Orí Kẹrin

1 Bi Pétérù àti Johánnù ti ńbá àwọn ènìyàn náá sọ ọ̀rọ̀, àwọn àlùfáà, àwọn òlórí ogun tẹ́ḿpílì àti àwọn Sadusí ya bo wọ̀n. 2 Ìdámú ba wọn gidigidi nítorí pé Pétérù òun Jòhánnù nkọ́ àwọn ènìyàn, wọ́n sì ń polongo àjíǹdé Jésù kúrò nínú àwọn òkú. 3 Wọ́n sì sọ wọn si inu tùbú di ọjọ́ kejì, nítorípé àlẹ tí lẹ. 4 Sùgbón, ọ̀pọ̀ ènìyàn tí wọ́n ti gbọ́ ọ̀rọ̀ wọn gbàgbọ́, iye àwọ́n tí o gbàgbọ́ sì jẹ́ ẹ̀gbẹrún márùn. 5 Ó sì ṣe nì ọjọ̀ kejì tí àwọn aláṣẹ, àwọn alàgbà atí àwọn akọ̀wé péjọpọ̀ ní Jèrúsálẹ́mù. 6 Ánná, Olórí àlùfáà wà níbẹ̀ atí Kéífàsì, atí Jòhánnù, atí Alẹksáńdérù atí gbogbo àwọn tí ó jẹ́ ẹbí Olórí àlùfáà. 7 Nígbà tí wọn tí fi Pétérù òun Jòhánnù sáàrin wọn, wọ́n bèrè lọ́wọ wọn ''nípa agbára wo, tàbí orúkọ wo ni ẹ́yin sé èyí'' 8 Nígbànáà ni Pétérù kún fún Ẹ̀mí mímọ́, ó wi fún wọn, ''ẹ̀yin aláṣẹ ènìyàn atí ẹ̀yin àgbàgbà, 9 bí a bá wa ń bi wá léèrè lóni nípa òun rere ti a ṣè sí ọkùnrin aláísàn yìi nípa ǹkán tí a fi mú un láradá? 10 kí èyí di mímọ̀ fún gbogbo yín àtí gbogbo ará Ísrẹ́lì, pé ní orùkọ́ Jésù Krístì tí Násárẹ́tì tí ẹ kàn mọ́ àgbélèbú, tí Ọlọ́run jí dìde kúrò nínú òkú; nípaṣẹ̀ rẹ̀ ni ọkùnrin yì ṣe dúro níwajú yín ní dídá ara. 11 Krístì ni òkúta tí ẹ̀yin ọ̀mọ̀lé kọ̀ sílẹ̀ sùgbọ́n tí a sọ di pàtàkì igun ilé. 12 Kòsí ìgbàlà lọ́dọ̀ ẹlòmíràn, nítorí kòsí orúkọ míràn lábẹ́ ọ̀run tí a fifún ènìyàn láti gbanilà'' 13 Nísinsìnyí, nígbàtí wọn sì rí ìgboyà Pétérù àti Jòhánnù tí wọn ṣì mọ pé ènìyàn lásán, aláìmọ̀wé niwọ́n, ẹnu yà wọ́n pé Pétérù atí Jòhánnù ti wà pẹ̀lú Jésù. 14 wọn ṣì rí ọkùnrin tí à mú láradá dúró pẹ̀lú wọn, wọn kò sì rí ohùn kankan wí sí wọn 15 lẹ́hìn ìgbà tí wọn pa àṣẹ fún àwọn àpóstélì láti jáde kúrò nínú ìpàdé ìgbìmọ̀, wọn bá ara wọn jíròrò. 16 Wọn wípé, ''kíni àwa ó ṣe si àwọn ọkùnrin yìí? Nítorípé, atí ti ọwọ́ wọn ṣe ìṣẹ́ ìyanu tí ó han sí gbogbo olùgbé Jèrúsálémù, ti akò lè fi ojú rénà. 17 Sùgbón, latí dẹ́kun ìtànkálẹ̀ rẹ̀, ẹ jẹ́ ki à kìlọ̀ fún wọn láti má sọ ọ̀rọ̀ fún ẹníkẹ́nì ni orúkọ yii'' 18 Wọn sì pè Pétérù atí Jòhánnù wọlé wọ́n sì pàṣẹ fún wọn láti má sọ̀rọ̀ tàbí kọ́ni ní orúkọ Jésù mọ́. 19 Ṣùgbón Pétérù oun Jòhánnù dáhùn, wọ́n sì wí fún wọn pé '' tí ó bá jẹ́ pé o tọ̀nà níwájú Ọlọ́run latí gbọ́ràn sì yín dípò Ọlọ́run, ẹ gba èyí rò. 20 Àwa kò le dẹ́kun ṣísọ ọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun tí a rí tí a si gbọ̀ 21 Lẹ́hìn tí wón ti kìwón nílọ̀ wọ́n fi Pétérù àti Jòhánù sílẹ̀. wọn kò sì rí ẹ̀sùn kankan latí jẹ wọn ni iiyà nítorípé gbogbo ènìyàn yin Ọlọ́run fún ohun ti ó ti ṣẹlẹ̀. 22 Ọ̀kùnrin tó ní ìrírí iṣẹ́ ìyanu ìwòsàn ju ogójì ọdún lọ 23 Lẹ́hín tí wọ́n da wọn sìlẹ́, Pétérù atí Jòhánnù wa sọ̀dọ́ àwọn ẹlẹgbẹ wọn, wọn ròhín gbogbo ohun ti àwọn Olòrí alùfáa, atí àgbàgbà sọ́ fún wọn. 24 Nìgbá tí wọn gbọ̀, wọn gbe ohún wọn pàpọ̀ soké sí Ọlọ́run pé ''Olúwa, ìwọ ni o dá àwọn ọrún atí aiyé atí òkun atí ohun gbogbo tí ó wá nínú wọn. 25 O sọ́ ọ̀rọ̀ nìpá Ẹmí mímọ́ latí ẹnu ìráńṣẹ rẹ, bàbá wa Dafídì, kìní ìdí tí àwọn orílèedè kéférí fí nbínù tí àwọn ènìyàn ṣí ngbero asan?" 26 ìwọ wipe, 'àwọn ọ̀ba àyé kó ara wọn jọ , atí àwọn àláṣẹ́ ko ra wọn jọ pọ̀ lodí sí Olúwa atí lodí sí Kristí rẹ̀.' 27 Ní tòótọ́, Hẹ́rọ́dù àti Pọ́ntù Pílátù pẹ̀lú àwọn kèfèrí àti àwọn ènìyàn Isrẹ́lì pé jọpọ̀ ní ìlú yìí tako ìránṣẹ́ mímọ́ rẹ Jésù tí ìwọ fi òróró yàn. 28 wọ́n pé jọ papọ̀ láti se ohun gbogbo tí ọwọ́ àti èto rẹ tí pinnu saájú pé yó ṣẹlẹ̀. 29 Nísisìnyí, Olúwa wo ìkìlọ̀ wọn kí o sì fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ ní ìgboyà láti sọ ọ̀rọ̀ rẹ. 30 Na ọwọ́ rẹ láti wòsàn àti láti fún ni ní àmì àti àwọn iṣẹ́ ìyanu nípasẹ̀ orúkọ ìránṣẹ́ mímọ́ rẹ Jésù.'' 31 Nígbàtí wọ́n gba àdúrà tán, ibi ti wọ́n pé jọpọ̀ sí mì, wọ́n sì kún fún Ẹ̀mí Mímọ́, wọ́n si fì ìgboyà sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. 32 Ọ̀gọ̀rọ̀ iye àwọn tó gbàgbọ́ wà ní ìsọ̀kan ní ọ̀kan àti ní ẹ̀mí, kò sí ẹni tó sọ pé ohun tí òun ní ti oùn ní, sùgbón wọ́n ní ohun gbogbo ní isọ̀kan. 33 Pẹ̀lú agbára ńlá, ni àwọn àpòstélì fi ń kéde ẹ̀rí wọn nípa Olúwa Jésù, ore ọ̀fẹ́ ńlá sí wà lórí gbogbo wọn. 34 Kòsí ẹnikẹ́ni nínú wọn tó se aláìnì ohunkóhun, nítorí àwọn tó ní ilẹ̀ tàbí ilé tà wọ́n 35 wọ́n sì kó owó oun tí wọ́n tà wá sí ẹsẹ̀ àwọn àpòstélì wọ́n sí se ìpìnfúnni wọn gẹ́gẹ́bí olúkúlùkù se níló. 36 Jósẹ́fù ọmọ Léfi, ọmọ kùnrin Sípúrọ́sì tí àwọn àpòstélí ǹpè ní Bánábà (ìtumọ̀ èyítí í ṣe, Ẹnití ó ń fúnni ní kóríyá), 37 ta ilẹ̀ ó sì mú owó rẹ̀ wá sí ẹsẹ̀ àwọn àpòstélì.