1 Ní báyi kókó ohun tí à ń sọ nìyí: A ní olórí àlúfà ti ó ti jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún níbi ìtẹ́ Ọlọ́ńlálá ní àwọn ọ̀run. 2 Òun sì jẹ́ ìránsẹ́ nínú ibi mímọ́, nìnú àgọ́ òtítọ́ ti Olúwa gbékalẹ̀, tí kìí ṣe èníyàn. 3 Nítorí gbogbo àlúfà ni a yàn láti rúbọ ọrẹ àti ẹbọ. Nítorí náà ó ṣé pàtàkì láti ní ohùn kan láti fi rúbọ. 4 Nísinsìnyí tí Krístì bá wà láyé, kòni jẹ́ àlúfá rárá, níwọ̀n igbà ti àwọn kan wà tí ó ń rúbọ ọrẹ ní ìlànà ti òfin. 5 Wọ́n ń sin ẹ̀dà àti òjìji àwọn ohun ti ọ̀run nínú àgọ́. Gẹ́gẹ́ bi ìgbà ti Ọlọ́run kìlọ̀ fún Mose nígbà ti ó fẹ́ tó àkókò láti kọ́ àgọ́: Ọlọ́run wípé "Rí wípé o se ohun gbogbo gẹ́gẹ́ bi àpẹrẹ ti a fi hàn ọ́ ní orí àpáta." 6 Ṣùgbọ́n nísinsìn yìí Krístì ti gba iṣẹ́ ìránṣẹ́ tí ó sunwọ̀n, gẹ́gẹ́ bí Òun tí jẹ́ Olùlàjà ti májẹ̀mu titun, tí o dálórí ìléri tó sunwọ̀n. 7 Nítori bí májẹ̀mú àkọ́kọ́ kò bá ní àbùkù, kò ní sí iwúlò fún májẹ̀mú kejì. 8 nítorí nígbà tí Ọlọ́run ri àbùkù pẹ̀lú ènìyàn, Ó wípé, "Wòó, ọjó ń bọ - ni Olúwa wí - nígbà tí Èmi yíó se májẹ̀mú titun pẹ̀lú ilé Ísrẹ́lì àti pẹ̀lú ilé Júdà." 9 Kò ní dàbi májẹ̀mú tí mo bá àwọn baba wọn da, ní ọjọ́ tí mo mú wọn lọ́wọ́ láti mú wọn jáde kúrò ni ilẹ̀ Ègíptì. Nítorí wọn kò farabalẹ̀ láti gbọ́ràn sí májẹmú mi, mo sì ṣe aláìnáání wọn - ni Olúwa wi. 10 Èyi ni májẹ̀mú titun tí Èmi yíó se pẹ̀lu ile Ìsrẹlì lẹ́yìn àwọn ọjọ́ wọ́n ń nì.Èmi ó fi àwọn òfin mi sínú ọkàn wọn, Èmi ó sì tún kọ wọ́n sí àyà wọn. Èmi yíó jẹ́ Ọlọ́run wọn, àwọn yíó sì jẹ́ ènìyàn mi. 11 Wọn kò ní kọ́ olúkúlúkù aládùúgbo àti olúkúlúkù arákùnrin rẹ̀, wípé, 'mọ Olúwa.' Nítorí gbogbo wọn ni yíó mọ mí, látorí ẹni to kéréjù títí dé ẹni tó pọ̀jù. 12 Nítorí Èmi yíó ṣe àànú sí gbogbo ìwa ibi wọn, àti ẹ̀ṣẹ̀ wọn ni Èmi kì yíò rántí mọ́. 13 Nípa wíwípé "titun," Ó ti sọ májẹ̀mú ti àkọ́kọ́ ní di ohun àtijọ́, àti pé ohun tí ó ti di ohun àtijọ àti ìgbà kan rí yíó parẹ́ láípẹ.