Orí Keje

1 Mekiṣẹ́dèkì yii, ọba Sálẹ́mù, àlùfáà Ọlọ́run tí ó gajù, tó pàde Ábráhámù nígbà tí ó ń bọ̀ láti ibi tí o ti ṣekú pa àwọn ọba, tí ó ṣì bùkún fún un. 2 Òun ni Ábráhámù fún ní ìdámẹ́wàá ohun gbogbo. , orúkọ rẹ̀ tíí se Mekiṣẹ́dèkì túmọ̀ si "ọba olódodo"; àti pé òun ni "ọba Salẹmu", tí í ṣe "ọba àlááfíà." 3 Kòní bàbá, kòní mama, kòni ìran, láì ni ìbẹ̀rẹ̀ àti òpin ayé. Dípò bẹ́ẹ̀, ó farajọ Ọmọ Ọlọ́run, nítorí ó jẹ́ àlùfáà títí láé. 4 Ẹ wó bí ọkùnrin yìí ṣe tóbi tó ẹni tí Ábráhámù bàbá nlá fún ní ìdámẹ́wàá ohun gbogbo tí ó ti kó ni ojú ogun. 5 Lápákan, Òfin ń bèrè lọ́wọ́ ìran Léfì tí o gba ipò àlúfáà láti gba ìdámẹ́wàá lọ́wọ́ àwọn ènìyàn, èyíi nì àwọn arákùnrin wọn, bó tilẹ̀ jẹ́ pé, àwọn náà, wá láti ẹ̀yà ara Ábráhámù. 6 Sùgbọ́n lọ́nàmíràn, Mẹkiṣẹ́dẹ́kì, ẹni tí ìran rẹ̀ kò wá láti ọ̀dọ wọn, o gba ìdámẹ́wàá lọ́wọ́ Ábráhámù, ó ṣì súre fún un, ẹni tí ó ní ìlérí. 7 Kòsí ìjanpata pé ẹni kékeré bùkuń fún ẹni nínlá. 8 Lórí ọ̀rọ̀ yìí, ènìyán ẹlẹ́ran ara gba ìdámẹ́wàá, sùgbọ́n lórí ọ̀rọ tọ̀hún ẹ̀rí wá pé òún wà títí láé. 9 Àti pé, nípa ìgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀, Lefi, tí ó gba ìdámẹ́wàá, òun náà pẹ̀lú san ìdámẹ́wàá nípaṣẹ̀ Ábráhámù, 10 nítori ó wà nínú ara baba ńlá rẹ̀ nígbà tí Mẹkiṣẹ́dẹ́kì páde Ábráhámù. 11 Nísínsín yii, tí àṣepé bá ṣeéṣe nípaṣẹ́ ṣíṣe iṣẹ́ àlùfáà àwọn ọmọ Lefi (nítorí lábẹ́ rẹ́ ni àwọn ènìyàn ti gba òfin), kínní ìwúlo tí ó tún le wà fún àlùfáà míiràn láti dìde ní irúu ìṣe Mẹkiṣẹ́dẹ́kì, àti láìrò ti ìṣe ti Árónì? 12 Nítori tí ìṣe àlùfáà bá yípadà, òfin pẹ̀lú gbọdọ̀ di yíyí padà. 13 Nítorí ẹni náà tí a sọ ǹka wọ̀nyí nípa rẹ̀ jẹ́ ti ìran míran, láti ibi ti ẹnikẹ́ni kò tíì sìn lóri pẹpẹ rí. 14 Nísínsìnyí ó dájú pe láti Júdàh ni a ti bí Olúwa, ẹ̀yà ti Mósè ko sọ rárá nipa àlùfáà. 15 Ohun tí à ń sọ tún yé síi nígbà ti àlùfáà míràn bá dìde ni ìlànà ti Mẹkiṣẹ́dẹ́kì. 16 Kìíṣe lóri òfin ẹran ara ti ìran ni ó ṣe di àlùfáà, ṣùgbọ́n ó dá lóríi agbára tó wà nínú ìyè ayérayé. 17 Nítori ti ìwé-mímọ́ ń jẹ́rìí nípa Rẹ̀ pé: "àlùfáà kan ni ọ gẹ́gẹ́ bíi ti ìtẹ̀lé ti Mẹkiṣẹ́dẹ́kì" 18 Nítorí tí a ti fagilé òfin àtijọ́ nítorí pé ó jẹ́ àìlágbára ati àìwúlò, 19 nítorí òfín ko se ohunkóhun pé, àti pé ìrètí tó sunwọ̀n sì jẹ́ fífihàn, nípa èyí ni àwá se sún mọ́ Ọlọ́run. 20 Èyí kò sẹlẹ̀ láìsí ìbúra. Ní apá kan, àwọn yòókù di àlúfà láìsí ìbúra, 21 ṣùgbọn ní apá kejì, èyí i nì, Jésù, di àlúfà nípa ìbúra ẹni tí ó wípé, "Olúwa búra kò sì ní yí ọkàn Rẹ̀ padà: 'Ìwọ jẹ àlúfà títí láé."' 22 Nípa èyí pẹ̀lú Jésù ti fún wa ní ìdánilójú májẹ́mú tí ó sunwọ̀n. 23 Ní apá kan, ọ̀pọ̀ àlúfá látàri pé ikú kò gbà wọ́n láàyè láti tẹ̀síwájú ní ipò wọn. 24 lápá kejì, nítorí Jésù wà títí láé, Ó ní ipò àlúfà títí láé. 25 Nítorí nàà Ó ní agbára pẹ̀lú láti gba gbogbo àwọn tí ó bá tọ Ọlọ́run wá nípasẹ̀ Rẹ̀ pátápátá, nítorí Ó ń wà láàyè nígbà gbogbo láti ṣìpẹ̀ fún wọn. 26 Nítorí irú olórí àlúfà yí ni ó yẹ fún wa. Ó jẹ́ aláìlẹ́sẹ̀, aláìléèrí, mímọ́ tí a sì yà sọ́tọ̀ kúrò nínú ẹlẹ́sẹ̀, ó sì ti ga ju àwọn ọ̀run lọ. 27 Ko nílò, bi ìse àwọn àlúfà yóku, láti rú ẹbọ ojoojúmọ́, lákọ̀ọ́kọ́ fún ẹ̀ṣẹ̀ ara rẹ̀, àti lẹ́yìn náà fun ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ènìyàn. Ó se èyí lẹ́ẹ̀kan náà nígbà ti Ó fi ara Rẹ̀ rúbọ. 28 Nítorí òfin ma ń yan àwọn ọkùnrin tó ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àìlera ní olórí àlúfà. Ṣugbọn ọ̀rọ̀ ti ìbúra, tí ó wá lẹ́yìn òfin, yan Ọmọkùnrin kan, ẹni tí O ti di àsepé títí láé.