1 Ǹjé nígbàtí iye àwọn ọmọẹ̀yìn ń pọ̀ gidigidi ní ọjọ́ wọnì, àwọn Júù ti Gíríkì ń se àwáwí lóri àwọn ará Hébérù, nítorí tí wón gbàgbe àwọn opó wọn níbí pín pín óunje ojojúmọ́. 2 Àwọn Ọmọẹ̀yìn méjìlá náà síì pe àwọn ọmọẹ̀yìn tí ókù jọ, wípé, "kò tọ̀nà fún wa lati máa pín óúnjẹ dípò kíkọ́ ọ̀rọ Ọlọ́run. 3 Nítorínà, ẹyan àwọn ọkùnrin méje láàrin arayín, àwọn ẹnití oní ìwà rere, tí wọ́n kún fún Ẹ̀mí Ḿimọ́ àti fún ọgbọ́n, tí a lè yàn fún iṣẹ́ yìí. 4 Sùgbọ́n Àwa yíò tẹ̀sìwájú nínu àdúrà àti nínu iṣẹ́ ìránsẹ́ ti kíkọ́ àti pípolongo ọ̀rọ̀ náà. 5 Ìjọ ènìyàn sí gbà ìmọ̀ràn wọn. Wọ́n sì yan Stífánù, ẹnití ókún fún ìgbàgbọ́ pẹ̀lú Ẹ̀mí, àti Fílípì, Prókórọ́sì, Níkánọ̀, Tímọ̀nì, Pámínásì, àti Níkólọ́sì. 6 Wọ́n sì mú wọn tọ àwọn ápọ́stélì lọ, tí wọ́n gbàdúrá fún wọn àti gbígbé ọwọ́ léwọn lórí. 7 Nítorínà, ọ̀ro Ọlọ́run síì ń gbilẹ̀, àwọn ọmọẹ̀yìn síì ń pọ̀ si gidigidi ní Jerúsálẹ́mù, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn àlúfà sì se ìgbọ́nràn sí ìgbàgbó náà. 8 Stífánù, ẹnití ókún fún ore-ọ̀fẹ́ àti agbára Ọlọ́run, ń se àwọn isẹ́ àmìn àti àwọn isẹ́ àgbàyanu láàrin àwọn ẹ̀nìyàn. 9 Sùgbọ́n àwọn aráa Sínágọ́gù kan dìde, tí à ń pè ní Sínágọ́gù Olómínira, ti Síríánì àti Alẹsáńdárà, àti àwọ́n kan ní Silísíà àti Ásíà. Wọ́n ń se àríyànjiyàn pẹ̀lu Stífánù. 10 Ṣùgbọ́n wọn kòlè borí Ẹ̀mí Mímọ́ àti ọgbọ́n tí Stífánù fi ń báwọn sọ̀rọ̀ 11 Wọ́n sì pe àwọn kan láti jẹ́ ẹ̀rí èké wípé, "Àwá ti gbọ́ tí Stífánù sọ̀rọ̀ òdì sí Mósè àti sí Ọlọ́run." 12 Wọ́n mú kí àwọn enìyàn, àwon alàgbà àti àwọn akọ̀wé bínú gidigidi tí wọ́n sì mú Stífánù lọ sí iwájú àwọn ìgbìmọ̀. 13 Wón sì mu awọn ẹlẹri èké wá láti takòo, wípé, ''Arákùnrin yìí ń sọ ọ̀rọ̀ òdì sí íbí mímọ́ yìí àti sí òfin. 14 Nítorítì àwá ti gbọ́ tí ó wípé Jésù ti Násárẹ́tì yìí máa wó ibi mímọ́ yìí palẹ̀, yí ó sì yí àwọn àsà tí ajogúnwá láti ọwọ́ Mósè padà'' 15 Gbogbo ẹnití ó jòkó ní ìjọ ìgbìmọ́ nàà sìí tẹjúmọ́ọ, wọ́n sì rí ojú rẹẹ̀ tí ó dàbi ti áńgẹ́lì.