1 Nísinsìnyí Pétérù àti Jòhánnù lọ sí tẹ́ḿpìlì ní àkókò àdúrà ní déédé wákàtí kẹsàn ọjọ́. 2 Ńwọ́n gbé ọkùnrin kan tí ó yarọ láti inú ìyá rẹ̀ wá sí ẹnu àbáwọ tẹ́ḿpìlì tí à ńpè ní dáradára láti máa tọrọ owó. 3 Nígbà tí ó rí Pétérù àti Jòhánnù bí wọn ṣe fẹ́ wọ inú téḿpìlì, ó tọrọ owó lọ́wọ́ wọn. 4 Pétérù pẹ̀lú Jòhánnù tẹjú mọ́ ọ, wọ́n wípé, "wò wá" 5 Ọkùnrin arọ náà wò wọń ní ìrètí àti rí ǹkan gbà lọ́wọ́ wọn. 6 Ṣùgbọ́n Pétérù wípé fàdákà àti wúrà, èmi kòní, ṣùgbọ́n ǹkan tí mo ní, ni mo fún ọ. Ní orukọ Jésù Krístì ti Násárẹ́tì, dìde kí o sì má a rìn. 7 Pétérù gbá a mú ní ọwọ́ ọ̀tún ó fàá sókè, lọ́gán ẹsẹ̀ àti gìgíṣẹ̀ rẹ̀ gba okun. 8 Ó fò sókè, ó ń rìn, ó sì wọ tẹ́ḿpìlì pẹ̀lú Pétérù àti Jòhánnù ó ń fò sókè ó sì ń yin Ọlọ́run. 9 Gbogbo ènìyàn rí i tí ón rìn tí ó sì ń yin Ọlọ́run. 10 Wọ́n sàkíyèsí pé, ò n ni ọkùnrin náà tí ń má ń tọrọ owó ní ẹnu ọ̀nà dáradára téḿpìlì, wọ́n kún fún ìyàlénu nítorí ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí i. 11 O di Pétérù atí Jòhánnù mu àwọn eníyàn súré sí wọ̀n ninu ìloro Sólómọ́nì pẹlu ìyàlẹ́nu. 12 Ti Peteru ri eyi, o da awọn eniyan lohun wipe 'Ẹyin eniyan Israẹli, eese ti ẹnu fi ya yin? ki ni idi ti ẹ fi tẹjumọ wa, bi pe awa la muun rin pelu agbara tabi ìwàbíọlọ́run wa ni a sè mú rin 13 Ọlọrún Àbrahámù, Isaakì atí Jàcọ́bù, Ọlọrún awọ́n baba wà fií ogo rẹ̀ han ninu iranṣẹ rẹ Jesu. Oun ni ẹ yọnda ti ẹ si kọ niwaju Pílátù, nigba ti o ti pinnu lati jọwọ rẹ silẹ lọ. 14 Ẹ kọ ẹni mímọ́ atí olododo ẹ si bere fun jijọ̀wọ̀ apaniyan silẹ fun yin. 15 Ẹ pa olusẹ̀dá ẹ̀mí tí Ọlọrùn ji didé kuro ninu oku, a si jẹ ẹlẹri si ijídìdé rẹ̀. 16 Nisinyi, nipa igbagbọ ninu orukọ rẹ ọkunrin yi ti ẹyin ri, ti ẹ si mọ, orukọ yi na lo mu ni ara le. Igbagbọ ninu Jesu lo mu larada niwaju gbogbo yin 17 Nisinsinyi, ará mo mọ pe ninu àìmọ̀ ni ẹ huwa, gẹgẹbi awọn alaṣẹ yin na ti se. 18 Sugbon awọn nkan ti Ọlọrun ṣọ sááju lati ẹnu awọn wòólì pe Kristi yo jiya ti wa si ìmúsẹ. 19 Nitorínà, ẹronù ki ẹ sí yipadà ki à ba le pa ẹsẹ yin rẹ̀, fún akòkò itúrà lati ọdọ Oluwa, 20 atí pe ki aba le ran Kristi ẹni ti a ti yan fun yin, àní Jesu. 21 Oun ní Ọrún ma gbà titi di akòkò ìmúpadàbọ̀sípò oun gbogbo ti Ọlọrun ti sọ saaju lati ẹnu awọn wòólì mimọ rẹ. 22 Mósè nà wípé, "Olúwa Ọlọ́run yóò gbé wòólì dìde bí rẹ̀ láàrín àwọn arákùnrin yín. Ìwọ yóò sì tẹ́tísílẹ̀ gbọ́ oun gbogbo tí yóò sọ fún ọ. 23 Ẹnikẹ́ni tí kò bá tẹ́tísílẹ̀ gbọ́ ọ̀rọ̀ wòólì náà yóò parun láàrín àwọn ènìyàn." 24 Lòtitọ̀, gbogbo àwọn wòólì láti orí Sámúẹ́lì àti àwọn tó wá léyìn rẹ̀, wọn sọ́ jáde, wọn si kéde àwọn ọjọ́ yìí. 25 Ẹ̀yin ni àwọn ọmọ wòólì àti tí májẹ̀mú tí Ọlọ́run dá pẹ̀lú àwọn baba ńlá yín, gẹ́gẹ́bí Ó ti wí fún Ábráhámù, "Nínú èso rẹ́ ní gbogbo ìdílé áyé yóò di alábùkún fún." 26 lẹ́yìn, tí Ọlọ́run jí ìráńṣé rẹ̀ dìde, Ó kọ́kọ́ rán sí yín kó ba lè bùkun yin nipa yiyipada kuro ninu ibi.