí kí àláfíà Ọlọ́run, eni ti ó mú olùṣọ́-àgùtàn àgbà, Jésù Olúwa wa padà wá kúrò nínu ipò òkú nípaṣẹ májẹ̀mú ẹ̀jẹ̀ tí kò ní pẹ̀kun, 21 kí ó ṣe yín pé pẹ̀lu ohun rere gbogbo láti le ṣe ìfẹ́ rẹ̀. Kí ó lè ṣe ohun tí ó tẹ́ ẹ lọ́rùn lójú rẹ̀ nínú wa, nípaṣẹ Jésù Krístì, ẹni tí ògo wá fún títíláí. Àmín. 22 Mo gbà yín níyànjú ará ní ìsinsìnyí, kí ẹ gba ọ̀rọ̀ ìyànjú tí mo kọ ní kùkúrú sí yín mọ́ra. 23 Ẹ mọ èyí pé, a ti tú Tìmótíù arákùnrin wa sílẹ̀, eni tí a ó jọ dé ọ̀dọ̀ yín bí ó bá tètè dé. 24 Ẹ kí gbogbo àwọn aládarí yín àti gbogbo àwọn onìgbàgbọ́. Gbogbo àwọn tí ó wá láti Ítálì kí yín. 25 Ǹjẹ́ kí ore-ọ̀fẹ́ kí ó wà pẹ̀lú gbogbo yín.