1 Nítorínà, ẹ̀yin ará mímọ́, ẹjẹ́ alábàápín ìpè tí o ti ọ̀run wá. Ẹ kíyèsí Jesu, àpóstélì ati Olórí Àlùfáà ìjẹ́wọ́ ìgbàgbọ́ wa. 2 Ó jẹ́ olóòtítọ́ sí Ọlọrun, tí Ó yàn-án gẹ́gẹ́ bí Mose ti jẹ́ olóòtítọ́ nínú ilé Ọlọrun. 3 Nítori a ka Jesu yẹ fún ògo tí o lọ́la ju ti Mose Lọ, bí ẹni tí ó kọ́lé ti ń ọlá ju ilé rẹ̀ lọ. 4 Nítorí kò sí ilé kan tí a kò ti ọwọ́ ènìyàn kọ́, ṣùgbọ́n Ọlọrun ni O kọ ohun gbogbo. 5 Mose jẹ́ olóòtítọ́ nínú gbogbo ilé Ọlọrun gẹ́gẹ́ bíi ìránsẹ. Oun jẹ́ ẹ̀rí sí àwọn ohun tí a yóò sọ ní ọjọ́ iwájú 6 Ṣùgbọ́n kristi ni ọmọ Ọlọrun tí Ó n sàkóso ilé Ọlọrun. Àwa ni ilé Rẹ̀ tí a bá di ìgboyà àti ìsogo ìrètí wa mú sinsin. 7 Nítorínà, gẹ́gẹ́ bí Ẹ̀mí Mímọ́ ti wí pé " Lónìí, bi ẹ̀yin bá gbọ́ ohun Rẹ̀, 8 ẹ má se sé ọkàn yín le bìi ti àkókò tí ẹ se ìsọ̀tẹ̀, ní àkóko ìdánwò nínú aginjú " 9 Nígbà náà ni àwọn baba yin se inúnibíni tí wọ́n dán Mi wò, tí wọ́n sì rí ìse mi fún ogójì ọdún. 10 Nítorí náà mo bínú sí ìran náà. Mo sọ wípé, "Ní gbogbo ìgbà ni ọkàn wọn ń sákolọ. Wọn kò si mọ ọ̀nà mi." 11 Bí mo ti búra nínú ìbínú mi pé, "wọn kò ní wọ inú ìsinmi mi." 12 Ẹ kíyèsára, ará, kí á máse rí ẹni kankan nínú yín tí o ní okàn búburú ti àìgbàgbọ, ọkàn tí ó yapa kúrò lọ́dọ̀ Ọlọrun alàye. 13 Dípò bẹ́ẹ̀, ẹ máa gba ara yín ní ìyànjú ní ojoojúmọ́, ní gbogbo ìgbà tí a bá pè ní "òni," kí enikẹ́ni nínú yín ma baà sé ọkàn rẹ̀ le nípa ìtànjẹ ẹ̀sẹ̀. 14 Nítorí pé a ti di alábàsisẹpọ̀ pẹ̀lú Kristi tí a bá di ìgbẹ́kẹ̀lé wa nínú Rẹ̀ mú ṣinṣin títí dé òpin. 15 Ati sọ nípa èyí pé, "Lónìí, bí ẹ bá gbọ́ ohun Rẹ̀, ẹ má se ọkàn yín le, bíi ti ìgbà ìsọ̀tẹ̀." 16 Tani ó gbọ tí Ọlọrun sọ̀rọ tó tun sọ̀tẹ̀? Sé kìí se gbogbo àwọn tí Mose kó jáde kúrò ní Éjíbìtì? 17 Tani Ó bínú sí fún ogójì ọdún? Sé kìí se sí àwọn tí wọ́n sẹ̀, àwọn tí òkú wọn subú sí aginjù? 18 Tani Ó búra fún wípé, kò ní wọ inú ìsinmi Òun, tí kìí bá se àwọn tí wọn se àìgbọràn sí I? 19 A rí i pe, wọn kò leè wọ inú ìsinmi Rẹ̀ nítorí àìgbagbọ wọn.