1 Nítorí náà, ẹjẹ́ kí á kíyèsára kí ẹnikẹ́ni nínú yín má baà kùna láti wọ inú ìsinmi Ọlọrun, ti O sèlérí fún yín. 2 Nítorí àwa náà ti gbọ́ ìròyìn ayọ̀ náà gẹ́gẹ́ àwọn náà ti gbọ́ọ. Ṣùgbọ́n, ọ̀rọ̀ tí wọ́n gbọ ko se ànfàní fún àwọn tí kò gbàgbọ. 3 Niítorí àwa tí a ti gbàgbọ́ ni yíò wọ inú ìsinmi gẹ́gẹ́ bí O ti wí pe, "Bí mo ti búra nínú ìbínú mi pé, wọn kì yíò wọ inú ìsinmi mi." Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Ó ti parí iṣẹ́ ìṣẹ̀dá láti ìpìlẹ̀ ayé. 4 Niítorí Ó ti sọ nípa ọjọ́ keje pe, "Ọlọrun sì sinmi ní ọjọ́ keje lẹ́nu iṣẹ́ Rẹ̀ gbogbo." 5 Ó tún sọọ́ lẹ́ẹ̀kan si pé, "Wọn kì yíò wọ inú ìsinmi mi láéláé." 6 Nítorí náà, nítorípe Ó ti sètò rẹ̀ pé àwọn kan yíò wọ inú ìsinmi Rẹ̀, àti pé nígbàtí ó jẹ́ pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọ Isrẹẹli tí wọ́n gbọ́ ìròyìn ayọ̀ náà kò wọ̀ọ́ nítorí àìgbọran, 7 Ọlọrun tún ti yan ọjọ́ kan tí a pè ni, "òní." Lẹ́yìn ọjọ́ pípẹ́, Ó sọ̀rọ̀ láti ẹnu Dafidi, bí Ó ti sọ tẹ́lẹ̀ pé, "Lónìí tí ẹ bá gbọ́ ohùn Rẹ̀, ẹ má sé ọkàn yín le" 8 Nítorí, bí ó ba se pé Joṣua bá ti fún wọn ní ìsinmi ni, Ọlọrun kì bá tí sọ̀rọ̀ nípa ọjọ́ míràn mọ́. 9 Nítorí náà, ìsinmi kan kù fún àwọn enìyàn Ọlọrun. 10 Nítorí ẹni tí ó ba wọ ibi ìsinmi Ọlọrun ti ní ìsinmi nínú iṣẹ́ rẹ, gẹ́gẹ́ bi Ọlọrun ti sinmi nínú iṣẹ́ tirẹ̀. 11 Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí a´sa gbogbo ipá láti wọ inú ìsinmi náà, kí ẹnikẹ́ni má baà se àìgbọran bíi àwọn ti ìsáájú. 12 Nítorí pé, ọ̀rọ̀ Ọlọrun wà láàyè ó tún ní agbára, ó sì tún mú ju idàkídà olójú méjì lọ. Ó si ń fa ọkàn ati ẹ̀mí ẹni ya, àti oríkèé àti ọ̀rá inú egungun. Ó sì mọ ète àti èrò ọkàn ènìyàn. 13 Kò sí ẹ̀dá kankan tó fara sin níwájú Ọlọrun, ohun gbogbo ni ó wá ní ìhòho tí ó sì hàn gbangba níwájú Ẹniti a ó jíyìn fun. 14 Nítorí náà, níwọ̀n ìgbà tí a ní Olórí Àlùfáà ńlá tí Ó ré kọjá lọ sí ọ̀run, àní Jesu ọmọ Ọlọrun, ẹ jẹ́ kí á di ìjẹ́wọ́ wa mú sinsin. 15 Nítorí pé, a kò ní Olórí Àlùfáà tí kìí bá ni kẹ́dùn nínú àwọn àilera wa. Ṣùgbọn, a ní Ẹni tí a ti dán wò ní gbogbo ọ̀nà bíi ti wa, ṣùgbọ́n Òun kò dẹ́sẹ̀ kankan. 16 Ẹ jẹ́ kí á wá sí ibi ìtẹ́ oore-ọ̀fẹ́ pẹ̀lú ìgboyà, kí á leè rí àánú gbà, kí á sì ri oore-ọ̀fẹ́ láti maa ran ni lọ́wọ́ ní àkókò tí ó wọ̀.