Orí kejì

1 Nígbà tí ọjọ́ Pẹ́tíkọ́stì dé, gbogbo wọn wà papọ̀ níbi kan náà. 2 Lòjíjì ni ohùn kan bíi ti efúúfù líle tí ọ̀run sọ̀kalẹ̀ wá, ó sì kún gbogbo ibi tí wọ́n jòkó sí 3 Ohún tí ó jọ ẹ̀là ahọ̀n sì yọ lòrì ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn 4 Gbogbo wọn sì kún fún Ẹ̀mí Mímọ́, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ àwọn èdè míràn bí Ẹ̀mí náà ti fún wọn lọ́rọ̀ sọ. 5 Nígbà yẹn ni àwọn Júù olùfọkànsìn láti orilẹ̀-èdè kọ̀ọ̀kàn tí wọ́n ń gbé ní Jèrúsálẹ́mù 6 Nígbà ti wọ́n gbọ́ ariwo yìí, ọ̀pọ̀ ènìyàn kò ara wọn jọ, ẹ̀nu sì ya ọ̀kọ̀ọ̀kàn wọn nítorí olúkúlùkù ni ó gbọ́ èdè abínibí tirẹ̀ lẹ́nu wọn. 7 Ẹnu sì yà wọn gidigidi, wọ́n sì sọ fún ra wọn wípé, ẹ wò ó, ǹjẹ́ àwọn wọ̀nyí kì íṣe àwọn ara Gálílì bí? 8 Èé ṣé tí gbogbo wá fí ń gbọ́ èdè abínibí tírẹ̀ 9 Àwọn ará Pátíà, Mídíà, Élámù àti àwọn tí ń gbe ni Mesopotámíà, ni Jùdíà àti Kapadóṣíà, ni Pọ́ńtù àti Ásíà 10 Fírígìa, Pamfílíà, ni Ìjǐpitì àti àwọn agbègbè Líbíyà lẹ́bàá kírénè, àti àwọn àléjò Róòmù, Júù àti àwọn ọmọ lẹ́yìn. 11 Àwọn ará Kìrétè àti Arábíà, à ńgbọ́ tí wọn ńsọ̀rọ̀ iṣẹ́ ìyanu Olúwa. 12 Ẹ́nú sì yà wọ́n gidigidi, ó sì rú wọn lójú, wọ́n sì wí fún ara wọn wìpé, "Kínni ìtumọ̀ èyí?" 13 Ṣùgbọ́n àwọn afiniṣẹ́lẹ́yà àárìn wọn wípé, àwọn wọ̀nyi tí mu ọtí yó." 14 Ṣùgbọ́n Pétérù dìde dúró pẹ̀lú àwọn mọ́kànlá yòókù, Ó gbé ohùn rẹ sókè, ó sì wí fún wọn wípé, " Ẹ̀yin ará Jùdíà àti gbogbo ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbé ní Jérúsálẹ́mù, ẹ mọ èyí lónìí, ẹ sì fi etí sílẹ̀ sí ohun tí mo ní láti sọ 15 Àwọn eniyan wọ̀nyi kò mu ọtí para bí ẹ̀yín ti léro, bi ẹti mọ̀ wípé wákàtí kẹta ọjọ́ laa wà. 16 Ṣùgbọ́n èyí jẹ ohun tí ó ti ẹnu wòólì Jóẹ̀lì wá wípé: 17 Yí ò sì ṣe ní ọjọ́ ìkẹyìn, ni Olúwa wí, Èmi ó tú ú Ẹ̀mi mi jáde sí orí gbogbo ènìyàn: àwọn ọmọ yín ọkùnrin àti àwọn ọmọ yín obìnrin yin yí ó má sọtẹ́lẹ̀: àti àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin yín yí ó má a ríran àti àwọn arúgbó yín yí ó máa lá ààlá. 18 Àti lórí àwọn ìránṣẹ́ mi lọkùnrin àti lòbìnrin ni Èmí ó tu Ẹ̀mí mi jáde sí, wọn ó sì má sọtẹ́lẹ̀. 19 Èmi ó fi àmìn hàn ní ọ̀run àti ní ayé lábẹ́ rẹ̀, ẹ̀jẹ̀, iná àti ooru èéfín. 20 Òòrùn yí ó sì di òkùnkùn, òsùpá yí ò sì di ẹ̀jẹ̀ kí ọjọ Olúwa tí ó tóbi tí ó si láàmì láaka kí ó tóó dé. 21 Yí ò sì ṣe, ẹnikẹ́ni tí ó bá pé orúkọ Olúwa ni á ó gbàlà. 22 Ẹ̀yin ara Ísrẹ́lì, ẹ gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyi: Jésù tí Násárẹ́tì, Ẹní tí Olúwa fihàn nípa ìsehun ńlá tí ó jẹ́ ojúlówó, àti iṣẹ́ ìyanu èyi tí Olúwa tí ọwọ́ Rẹ́ ṣé bí ẹ̀yin tí mọ̀. 23 À fí arákùrin yí lé lẹ̀ láti ọwọ́ Olúwa nípa èté ti Olúwa ní lọ́kàn àti ìmọ̀ òye Rẹ àti ẹ̀yin nípa àwọn arúfin yín kàn án mọ́ àgbélébú. 24 Ṣùgbọ́n Olúwa jí i didé, Ó sí túu sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ìrora ísà òkú, nítorí kò ṣèé ṣé fún un láti mún un ní ìgbèkùn. 25 Nítorì Dáfídì sọ nípa Rẹ̀, 'Èmí gbé Olúwa ka iwájú mi Ó wà ní apá ọ̀tún mi, A kíì yóó ṣími nípò. 26 Nítorì náà inú mi dún ayọ̀ mí sì kún. Bákan náà, mo ní ìgboyà nínú ara mí. 27 Nítorì ìwọ kò ni gbàgbé ọkàn mi sí ipò òkú tàbí kí o jẹ́ kí Ẹni Mímọ́ Rẹ rí ìdìbàjẹ́. 28 Ìwọ ó fi ọ̀nà ìyè hàn mí; ìwọ Ó jẹ́ kí èmi kuń fuń inú dídùn níwájú Rẹ. 29 Ẹ̀yin ará, mo lè ba yín sọ̀rọ́ pẹ̀lú ìgboyà nípa Bàbá wa Dáfídì: ó kú, a sì sín, gbogbo wa ni a sì mọ sàárè rẹ̀ títí di òní. 30 Nítorína, ó jẹ́ wòólì, ó sì mọ̀ wípé Ọlọ́run ti búra pẹ̀lú rẹ̀ wípé Òun yí ò fi ìkan nínú àwọn èso rẹ̀ sí óri ìtẹ rẹ̀. 31 Ó ti rí èyí sáájú, ó si sọ nípa àjíǹde Krístì, A kò kọ̀ ọ́ sílẹ̀ ní ipò òkú tàbí kí ẹran ara rẹ̀ rí ìdìbajẹ. 32 Jésù yí ni Ọlọ́run jí dide, èyí tí gbogbo wà sì jẹ́ ẹlẹ́rìí. 33 Nítorínà níwọ̀n ìgbà tí a ti gbé E ga sí ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run ati Ẹ̀mí Mímọ́ tí a sí tì ṣe ìlérí rẹ̀ fún wa ni ó tú jáde sí wa báyìí èyí tí ẹ̀yin rí, tí ẹ sì gbọ́. 34 Nítorí Dáfídí kò gòkè lọ́ sí ọrún, ṣùgbọ́n ó wipé, Olúwa sì sọ́ fún Olúwa mi pé Jòkó sí apá ọtún mí, 35 títí Èmí ó fí sọ àwọn ọ̀tá rẹ dí àpọ́tí ìtìsẹ̀ rẹ 36 Nitorínà, gbogbo ilè Ísírẹ́lì, ẹ mọ̀ èyí dajú wipé Ọlọ́rún tí sọ ọ́ di Olúwa ati Krístí, Jesú yìí tí ẹ kàn mọ́ àgbèlèbú. 37 Nísinsìnyi, nígbà tí wọ́n gbọ́ èyí, ọkán wọn gbọgbẹ́, wọ́n sì wí fún Pétérù àti àwọn Àpọstéli tí ó kù, " Ará, kíni kí á ṣe?" 38 Nígbà náà ni Pétérù wí fún wọn wípé " Ẹ ronúpìwàdà, kí á sì rì olúkúlúkù yín bọmi ní orúkọ Jésù fun ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ yín, ẹ̀yin ó sì gba ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́. 39 Nítorítí ilérí náà wa fún yín àti fún àwọn ọmọ yín àti fún gbogbo àwọn ti ó wà lókè réré, àti gbogbo àwọn tí Olúwa, Ọlórún wa yí ó pè. 40 Pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ míràn ni ó fi jẹ́ẹ́rí tí ó sì gbà wọ́n níyànjú, Ó wípé, " Ẹ gba ara yín là lọ́wọ́ ìran bubúrù yíì." 41 Nígbà náà ni wọ́n gbà á gbọ́, a sì rí wọ́n bọ omi, Ẹgbẹ̀rún mẹ́ta sì darapọ̀ mọ́ wọn 42 Wọ́n tẹ̀sìwájú nínú ẹ̀kọ́ àwọn Àpọ́stèlì àti ìjọsìn, ní pínpín àkàrà àti nínú àdúrà. 43 Ẹ́rú ba ọpọ ènìyàn nítorí ọ̀pọ̀ isẹ́-ìyanu àti àmì nì a gba ọwọ́ àwọn Àpọ́stélì ṣe 44 Gbogbo àwọn ti ó gbàgbọ́ sì wà a ní ìṣọ̀kan, wọ́n sì ní ohun gbogbo papọ̀. 45 Àwọn ti ó ní n ǹkàn ìní àti ogún sì tà á, wọ́n sì fún olúkùlùkù, gẹ́gẹ́ bí wọ́n tí nílò. 46 Látì ọjọ́ dé ọjọ́, wọ́n ń tẹ̀síwájú pẹ̀lú ìsọ̀kan nínù témpílì, wọ́n sì ń jẹun ní ilè ara wọn pẹ̀lú ayọ́ àti ìrẹ̀lẹ̀ ọkàn; 47 wọ́n n yín Ọlọ́rún lógo, wọ́n sì rí ojúrere gbà lọ́wọ́ gbogbo ènìyàn.Ojojúmọ́ ni Olúwa sì mú àwọn ènìyàn darapọ̀ mọ́ àwọn tí á gbàlà.