Orí-Karùn ún

1 Nítori fún àwọn olóri Àlúfàá, tí a yàn láàrin àwọn ènìyàn, a yàn án láti ṣójù àwọn ènìyàn nínú àwọn nǹkan ti ṣe ti Ọlọ́run, ki o le ṣe ìfifún èbùn àti ìrúbo fún ẹ̀sẹ̀. 2 Ò le fí ìwà pèlé ba àwọn alíàlóye àti àwọn tí ó yapa lo nítorí a ti fi aìlera yí òhun náá ká . 3 Nítorí èyí, ó pọn dandan ki o ṣe ìrúbọ fún ẹ̀sẹ̀ òhun tìkararé gégè bi o ti ṣe fún ẹ̀sẹ̀ àwọn ènìyàn . 4 Ọ̀lá yi kí ṣe fún ẹnikéni látì gbà fún ara ré,bíkòse pé, Ọlọ́run pèé gẹ́gẹ́ bi o ṣe pé Áarọ́nì. 5 Bákanáà, Krístì kò bu ọlá fún ara rẹ̀ láti fi ara Rẹ̀ ṣe olóri Àlúfáà. Bíkòṣe, ẹni tí ó n ba sọ̀rọ̀ wípé, ´´Ìwọ ni Ọmọ mi, lọ́ní ni mo di Bàbá rẹ̀ . 6 Bí o tí ṣe ṣo níbó míran, ``Ìwọ ni álúfà títí láíláí bí i ti ẹ̀yà ti Melkisédẹ́kì. 7 Nígbàtí Ó wà nínú ara, Krístì gbàdúrà pẹ̀lú ìsìpẹ̀ ní ohùn rara àti omijé sí Ọlọ́run, ẹnití ó le è gbàá lọ́wọ́ ikú, Ọlọ́run si gbọ́ ọ nítorí ọ̀wọ̀ àti ìsìpẹ̀ rẹ̀ 8 Bi o tilẹ̀ jẹ́ pé Ọmọ ni, Ó kọ́ ìgbọ́ràn láti inú àwọn ohun tí Ó jìyà fún. 9 A sọ Ọ́ di pípé, Fún ẹnikẹ́ni tí o gbọràn sí lènú, Àwọn tí o fa ìyè ayérayé. 10 Ọlọ́run sì ti yàn án gẹ́gẹ́ bi Olórí Àlùfáà bí i ti ẹ̀yà ti Melkisédékì. 11 A ní ohun púpọ̀ láti sọ nípa Jésù ṣùgbọ́n óṣòro láti ṣàlàyé níwọ̀n ìgbàtí etíyín lọ́ra láti gbọ́ràn. 12 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òyẹ kí ẹ ti di Olùkọ́ni nísinsìnyí, ẹ ṣì nílò kí ẹnìkan kọ yín ní àwọn ìpìlẹ̀ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. 13 Ẹ ní lò o wàrà, kì í ṣe oúnjẹ líle Nítorí ẹnití ó bá ń mu wàrà nìkan kòní ìrírí pẹ̀lu ìsòtítọ́ ọ̀rọ̀ náà , nítorípe ó sì jẹ́ ọmọdé. 14 Ṣùgbọ́n oúnjẹ líle wà fún àwọn àgbàlagbà. Àwọn wọ̀nyí ni àwọn tí wọ́n torí ìdàgbà wọn kọ òye fún ìṣeyàtọ̀ ohun tó dára àti tí kò dàra.