Orí kínní

1 Ní ìgbà àtijọ́, Ọlọrun fi onírúurú ọ̀nà bá àwọn baba wa sọ̀rọ̀ ní órísìísìí ọ̀ná pǎpǎ jùlọ nípa sẹ àwọn wòli. 2 Sùgbọ́n ní ìgbà ìkẹyìn yìí, Ọlọrun ń báwa sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ Ọmọ Rẹ̀, ẹnití O yàn làti jẹ́ ajogún ohun gbogbo. Nípasẹ̀ Rẹ̀ ni Ọlọrun dá ohun gbogbo. 3 Òun ni ìtànsàn ìmọ́lẹ̀ ògo Ọlọrun, àwòrán ohun tì Ọlọrun jẹ́ gan- an. Ò sì tún ń fi ọ̀rọ̀ agbára Rẹ̀ di ohun gbogbo mú sinsin. Lẹ́yìn tí Ó tí se ìwẹ̀numọ́ gbogbo ẹ̀sẹ̀ ènìyàn tán, Ó jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún ọ̀gá ògo ní ibi tí ó ga jùlọ. 4 Òun sí ní ipò tí ó ga ju ti àwọn ángẹ́lì lọ, gẹ́gẹ́ bí orúkọ tí Ó jogún ti tayọ orúkọ wọn. 5 Nìtorípé, èwo nínú àwọn ángẹ́lì ni Ọlọrun sọ fún wípé " Ìwọ ni ọmọ mi, lónìí mo di Bàbá rẹ" tàbí tí Ó wípé " Èmi yóò jẹ́ Bàbá fún un, òun náà yóò jẹ́ ọmọ fún mi"? 6 Ṣùgbọ́n lẹ́ẹ̀kansi, nígbàtí Ọlọrun mú àkọ́bí Rẹ̀ wá sínú ayé, Ó wípé, " Gbogbo àwọn ángẹ́lì Ọlọrun gbọdọ̀ sìn ín" 7 Nípa ti àwọn ángẹ́lì, O wípé, "Òun ni ó dá àwọn ángẹ́lì ní ẹ̀mí, àti àwọn ìránsẹ́ Rẹ̀ ní ọ̀wọ́ iná" 8 Ṣùgbọ́n nípa ti Ọmọ Ó sọ pé, "ìtẹ́ Rẹ, Ọlọrun, ó wà títí láé àti láéláé. Ọ̀pá òdodo ni Ọ̀pá ìjọba Rẹ" 9 Ìwọ ti fẹ́ràn òdodo, O sì kórira àigbọràn sí òfin. Nítorínà Ọlọrun, Ọlọrun Rẹ ti fi òróró ayọ̀ yàn ọ́ ju àwọn ẹgbẹ́ Rẹ lọ." 10 Ní àtètèkọ́se, Oluwa, O ti fi ìpìlẹ̀ ayé lélẹ̀. Isẹ́ ọwọ́ Rẹ ni àwọn ọ̀run. 11 Wọn yóò parun, sùgbọn Ìwọ wà síbẹ̀. Wọn yóò gbó bíi asọ èkísa 12 Ìwọ yóò ká wọn jọ bíi asọ, ìwọ yóò sì pààrọ̀ wọn bíi asọ. Ṣùgbọ́n Ìwọ wà bákan náà, ọdún Rẹ kò lópin. 13 Ṣùgbọ́n èwo nínú àwọn ángẹ́lì ni Ò fi ìgbà kan wí fún pé, " Jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún mi, títí Èmi yóò fi sọ àwọn ọ̀tá rẹ di àpótí ìtìsẹ̀ rẹ " 14 Sé àwọn ángẹ́lì kìí se ẹ̀mí tó n jísẹ́ ni, tí a rán láti ma jíṣé ati lati máa tọ́jú àwọn tí yíò jogún ìgbàlà?