1 Nítorínà, a gbọdọ̀ se àkíyèsí gidigidi lórí àwọn ohun ti ati ngbọ̀, kí á ma baà yapa kúrò nínú rẹ̀. 2 Nítorí bí ọ̀rọ̀ tí a ti ẹnu àwọn ángẹ́li sọ bá jẹ́ òtítọ́, àti tí gbogbo ìwà ẹ̀sẹ̀ àti àìgbọràn gba ìjiyà ti ó tọ́ sii, 3 bá wo ni a se leè sá àsálà bí akò ba náání ìgbàlà ńla yìí? Ìgbàlà yí tí Olúwa fúnrarẹ́ kọ́kọ́ kède, tí àwọn tí ó gbọ́ọ sì fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ fún wa 4 Ọlọrun náà jẹri síi pẹ̀lu iṣẹ́ àmì, ìyanu ati àwọn onírúrú iṣẹ́ agbára, àti nípa pínpín àwọn ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́ gẹ́gẹ́ bíi ìfẹ́ Rẹ̀. 5 Nítorípé kìí se àwọn ángẹ́lì ni Ọlọrun fún ni àsẹ láti se àkóso ayé ti ń bọ̀, èyí tí à ń sọ nípa rẹ̀. 6 Dípò bẹ́ẹ̀, ẹnìkan ti jẹ́rìí níbìkan wípé, "Kí ni ènìyàn, tí ìwọ fi ńse ìrántí rẹ̀? Tàbí ọmọ ènìyàn tí ìwọ fi ń se ìtọ́jú rẹ̀? 7 Ìwọ́ dá ènìyàn sí ipò tí ó kéré díẹ̀ sí ti àwọn ángẹ́lì; O sì fi ògo àti ọlá dée ládé. 8 O fi ohun gbogbo sí abẹ́ àkóso rẹ̀." Nítorípé Ọlọrun ti fi ohun gbogbo si abẹ àkóso rẹ. Kò sí ohun kankan ti kò fi sí abẹ́ àkóso rẹ̀. Ṣùgbọ́n nísinsìn yìí, àwa kò ì tíì ri gbogbo ohun tí Ó fi sí abẹ̀ àkóso rẹ. 9 Ṣùgbọ́n àwa rí ẹnití a rẹ̀ sílẹ̀ díẹ̀ ju àwọn ángẹ́lì lọ fùn ìgbà díẹ̀: Jesu, eniti, nítorí ìjìyà àti ikú Rẹ̀, ati dée ní adé ògo àti ọla. Nítorí náà nísinsìn yìí nípa oore ọ̀fẹ́ Ọlọrun, Ó ti tọ́ ikú wò fún gbogbo ènìyàn. 10 Nítorípé ó yẹ fún Ọlọrun, nítorí ohun gbogbo wà fun un àti nípasẹ Rẹ, làti mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọ wá sínú ogo. O tọ́ kí Ó se àsepé Olùgbàlà wọn nípasẹ̀ àwọn ìjìyà Rẹ̀. 11 Nitori láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun kan soso ni ẹni tí ń sọ ni di mímọ́ àti àwọn tí à ń sọ di mímọ́ ti wá. Nítorí náà Jesu kò tijú láti pè wọ́n ni àwọn arákùnrin Rẹ̀. 12 Ò wípé, " Èmi o polongo orúkọ rẹ fún àwọn arákùnrin mi, èmí yíò kọ orin nípa rẹ ní àarin àwùjọ ènìyàn." 13 Ó tún sọ pé, "Èmi yóò gbẹ́kẹ̀ mi léè." Ó tún wípé, "Kíyèsii, èmi nìyí àti àwọn ọmọ tí Ọlọrun fi fún m." 14 Nítorí náà, níwọ̀n ìgbà tí àwọn ọmọ Ọlọrun jẹ́ ẹlẹ́ran ara àti ẹ̀jẹ̀, Jesu náà di ẹlẹ́ran ara àti ẹ̀jẹ̀ bíi wọn, kí Ó leè ti ipàsẹ̀ kíkú ṣégun ẹnití o ni agbára ikú run, èyí nì, Sátánì. 15 Èyí rí bẹ́ẹ̀ kí O leè fi òmìnira fún gbogbo àwọn tí ń gbé ìgbé ayé ẹrú nípa ẹ̀rù ikú sọ. 16 Nítorí ódájú pé, kò wá nítorí àwọn ángẹ́lì; bíkòse fún àwọn irú ọmọ Ábráhámù. 17 Nítorí nàà, ó yẹ fún Un làti dàbí àwọn arákùnrin Rẹ̀ ní gbogbo ọna, kí Òun leè jẹ́ olú àlùfáà aláànú àti olóòtítọ́ nínú àwọn ohun tíí se ti Ọlọrun, àti kí Òun leè jẹ́ ètùtù fún ẹ̀sẹ̀ àwọn ènìyàn 18 Nítorípé, Jesu tìkara Rẹ̀ ti jìyà àti pe a sì ti dan an wò, Ó ni agbára láti ran àwọn tí à ń dánwò lọ́wọ́.