ORÍ KẸẸ̀WÁ

1 Èmi, Pọ́ọ́lù, mo bẹ̀ ẹ̀ yín, nípa ìrẹ̀lẹ̀ àti ìwà tútù ti Krístì. Mo jẹ́ oní ìrẹ̀lẹ̀ ní iwájú yín, ṣùgbọ́n mo ní ìgboyà sí yín nígbà tí mo bá kúrò ní iwájú yín. 2 Mo bẹ̀ yín wípé nígbàtí mo bá wà pẹ̀lú yín, èmi kò ní n íláti ní ìgbọyà pẹ̀lú ìgbàgbọ́ nínú ara ẹni. Ṣùgbọ́n mo lérò wípé mo ní láti ní ìgboyà nígbàtí mo bá dojú kọ àwọn tí wọ́n rò wípé àwa ń gbé nípa ti ara. 3 Ṣùgbọ́n bí ó tí lẹ̀ jẹ́ wípé àwa ń rìn nípa tí ara, àwa kò ja ogun bí ẹni tí ara. 4 Nítorí àwọn ohun ìja tí à ń fí jà kì í ṣe ti ẹran ara. Dípò bẹ̀, àwọn ohun ìjà náà ní agbára Ọlọ́run láti pa àwọn ibigíga run. 5 Àwa tún ń pa ohun gbogbo tí ó gbé ara rẹ̀ ga sí ìmọ̀ Ọlọ̀run run. Àwa mú gbogbo èrò wá sí ìgbèkùn láti gbọ́ràn si Ọlọ́run. 6 À ń sì múra sílẹ̀ láti fi ìyà jẹ gbogbo ìwà àìgbọràn, kété tí ìgbọràn yín bá pé. 7 Ẹ ṣe àkíyèsí dáda ohun tí ó wà ní iwájú yín. tí ó bá dá ẹnikẹ́ni lójú wípé Òun nà ni Krístì, ẹ jẹ́ kí ó rán ara rẹ̀ létí wípé gẹ́gẹ́ bí òun ṣe jẹ́ Krístì, ni àwa nà jẹ. 8 NÍtorí bí mo tilẹ̀ fọ́n ẹnu níwọ̀n kékeré nípa àṣẹ wa, èyí tí Olúwa fifún wa láti fi kọ́ yín sókè àti láti mọ́ fi pa yín run, ojú kì yóò tì mí. 9 Èmi kò fẹ́ kí ó farahàn gẹ́gẹ́ bí wìpé mò ń dá ẹ̀rù bà yín nípa àwọn ìwé è mi. 10 Nítorí àwọn kan sọwípé, "Àwọn ìwe rẹ̀ ní agbára ó sì ni la púpọ̀, ṣùgbọ́n ó jẹ́ aláìlera nípa ti ara. Àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ kò sì yẹ fún gbígbọ́." 11 Ẹ jẹ́ kí irú àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀ mọ̀ wípé ohun tí a jẹ́ nínú ọ̀rọ̀ ìwé wa nígbàtí a kòsí ní ọ̀dọ̀ yín ni a ó jẹ́ nínú ìṣe wa nígbàtí a bá wà pẹ̀lu yín. 12 Àwa kò lọ jìnà láti kó ara wa jọ tàbí kí á fi ara wa wé àwọn tí wọ́n ń gbé oríyìn fún ara wọn. Ṣùgbọ́n nígbàtí wọ́n gbé ara wọn sí orí òsùnwọ̀n tí wọ́n sì fi ara wọn we ẹlòmíràn, wọn kò ní ojú inú. 13 Àwa pẹ̀lú, kò ní fọ́n ẹnu kọjá bí ó ti yẹ. Kàkà bẹ́ẹ̀, a ó ṣe é ní dédé ìwọ̀n tí Ọlọ́run yàn fún wa, ní ìwọ̀n bí ẹ̀yín ṣe mọ. 14 Nítorí àwa kò kọjá ìwọ̀n ti Ọlọ́run yàn fún wa ní ìgbàtí a dé ọ̀dọ̀ yín. Àwa ni ẹni àkọ́kọ́ tí ó kọ́kọ́ mú ìhìnrere Krístì tọ̀ ọ̀ yín wá. 15 Àwa kò fọ́n ẹnu ju bí ó ti yẹ lọ nípa iṣẹ́ àwọn ẹlòmíràn. Dípò bẹ́ẹ̀, a ní ìrètí wípé agbègbè ibi iṣẹ́ ti wa náà yí ó gbòòrò gidigidi gẹ́gẹ́ bí ìgbàgbọ́ yín tí ń dágbà, ní èyí tí kò ní kọjá ìwọ̀n tí ó yẹ. 16 Àwá ní ìrètí fún iǹkan wọ̀n yí, kí àwa bà le mọ́ wàásù ìhìnrere ní àwọn ibi tí ó kọjá agbègbè yín. A kò ní fọ́n ẹnu nípa àwọn iṣẹ́ tí a ti ṣe ní àwọn agbègbè míràn. 17 "Ṣùgbọ́n ẹ jẹ kí ẹni tí ó ún fọ́n ẹnu, fọ́n ẹnu nípa iṣẹ́ Olúwa." 18 Nítori kìí ṣe ẹni tí ó ún yin ara rẹ̀ ni ó jẹ́ ẹni ìfọwọ́sí. Dípò bẹ́ẹ̀, ẹni tí Ọlọ́run bá fí ọwọ́ sí