1 Ó sì ṣe ọkùnrin kan ti à ń pè ni Ànànáyà, pẹ̀lú Sàfírà aya rẹ̀, ta ìlẹ̀ kan, 2 ó sì fi díẹ̀ lára owó ilẹ̀ náà pamọ́ (aya rẹ̀ sí mọ̀ síi), ó sì mú ìyókù owó náà wá ó sì fi í sílẹ̀ lábẹ́ ẹsẹ̀ àwọn àpọ́stélì 3 Pétérù sì wípé, "Ananáyà kílódé tí Sàtánì fi kùn ọkàn rẹ láti pa irọ́ fún Ẹ̀mí Mímọ́ àti láti fi pamọ́ lára owó ilẹ̀ náà? 4 Nígbàtí o kò tí tà á, kìí ha ń ṣe tìrẹ bí, àti lẹ́yìn igbà tì o ti tàá, kò ha sí ní ìkàwọ́ rẹ bí? Èéṣe tí o fi ro nǹkan yí ní ọkàn rẹ? Ọlọ́run ni o parọ́ fún, kìí ṣe ènìyàn. 5 Bí Ànànáyà ṣe gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, ó ṣubú lulẹ̀, ó sì kú, ẹ̀rù ńlá sí ba gbogbo àwọn tí ó gbọ́. 6 áwọn ọ̀dọ́kùnrin jáde wá wọ́n sí fi asọ dì í, wọ́n gbé e jáde láti lọ sin. 7 Lẹ́yìn bí i wákàtí mẹ́ta, ìyàwó rẹ wọlé dé, láì mọ ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀. 8 Pétérù sì wí fún pé, "sọ fún mi bóyá iye báyì ni ẹ ta ilẹ̀ yí". Ó sì wípé, "bẹ́è ni, iye rẹ́ ni". 9 Nígbà náà ni Pétérù wí fún un pé, kílódé tí ẹ fi pàmọ̀rànpọ̀ láti dán Ẹ̀mí Olúwa wò? Kíyèsi, àwọn tí wọ́n lọ sin ọkọ rẹ ni wọ́n jáde yìí, wọn yóò sì gbé ìwọ náà jáde pẹ̀lu. 10 Lójúkànnáà, ó ṣúbu lulẹ̀ lẹ́sẹ rẹ̀, ó sì kú. Nígbàtí àwọn ọ̀dọ́kùnrin náà wọlé dé, wọ́n bá a tí ó ti kú, wọ́n sì gbé e jáde, wọ́n sì sín sí ẹ̀gbẹ́ ọkọ rẹ̀. 11 Ẹ̀rù ńlá sì ba gbogbo ìjọ àti gbogbo àwọn ẹni tí ó gbọ́ àwọn nǹkan wọ̀nyìí. 12 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn iṣẹ́ àmì àti iṣẹ́ ìyanu ló ń ṣẹlẹ̀ láti ọwọ́ àwọn àpọ́stélì. 13 Ṣugbọn ẹnikẹ́ni kò lè dábàá àti darapọ̀ mọ́ wọn; síbẹ̀ àwọn ènìyàn kà wọ́n kún ẹni pàtàkì. 14 Síbẹ̀síbẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn onígbàgbọ́ lọ́kùnrin àti lóbìnrin ń darapọ̀ mọ́ Olúwa, 15 tóbẹ̀ẹ̀ tí wọ́n gbé àwọn aláìsàn wá sí ojú ọ̀nà tí wọ́n sì tẹ́ wọn sí orí ìbùsùn àti orí ìtẹ́ kí òjìji Pétérù, nígbà tí ó bá ń kọjá, le wò wọ́n sàn. 16 Ộpọ̀lọpọ̀ ènìyàn sí tún wá láti àwọn ìlú agbègbe Jèrúsálẹ́mù, pẹ̀lú àwọn aláìsàn àti àwọn tí àwọn ẹ̀mí àimọ́ ń dàláàmú, a sì mú gbogbo wọ́n láradá. 17 Sùgbọn olóri àlúfà dìdé, àti gbogbo àwọn ẹni tí wọ́n wà pẹ̀lú rẹ̀ (àwọn ẹ̀yà Sadusí); wọ́n sí kùn fún owú. 18 wọ́n sí fi ipá gbá àwọn àpọ́stélì mú, wọ́n sí sọ wọ́n sínu túbú gbogbogbò. 19 Síbẹ̀ ní alẹ́, ángẹ́lì Olúwa ṣí àwọn ìlẹ́kùn ilé túbú nàà, ó sì mú wọn jáde, ó wípé, 20 "Ẹ lọ, ẹ dúró ní tẹ́ḿpìlì kí ẹ sì sọ gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ Ìyè yì fún àwọn ènìyàn náà. 21 Nígbàtí wọ́n gbọ́ èyí, wọ́n wọ inú tẹ́ḿpìlì lọ ní àfẹ́júmọ́, wọ́n sí kọ́ ni. Sùgbọ́n olórí àlúfà dé, àti àwọn tí ó wà pẹ̀lu rẹ̀, wọ́n sì pe ìgbìmọ̀ jọ àti gbogbo àwọn àgbààgbà àwọn ọmọ Ísrẹ́lì wọ́n sì ránsẹ́ sí ilé túbú látì mú àwọn àpọ́stélì na wà. 22 Sùgbọ́n àwọ́n ọmọ-ogun tí wọ́n lọ kò rí wọn nínú túbú, wọ́n sì padà lọ jísẹ́ fún wọn, 23 "A bá ìlẹ̀kùn ilé túbú ní títìpa, àwọn ẹ̀sọ́ sì ń ṣọ́ ẹnu ọ̀nà, sùgbọ́n nígbàtí a ṣí ilé túbú, a kò rí ẹnikẹ́ni nínú rẹ." 24 Ǹjẹ́ nígbàtí olórí ogun tẹ́ḿpílì àti àwọn olórí alùfá gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, ọkàn wọn pòruurù nípa ohun tí yóò ti ẹ̀yìn rẹ̀ wá. 25 Lẹ́yìn náà ni ẹnìkan wá tí ó sì sọ fún wọn wípé, "Àwọn ọkùnrin tí ẹ fi sínu túbú ńkọ́ àwọn ènìyàn nínú tẹ́mpílì." 26 Nígbà nàá ni olórí ogun tẹ̀lẹ́ àwọn ọmọ-ogun, wọ́n sì lọ mú wọn padà, sùgbọ́n láìfi ipá ṣe é, nítorí ẹ̀rù bà wọ́n pé àwọn ènìyàn le sọ wọ́n ní òkúta. 27 Nígbàtí wọ́n sì ti mú wọn wá, wọ́n kó wọn wá sí iwájú ìgbìmọ̀. Olórí àlúfà sì fi ọ̀rọ̀ wá wọn lẹ́nu wò, 28 wípé, "A ti kìlọ̀ fún yín gidigidi pé kí ẹ máse kọ́ni ní orúkọ yìí mọ́, síbẹ̀, ẹ ti fi ẹ̀kọ́ yín kún Jerúsálémù, ẹ sì ti pinnu làti fa ẹ̀jẹ̀ ọkùnrin yìí sórí wa." 29 Ṣùgbọ́n Pétérù àti àwọn àpọ́stélì dáhùn wípé, "Ó pan dandan fún wa láti gbọ́ràn sí Ọlọ́run ju ènìyàn lọ. 30 Ọlọ́run àwọn bàba wa jí Jésù dìde, Ẹni tí ẹ̀yin pa nípa kíkàn Án mọ́ igi. 31 Ọlọ́run sì gbé E ga sí ọwọ́ ọ̀tún Rẹ̀ láti jẹ́ Ọmọ-Ọba àti Olùgbàlà, látì fún Ísrẹ́lì ní ìrònúpìwàdà àti ìdáríjí ẹ̀sẹ̀ wọn. 32 Àwá sì jẹ́ ẹlẹ́rìí àwọn nkan wọnyìí, bẹ́ẹ̀ sì ni Ẹ̀mí Mímọ́, Ẹniti ti Ọlọ́run ti fún àwọn tí ó gbọ́ràn sí I. 33 Nígbàtí àwọn ọmọ ìgbìmọ̀ gbọ́ èyí, inú bí wọn gidigidi, wọ́n sì fẹ pà àwọn àpọ́stélì. 34 Ṣùgbọ́n Farisí kan tí à n pé ní Gàmálíẹ́lì, olùkọ́ òfin, ẹnití gbogbo àwọn ènìyàn bu ọlá fún, dìde dúró o sì pàṣẹ wípé kí àwọn àpọ́stélì yẹra fún wọn fún ìgbà díẹ̀. 35 Ó sì sọ fún wọn wípé "Ẹ̀yin alàgbà Ísrẹ́lì, ẹ kíyési ohun tí ẹ n gbèrò látì ṣè sí àwọn ènìyàn wọ̀nyí o. 36 Ní ìgbà díẹ̀ sẹ́yìn, Tíúdà dìde, ó ń ka ara rẹ̀ kún ẹnikan pàtàkì, áwọn okúnrin bíi irinwó sì darapọ̀ mọ. Ṣùgbọ́n lẹ́yìn ikú rẹ̀, àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ fọ́n káàkiri, wọ́n kò sì já mọ́ ǹkankan mọ́. 37 Lẹ́yìn arákùnrin yìí, Júdásì aráa Gálílì dìde ní ìgbà ìkànìyàn, ó sì fa ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn sọ́dọ̀ rẹ̀. Òhun náà ṣègbé gbogbo àwọn tí ó ti ń tẹ̀le sì fọ́n káàkiri. 38 Ǹjẹ́ mo wí fún yín, ẹ ṣe gáfárà fún àwọn ènìyàn yí kí ẹ sì fi wọ́n lọ́rùn sílẹ̀, nítorí tí iṣẹ́ yìí bá jẹ́ ti ènìyàn, yí ò dàwó. 39 Ṣùgbọ́n tí ó bá jẹ́ ti Ọlọ́run, ẹ kò nì le borí wọn; ẹ tún wá le ṣe àkíyèsí pe ẹ̀ ń dojú ìjà kọ Ọlọ́run ni." Bẹ́èni ó sì rí wọ́n rọ̀. 40 Wọ́n sì pe àwọn àpọ́stélì náà wọlé, wọ́n nà wọ́n, wọ́n sì páṣẹ́ fún wọn wípé kí wọn máṣe sọ̀rọ̀ ní orúkọ Jésù mọ́, wọ́n sì fún wọn ní òmìnira. 41 Wọ́n fi ayọ̀ kúrò lọ́dọ àwọ́n ìgbìmò wípé a kà wọ́n yẹ láti kàbùkù nítorí Orúkọ náà. 42 Lẹ́yìn èyí lójojúmọ́, nínú tẹ́ḿpílì àti láti ilé dé ilé, wọ́n tẹ̀síwájú láti má kọ́ni àti láti má polongo Jésù gẹ́gẹ́bi Krístì náà.