Orí kẹfà

1 Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí á fi ìbẹ̀rẹ̀ ẹ̀kọ́ ti Krístì sílẹ̀, kí á tẹ̀síwájú sí dídàgbà. Ẹ máṣe jẹ́ ki á tún fi ìpìlẹ̀ ìrònúpìwàdà kúrò nínú àwọn oku isẹ́ àti ti ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run lélẹ̀ mọ́, 2 tàbí ìpìlẹ̀ ẹ̀kọ́ nípa ìtẹ̀bọmi, ìgbọ́wọ́ léni lórí, àjíǹde ti àwọn òkú àti ìdájọ́ ayérayé. 3 A ó se èyí náà bí Ọlọ́run bá fààyè gbàá. 4 Nítorí kò ṣééṣe fún àwọn tí ojú wọn ti là nígbà kan rí, tí wọ́n ti tọ́ ẹ̀bùn ọ̀run wò, àwọn tó pín nínú Ẹ̀mí Mímọ, 5 àti àwọn tó tọ́wò nínu ọ̀rọ̀ rere ti Ọlọ́run àti agbára ìgbà tí ńbọ̀, 6 sùgbọ́n tí wọ́n subú - kò ṣééṣe láti tún dáwọn padà sí ìrònúpìwàdà. Nítorí pé wọ́n pa Ọmọ Ọlọ́run fúnra wọn lẹ́ẹ̀kan síi, wọ́n síì dójú tì í ní gbangba. 7 Nítorí ilẹ̀ tí ó máa n mu òjò tí ó rọ̀ sórí rẹ̀, tí ó sí mú kí irúgin ti ó wúlò fún àwọn ẹni tí ń ṣiṣẹ́ lórí rẹ̀ jáde, èyí ni ilẹ̀ ti ó gba ìbùkún láti ọ̀dọ Ọlọ́run wá. 8 Ṣùgbọ́n tí ó ba so ẹ̀gún àti eṣú, kò wúlò àti pé ó súnmọ́ ègún. nígbẹ̀yìn yio di sísun níná. 9 Ṣùgbọ́n àwa ní ìdánilójú àwọn ohun dídára nípa yín, ẹ̀yin ará olùfẹ́, àwọn ohun tó níṣe pẹ̀lú ìgbàlà, bí a tilẹ̀ ń sọ́rọ̀ báyìí. 10 Nítorí Ọlọ́run kìí ṣe aláìsòdodo. kòní gbàgbé isẹ́ yín àti ìfẹ́ ti ẹ fihàn fún orúkọ rè, nítorí ẹ sin àwọn onígbàgbọ́, ẹ sì tún ń sìn wọ́n. 11 Ó sì wùwá gidigidi pé ẹni kọ̀ọ̀kan yín yió fi iru takuntakun yìí hàn títí di òpin, kí ìrètí yín le dájú. 12 Éyí rí bẹ kí ẹ má bà di ọ̀lẹ, ṣùgbọ́n aláwòkọ́ṣe àwọn tí wọ́n ti tipaṣẹ̀ ìgbàgbọ́ àti sùúrù jogun àwọn ìléri naa. 13 Nítorí nígbà tí Ọlọ́run ṣèlérí rẹ̀ fún Ábráhámù, ó búra nípa ara rẹ̀, nítorí kò sí ẹni tí ó tóbi jùúlọ t'Ó le fi búra. 14 Ó wípé, ''Èmi yió bùkún fún ọ nítòótọ́ àti pé irú ọmọ rẹ yíó di púpọ̀'' 15 Ní ọ̀nà yìí, Ábrámù gba ìlérí náà lẹ́yìn tí ó ti fi sùúrù dúró. 16 Nítorí àwọn ènìyàn a máa búra nípa ẹni tí ó tóbi jùwọ́n lọ. Lẹ́yìn gbogbo ìjà wọn, ìbúra a máa dúró fun ìdánilójú. 17 Nígbà tí Ọlọ́run pinnu láti fi ète Rẹ̀ tí kìí yípadà han àrólé nípa ìlérí, ó fi dáalójú pẹ̀lu ìbúra. 18 Ó ṣe eyi nípa ohun méji tí kòle yípadà - nítorí kò ṣééṣe fún Ọlọ́run láti parọ́ - àwa, tí ati sá fún àbò, yíó ni ìtùnú láti di ìrèti tí ó wa níwáju wa mú sinsin. 19 A ní èyí gẹ́gẹ́ bi ìdákòrò tí ó ní ìdánilójú àti tí ó seé gbẹ́kẹ̀lé, ìrètí tí ó wọ ibi ìkọ̀kọ̀ lẹ́yin asọ ìpéle, 20 níbi tí Jésù, tí ó ti lọ síwájú wa, ti wọ inú ibi ìkọ̀kọ̀ naa dípó wa. Ó ti di olórí àlùfáà ní ìtẹ̀lé Mẹkiṣẹ́dẹ̀kì.