ORÍ KẸẸ̀SÁN

1 Níti iṣẹ́ ìránṣẹ́ fún àwọn onígbàgbọ́, kò pọ̌ dandan fún mi láti kọ ìwé sí yín. 2 Mo mọ̀ nípa ìfẹ́ inú yín, tí mo sọ ọ̀rọ̀ rere nípa rẹ̀ fún àwọn ará Masidóníà. Mo sọ fún wọn wípé Akáyà ti múra sílẹ̀ láti ọdún tí ó kọjá. Ìpinnu ọkàn yín. Ìtara yín láti ṣiṣẹ́ ti ru ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn sókè láti ṣisẹ́. 3 Mo ti rán àwọn arákùnrin ní ìsinsìnyí kí ìsọ̀rọ̀ rere wa nípa yín má bà di asán, àti pé kí ẹ̀yin pẹ̀lú le múra sílẹ̀, gẹ́gẹ́ bí mo ti sọ. 4 Bíbẹ̀kọ́, tí àwọn ará Masidóníà kankan bá tẹ̀lé mi wá tí wọ́n sì bá a yín ní àìmúrasílẹ̀, a ó di ẹni ìtìjú - Èmi kò sọ ọ̀rọ̀ kankan nípa yín - nípa ìgbẹ́kẹ̀lé tí a ní nínú yín. 5 Nítorínà mo wòye wípé ó ṣe pàtàkì kí á rọ àwọn arákùnrin láti wá sí ọ̀dọ̀ yín àti láti ṣe gbogbo ètò sílẹ̀ sájú fún ẹ̀bùn tí ẹ ti ṣe ìlérí. A ṣe eléyìí kí ẹ̀bùn nà le ti wà ní ìmúra sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìbùnkún, kì í sì ṣe kí ó ba dàbí ẹnipé a jà yín ní olè. 6 Ohun tí ó ṣe kókó ni èyí: ẹni tí ó bá fún irúgbìn kékeré yí ò ká ohun kékeré, àti ẹni tì ó fún irúgbìn fún ète àti rí ìbùnkún yí ó rí ìbùnkún ká. 7 Ẹ jẹ́ kí olúkúlúkù kí ó fi fún ni gẹ́gẹ́ bí ò bá ti pinnu ní ọkàn rẹ̀. Ọlọ́run ní ìfẹ́ sí ẹni tí ó fifúnni pẹ̀lú ìdùnnú ọkàn. 8 Gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ti mú gbogbo ìbùnkún di púpọ̀ fún yín, kí ẹ̀yin kí ó le ní ohun gbogbo tí ẹ nílò nínú ohun gbogbo ní ìgbà gbogbo. Ìdí eléyìí ni láti mú kí ẹ di púpọ̀ nínú iṣẹ́ rere. 9 Ó ti wà gẹ́gẹ́ bí a ti kọ́: "Ó ti pín ọrọ̀ rẹ̀ Ó sì ti fi wọ́n fún àwọn tálákà. Òdodo rẹ̀ wà títí láíláí". 10 Ẹni tí ó pèsè irúgbìn fún ẹni tí ó gbin irúgbìn àti àkàrà fún óúnjẹ, yíò pèsè yíó sì sọ irúgbìn yín di púpọ̀. Yí ò jẹ́ kí ìkórè òdodo yín di púpọ̀. 11 Ẹ ó di ọlọ́rọ̀ ní gbogbo ọ̀nà kí ẹ̀yin kí ó bàlè ma fifúnni. Èyí nì yí ò mú ọpẹ́ wá fún Olúwwa làti ipasẹ̀ wa. 12 Síṣe iṣẹ́ ìsìn yìí kò bá àìní àwọn onígbàgbọ́ pàdé nìkan. Ṣùgbọ́n ó tún sọ ìṣe ìdúpẹ́ sí Ọlọ́run di púpọ̀. 13 Nítorí ìdáwó tí à ń ṣe fún yín àti ìyege yín nípa iṣẹ́ ìsìn yì, ẹ̀yin pẹ̀lú yí ò yin Ọlọ́run lógo nípa ìgbọ́ràn sí ìjẹ́wọ́ yín ti ìyìn rere ti Krístì. Ẹ ó tún yin Ọlọ́run lógo nípa àwọn ẹ̀bùn yín sí wọn àti sí àwọn míràn. 14 Wọ́n pòngbẹ láti rí yín, wọ́n sì ń gbàdúrà fún yín. Wọ́n ń ṣe ohun kan wọ̀nyí nítorí ore-ọ̀fẹ ńlá Ọlọ́run tí ó wà lórí yín. 15 Ọpẹ́ ni fún Ọlọ́run fún ẹ̀bùn ńlá tí kò sé fi ẹnu sọ!